Àìsáyà 38:1-22
38 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+
2 Ni Hẹsikáyà bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní:
3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí+ bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ,+ ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.” Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.
4 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé:
5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ,+
6 màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà, màá sì gbèjà ìlú yìí.+
7 Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lójú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ:+
8 Màá mú kí òjìji oòrùn tó ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn* Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”’”+ Oòrùn wá pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.
9 Ìwé* tí Hẹsikáyà ọba Júdà kọ nígbà tó ń ṣàìsàn, tí ara rẹ̀ sì yá.
10 Mo sọ pé: “Ní àárín ọjọ́ ayé mi,Mo gbọ́dọ̀ wọnú àwọn ẹnubodè Isà Òkú.*
A máa fi àwọn ọdún mi tó kù dù mí.”
11 Mo sọ pé: “Mi ò ní rí Jáà,* àní Jáà ní ilẹ̀ alààyè.+
Mi ò ní wo aráyé mọ́,Tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé ibi tí gbogbo nǹkan ti dáwọ́ dúró.
12 A ti fa ibùgbé mi tu, a sì ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi+Bí àgọ́ olùṣọ́ àgùntàn.
Mo ti ká ẹ̀mí mi bíi ti ẹni tó ń hun aṣọ;Ó gé mi kúrò bí àwọn òwú tó wà lóròó.
Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.
13 Mo fira mi lọ́kàn balẹ̀ títí di àárọ̀.
Ó ń fọ́ gbogbo egungun mi bíi kìnnìún;Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.
14 Mò ń ké ṣíoṣío bí ẹyẹ olófèéèré àti ẹ̀gà;*+Mò ń ké kúùkúù bí àdàbà.+
Ojú mi ń wo ibi gíga títí ó fi rẹ̀ mí:+
‘Jèhófà, ìdààmú ti bò mí mọ́lẹ̀;Ràn mí lọ́wọ́!’*+
15 Kí ni kí n sọ?
Ó ti bá mi sọ̀rọ̀, ó sì ti ṣe nǹkan kan.
Màá máa rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀* ní gbogbo ọdún miTorí ẹ̀dùn ọkàn tó bá mi.*
16 ‘Jèhófà, àwọn nǹkan yìí* ló ń mú gbogbo èèyàn wà láàyè,Ìwàláàyè ẹ̀mí mi sì wà nínú wọn.
O máa mú kí n pa dà ní ìlera tó dáa, o sì máa dá ẹ̀mí mi sí.+
17 Wò ó! Dípò àlàáfíà, ìbànújẹ́ ńlá ló bá mi;Àmọ́ torí ìfẹ́ tí o ní sí mi,*O pa mí mọ́ kúrò nínú kòtò ìparun.+
O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.*+
18 Torí pé Isà Òkú* ò lè yìn ọ́ lógo,+Ikú ò lè yìn ọ́.+
Àwọn tó lọ sínú kòtò kò lè retí ìṣòtítọ́ rẹ.+
19 Alààyè, àní alààyè lè yìn ọ́,Bí mo ṣe lè yìn ọ́ lónìí.
Bàbá lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa ìṣòtítọ́ rẹ.+
20 Jèhófà, gbà mí,A sì máa fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ àwọn orin mi+Ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ní ilé Jèhófà.’”+
21 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ mú ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ wá, kí ẹ sì fi sí eéwo náà, kí ara rẹ̀ lè yá.”+
22 Hẹsikáyà ti béèrè pé: “Àmì wo ni màá fi mọ̀ pé màá lọ sí ilé Jèhófà?”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtẹ̀gùn yìí ni wọ́n fi ń ka àkókò bíi ti aago òjìji oòrùn.
^ Tàbí “Ewì.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
^ Ní Héb., “Ṣe onídùúró mi.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ẹyẹ òfú.”
^ Tàbí “tìrònútìrònú.”
^ Tàbí “ọkàn mi tó gbọgbẹ́.”
^ Ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe.
^ Tàbí “mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò níwájú rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.