Ẹ́kísódù 27:1-21
27 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ;+ kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* márùn-ún, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Kí ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹpẹ náà dọ́gba, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+
2 Kí o ṣe ìwo+ sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; àwọn ìwo náà yóò wà lára pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà bo pẹpẹ náà.+
3 Kí o ṣe àwọn garawa láti máa fi kó eérú* rẹ̀ dà nù, kí o tún ṣe àwọn ṣọ́bìrì, àwọn abọ́, àwọn àmúga àti àwọn ìkóná, bàbà sì ni kí o fi ṣe gbogbo ohun èlò rẹ̀.+
4 Kí o fi bàbà ṣe àgbàyan* tó rí bí àwọ̀n fún pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà ṣe òrùka mẹ́rin sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.
5 Kí o gbé e sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ etí pẹpẹ náà, kí àgbàyan náà sì wọnú pẹpẹ náà níbi àárín.
6 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá fún pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà bò wọ́n.
7 Kí o ki àwọn ọ̀pá náà bọnú àwọn òrùka náà, kí àwọn ọ̀pá náà lè wà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá gbé e.+
8 Kí o ṣe pẹpẹ náà bí àpótí onípákó tí inú rẹ̀ jìn. Kí o ṣe é bí Ó ṣe fi hàn ọ́ lórí òkè gẹ́lẹ́.+
9 “Kí o ṣe àgbàlá+ àgọ́ ìjọsìn náà. Ní apá gúúsù tó dojú kọ gúúsù, kí àgbàlá náà ní àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe, èyí tí wọ́n máa ta, kí gígùn ẹ̀gbẹ́ kan jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́.+
10 Kí ó ní ogún (20) òpó pẹ̀lú ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe. Kí o fi fàdákà ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.*
11 Kí gígùn àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí apá àríwá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́, kí àwọn òpó rẹ̀ jẹ́ ogún (20) àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, pẹ̀lú ìkọ́ àwọn òpó náà àti ohun tó so wọ́n pọ̀* tí wọ́n fi fàdákà ṣe.
12 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n máa ta sí ẹ̀gbẹ́ àgbàlá náà lápá ìwọ̀ oòrùn jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò.
13 Kí fífẹ̀ àgbàlá náà ní apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.
14 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.+
15 Kí àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.
16 “Kí o ta aṣọ* tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe é,+ pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rin.+
17 Fàdákà ni kí o fi ṣe gbogbo òpó tó yí àgbàlá náà ká àti àwọn ohun tí wọ́n fi ń de nǹkan pọ̀ àti àwọn ìkọ́, àmọ́ bàbà ni kí o fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn.+
18 Kí gígùn àgbàlá náà jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́,+ kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ni kí o fi ṣe é, kó sì ní àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe.
19 Bàbà ni kí o fi ṣe gbogbo ohun èlò àti àwọn nǹkan tí ẹ ó máa fi ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn náà, pẹ̀lú àwọn èèkàn àgọ́ náà àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà.+
20 “Kí o pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n gbé ògidì òróró ólífì tí wọ́n fún wá sọ́dọ̀ rẹ láti máa fi tan iná, kí àwọn fìtílà náà lè máa wà ní títàn nígbà gbogbo.+
21 Nínú àgọ́ ìpàdé, lẹ́yìn òde aṣọ ìdábùú tó wà nítòsí Ẹ̀rí náà,+ kí Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣètò bí àwọn fìtílà náà á ṣe máa wà ní títàn láti alẹ́ títí di àárọ̀ níwájú Jèhófà.+ Àṣẹ yìí ni kí gbogbo ìran wọn máa tẹ̀ lé títí lọ, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe é.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
^ Tàbí “ayanran.”
^ Tàbí “aṣọ àtàtà.”
^ Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
^ Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.
^ Tàbí “aṣọ ìdábùú.”