Ẹ́kísódù 21:1-36

  • Ìdájọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé (1-36)

    • Tí wọ́n bá ra Hébérù ní ẹrú (2-11)

    • Tí ẹnì kan bá hùwà ipá sí ẹnì kejì (12-27)

    • Nípa àwọn ẹranko (28-36)

21  “Àwọn ìdájọ́ tí wàá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí:+  “Tí o bá ra Hébérù kan ní ẹrú,+ kí ó sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà, àmọ́ ní ọdún keje, kí o dá a sílẹ̀ láìgba ohunkóhun.+  Tó bá jẹ́ pé òun nìkan ló wá, òun nìkan ni yóò pa dà. Tó bá ní ìyàwó, kí ìyàwó rẹ̀ bá a lọ.  Tó bá jẹ́ pé ọ̀gá rẹ̀ ló fún un ní ìyàwó, tí obìnrin náà sì bí àwọn ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin fún un, obìnrin náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò di ti ọ̀gá rẹ̀, ọkùnrin náà nìkan ni yóò lọ.+  Àmọ́ tí ẹrú náà ò bá gbà láti lọ, tó sì sọ pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ mi; mi ò fẹ́ kí ọ̀gá mi dá mi sílẹ̀,’+  kí ọ̀gá rẹ̀ mú un wá síwájú Ọlọ́run tòótọ́. Kó wá mú ọkùnrin náà wá síbi ilẹ̀kùn tàbí férémù ilẹ̀kùn, kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu* lu etí rẹ̀, yóò sì di ẹrú rẹ̀ títí láé.  “Tí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹrú, ọ̀gá rẹ̀ ò ní dá a sílẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣe fún ọkùnrin tó jẹ́ ẹrú.  Tí inú ọ̀gá obìnrin náà ò bá dùn sí i, tí kò sì fi ṣe wáhàrì,* àmọ́ tó mú kí ẹlòmíì rà á,* kò ní lẹ́tọ̀ọ́ láti tà á fún àwọn àjèjì, torí ó ti da obìnrin náà.  Tó bá fún ọmọkùnrin rẹ̀ ní obìnrin náà pé kó fi ṣe aya, kó fún obìnrin náà ní ẹ̀tọ́ tó yẹ ọmọbìnrin. 10  Tó bá fẹ́ ìyàwó míì, oúnjẹ, aṣọ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó+ àkọ́kọ́ ò gbọ́dọ̀ dín kù. 11  Tí kò bá fún un ní nǹkan mẹ́ta yìí, kí obìnrin náà lọ lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó. 12  “Tí ẹnì kan bá lu èèyàn pa, kí ẹ pa onítọ̀hún.+ 13  Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kò mọ̀ọ́mọ̀ pa á, tí Ọlọ́run tòótọ́ sì fàyè gbà á, màá yan ibì kan fún ọ tó lè sá lọ.+ 14  Tí ẹnì kan bá bínú gidigidi sí ọmọnìkejì rẹ̀, tó sì mọ̀ọ́mọ̀ pa á,+ kí ẹ pa onítọ̀hún, ì báà jẹ́ ibi pẹpẹ mi lo ti máa wá mú un.+ 15  Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá lu bàbá tàbí ìyá rẹ̀.+ 16  “Kí ẹ pa+ ẹnikẹ́ni tó bá jí èèyàn gbé+ tó sì tà á tàbí tí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́.+ 17  “Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣépè fún* bàbá tàbí ìyá rẹ̀.+ 18  “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí ẹnì kan wá ju òkúta lu ẹnì kejì rẹ̀ tàbí tó gbá a ní ẹ̀ṣẹ́,* tí kò sì kú, àmọ́ tí kò lè kúrò lórí ibùsùn rẹ̀, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyí: 19  Tó bá lè dìde, tó sì fi ọ̀pá rìn káàkiri níta, ẹ má fìyà jẹ ẹni tó ṣe é léṣe. Àmọ́ kó san nǹkan kan láti fi dí àkókò tí ẹni tó fara pa yẹn ò fi lè ṣiṣẹ́ títí ara rẹ̀ á fi yá. 20  “Tí ọkùnrin kan bá fi igi lu ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, tó sì kú mọ́ ọn lọ́wọ́, kí ẹ gbẹ̀san ẹrú náà.+ 21  Àmọ́, tí kò bá kú láàárín ọjọ́ kan sí méjì, ẹ má gbẹ̀san lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ̀, torí owó ara rẹ̀ ló fi rà á. 22  “Tí àwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe obìnrin tó lóyún léṣe, tó wá bímọ nígbà tí àsìkò rẹ̀ kò tíì tó,*+ àmọ́ tí kò la ẹ̀mí lọ,* ẹni tó ṣe obìnrin náà léṣe gbọ́dọ̀ san owó ìtanràn tí ọkọ rẹ̀ bá bù lé e; kí ó san án nípasẹ̀ àwọn adájọ́.+ 23  Àmọ́ tó bá la ẹ̀mí lọ, kí o fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí,*+ 24  ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀,+ 25  kí o fi nǹkan jó ẹni tó bá fi nǹkan jó ẹnì kejì, ọgbẹ́ dípò ọgbẹ́, ẹ̀ṣẹ́ dípò ẹ̀ṣẹ́. 26  “Tí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, tí ojú rẹ̀ sì fọ́, kó dá ẹrú náà sílẹ̀ lómìnira láti fi dípò ojú rẹ̀ tó fọ́.+ 27  Tó bá sì gbá eyín ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ yọ, kó dá ẹrú náà sílẹ̀ lómìnira láti fi dípò eyín rẹ̀ tó yọ. 28  “Tí akọ màlúù kan bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan, tí ẹni yẹn sì kú, kí ẹ sọ akọ màlúù náà lókùúta pa,+ kí ẹnikẹ́ni má sì jẹ ẹran rẹ̀. Ẹ má fìyà jẹ ẹni tó ni akọ màlúù náà. 29  Àmọ́ tó bá ti di ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn, tí wọ́n sì ti kìlọ̀ fún ẹni tó ni ín àmọ́ tí kò bójú tó o, tí akọ màlúù náà wá pa ọkùnrin tàbí obìnrin kan, kí ẹ sọ ọ́ lókùúta pa, kí ẹ sì pa ẹni tó ni ín. 30  Tí wọ́n bá ní kó san ìràpadà,* ó gbọ́dọ̀ san gbogbo owó tí wọ́n bá ní kó san láti fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà. 31  Ì báà jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin ni màlúù náà kàn, ìdájọ́ yìí ni kí wọ́n ṣe fún ẹni tó ni akọ màlúù náà. 32  Tí akọ màlúù náà bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin kan, ẹni tó ni ín yóò san ọgbọ̀n (30) ṣékélì* fún ọ̀gá ẹrú yẹn, wọ́n á sì sọ akọ màlúù náà lókùúta pa. 33  “Tí ọkùnrin kan bá ṣí kòtò kan sílẹ̀ tàbí tó gbẹ́ kòtò kan, tí kò sì bò ó, tí akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan wá já sínú rẹ̀, 34  kí ẹni tó ni kòtò náà san iye kan dípò ẹran náà.+ Kí ó san owó náà fún ẹni tó ni ín, òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀. 35  Tí akọ màlúù ẹnì kan bá ṣe akọ màlúù ẹlòmíì léṣe, tó sì kú, kí wọ́n ta akọ màlúù tí kò kú yẹn, kí wọ́n sì pín owó rẹ̀; kí wọ́n tún pín òkú ẹran náà. 36  Tàbí tó bá jẹ́ pé ó ti di ìṣe akọ màlúù kan láti máa kàn, àmọ́ tí ẹni tó ni ín ò bójú tó o, kó fi akọ màlúù dípò akọ màlúù, èyí tó kú yóò sì di tirẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, ohun tí wọ́n fi ń dá nǹkan lu.
Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Ní Héb., “tún un rà.”
Tàbí “pe ibi wá sórí.”
Tàbí kó jẹ́, “fi ohun kan lù ú.”
Tàbí “tí jàǹbá tó burú jáì kò ṣẹlẹ̀.”
Ní Héb., “tí àwọn ọmọ rẹ̀ sì jáde.”
Tàbí “ọkàn fún ọkàn.”
Tàbí “owó ìtanràn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.