Àwọn Onídàájọ́ 11:1-40

  • Wọ́n lé Jẹ́fútà onídàájọ́ jáde, àmọ́ wọ́n sọ ọ́ di olórí nígbà tó yá (1-11)

  • Jẹ́fútà bá àwọn ọmọ Ámónì sọ̀rọ̀ (12-28)

  • Ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ àti ọmọbìnrin rẹ̀ (29-40)

    • Ọmọbìnrin náà ò lọ́kọ rárá (38-40)

11  Jagunjagun tó lákíkanjú ni Jẹ́fútà+ tó wá láti ìdílé Gílíádì; aṣẹ́wó ni ìyá rẹ̀, Gílíádì sì ni bàbá rẹ̀.  Àmọ́, ìyàwó Gílíádì náà bí àwọn ọmọkùnrin fún un. Nígbà tí àwọn ọmọ ìyàwó rẹ̀ dàgbà, wọ́n lé Jẹ́fútà jáde, wọ́n sì sọ fún un pé: “O ò ní bá wa pín ogún kankan ní agbo ilé bàbá wa, torí ọmọ obìnrin míì ni ọ́.”  Torí náà, Jẹ́fútà sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì lọ ń gbé ilẹ̀ Tóbù. Àwọn ọkùnrin tí kò níṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jẹ́fútà, wọ́n sì jọ ń rìn.  Nígbà tó ṣe díẹ̀, àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà.+  Nígbà tí àwọn ọmọ Ámónì bá Ísírẹ́lì jà, ojú ẹsẹ̀ làwọn àgbààgbà Gílíádì lọ mú Jẹ́fútà pa dà wá láti ilẹ̀ Tóbù.  Wọ́n sọ fún Jẹ́fútà pé: “Wá di ọ̀gágun wa, ká lè gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì.”  Àmọ́ Jẹ́fútà sọ fún àwọn àgbààgbà Gílíádì pé: “Ṣebí ẹ̀yin lẹ kórìíra mi débi pé ẹ lé mi jáde ní ilé bàbá mi?+ Kí ló dé tí ẹ wá ń wá mi báyìí tí ìdààmú ti bá yín?”  Àwọn àgbààgbà Gílíádì wá sọ fún Jẹ́fútà pé: “Ìdí nìyẹn tí a fi pa dà wá bá ọ báyìí. Tí o bá tẹ̀ lé wa tí o sì bá àwọn ọmọ Ámónì jà, wàá di olórí wa àti gbogbo àwọn tó ń gbé ní Gílíádì.”+  Torí náà, Jẹ́fútà sọ fún àwọn àgbààgbà Gílíádì pé: “Tí ẹ bá mú mi pa dà láti bá àwọn ọmọ Ámónì jà, tí Jèhófà sì bá mi ṣẹ́gun wọn, ó dájú pé màá di olórí yín!” 10  Àwọn àgbààgbà Gílíádì sọ fún Jẹ́fútà pé: “Kí Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́rìí* láàárín wa tí a ò bá ṣe ohun tí o sọ.” 11  Jẹ́fútà wá tẹ̀ lé àwọn àgbààgbà Gílíádì lọ, àwọn èèyàn náà sì sọ ọ́ di olórí àti ọ̀gágun wọn. Jẹ́fútà sì tún gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ níwájú Jèhófà ní Mísípà.+ 12  Jẹ́fútà wá ránṣẹ́ sí ọba àwọn ọmọ Ámónì+ pé: “Kí ni mo fi ṣe ọ́* tí o fi wá gbógun ja ilẹ̀ mi?” 13  Ọba àwọn ọmọ Ámónì sọ fún àwọn tí Jẹ́fútà rán wá pé: “Torí pé nígbà tí Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì,+ wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Áánónì+ dé Jábókù títí dé Jọ́dánì.+ Ó yá, dá a pa dà ní àlàáfíà.” 14  Àmọ́ Jẹ́fútà ní kí àwọn ìránṣẹ́ náà pa dà sọ́dọ̀ ọba àwọn ọmọ Ámónì, 15  kí wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jẹ́fútà sọ nìyí: ‘Ísírẹ́lì ò gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Móábù+ àti ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ 16  torí nígbà tí Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n rin aginjù títí dé Òkun Pupa,+ wọ́n sì dé Kádéṣì.+ 17  Ísírẹ́lì wá ránṣẹ́ sí ọba Édómù+ pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá,” àmọ́ ọba Édómù ò gbà. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù,+ àmọ́ kò gbà. Ísírẹ́lì ò wá kúrò ní Kádéṣì.+ 18  Nígbà tí wọ́n rin aginjù, wọn ò gba inú ilẹ̀ Édómù+ àti ilẹ̀ Móábù kọjá. Apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Móábù+ ni wọ́n gbà, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì; wọn ò wọnú ààlà Móábù,+ torí Áánónì ni ààlà Móábù. 19  “‘Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì ránṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn Ámórì, ọba Hẹ́ṣíbónì, Ísírẹ́lì sì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá sí àyè wa.”+ 20  Àmọ́ Síhónì kò fọkàn tán Ísírẹ́lì, kò gbà kí wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá, torí náà, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jáhásì, wọ́n sì bá Ísírẹ́lì jà.+ 21  Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá fi Síhónì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, torí náà wọ́n ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámórì tó ń gbé ilẹ̀ náà.+ 22  Bí wọ́n ṣe gba gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámórì nìyẹn, láti Áánónì dé Jábókù àti láti aginjù títí dé Jọ́dánì.+ 23  “‘Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ló lé àwọn Ámórì kúrò níwájú Ísírẹ́lì èèyàn rẹ̀,+ ṣé o wá fẹ́ lé wọn kúrò ni? 24  Ṣebí ohunkóhun tí Kémóṣì+ ọlọ́run rẹ bá fún ọ pé kí o gbà lo máa ń gbà? Torí náà gbogbo àwọn tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá lé kúrò níwájú wa la máa lé kúrò.+ 25  Ṣé ìwọ wá sàn ju Bálákì+ ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ ni? Ṣé ó bá Ísírẹ́lì fa ohunkóhun rí, àbí ó bá wọn jà rí? 26  Nígbà tí Ísírẹ́lì ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì àti àwọn àrọko rẹ̀* àti Áróérì àti àwọn àrọko rẹ̀+ àti ní gbogbo ìlú tó wà létí Áánónì fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún, kí ló dé tí ẹ ò gbìyànjú rárá láti gbà wọ́n pa dà nígbà yẹn?+ 27  Mi ò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ lo ṣe ohun tí kò dáa bí o ṣe wá gbógun jà mí. Kí Jèhófà Onídàájọ́+ ṣe ìdájọ́ lónìí láàárín àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti àwọn èèyàn Ámónì.’” 28  Àmọ́ ọba àwọn ọmọ Ámónì kò fetí sí ohun tí Jẹ́fútà ní kí wọ́n sọ fún un. 29  Ẹ̀mí Jèhófà wá bà lé Jẹ́fútà,+ ó sì gba Gílíádì àti Mánásè kọjá lọ sí Mísípè ti Gílíádì,+ láti Mísípè ti Gílíádì ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì. 30  Jẹ́fútà wá jẹ́ ẹ̀jẹ́+ kan fún Jèhófà, ó ní: “Tí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́, 31  tí mo bá pa dà ní àlàáfíà látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, ẹnikẹ́ni tó bá jáde ní ẹnu ọ̀nà ilé mi wá pàdé mi máa di ti Jèhófà,+ màá sì fi onítọ̀hún rú ẹbọ sísun.”+ 32  Lẹ́yìn náà, Jẹ́fútà lọ bá àwọn ọmọ Ámónì jà, Jèhófà sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́. 33  Ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ láti Áróérì títí dé Mínítì, ogún (20) ìlú, títí lọ dé Ebẹli-kérámímù. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámónì nìyẹn. 34  Níkẹyìn, Jẹ́fútà dé sí ilé rẹ̀ ní Mísípà,+ wò ó! ọmọbìnrin rẹ̀ ló ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó ń lu ìlù tanboríìnì, ó sì ń jó! Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Kò ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin míì. 35  Nígbà tó rí i, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́,* torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, mi ò sì lè yí i pa dà.”+ 36  Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Bàbá mi, tí o bá ti la ẹnu rẹ sí Jèhófà, ohun tí o ṣèlérí+ ni kí o ṣe sí mi, Jèhófà kúkú ti bá ọ gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ, àwọn ọmọ Ámónì.” 37  Ó wá sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Ohun tí o máa ṣe fún mi nìyí: Jẹ́ kí n dá wà fún oṣù méjì, sì jẹ́ kí n lọ síbi àwọn òkè, kí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi obìnrin sì sunkún torí pé mo jẹ́ wúńdíá.”* 38  Ó wá sọ fún un pé: “Máa lọ!” Torí náà, ó ní kó lọ fún oṣù méjì, òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì lọ síbi àwọn òkè láti lọ sunkún torí ó jẹ́ wúńdíá. 39  Lẹ́yìn oṣù méjì, ó pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, ó sì ṣe ohun tó jẹ́jẹ̀ẹ́ nípa rẹ̀.+ Ọmọbìnrin náà ò bá ọkùnrin lò pọ̀ rárá. Torí náà, ó di àṣà* wọn ní Ísírẹ́lì pé: 40  Lọ́dọọdún, àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní Ísírẹ́lì máa ń lọ yin ọmọbìnrin Jẹ́fútà ọmọ Gílíádì ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “ẹni tó ń gbọ́.”
Ní Héb., “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀?”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”
Ní Héb., “O ti rẹ̀ mí wálẹ̀ gan-an.”
Tàbí “kí n sì sunkún pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi torí mi ò ní lọ́kọ láé.”
Tàbí “ìlànà.”