Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí 11:1-19
11 A sì fún mi ní esùsú* kan tó dà bí ọ̀pá*+ bó ṣe ń sọ pé: “Dìde, kí o wọn ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀.
2 Àmọ́ ní ti àgbàlá tó wà ní ìta ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, fi sílẹ̀, má sì wọ̀n ọ́n, torí a ti fún àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì máa fi ẹsẹ̀ wọn tẹ ìlú mímọ́ náà+ mọ́lẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì+ (42).
3 Màá mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì fi ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ (1,260) sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀.”*
4 Àwọn yìí ni igi ólífì méjì+ àti ọ̀pá fìtílà méjì ṣàpẹẹrẹ,+ wọ́n dúró síwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.+
5 Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ pa wọ́n lára, iná á jáde láti ẹnu wọn, á sì jó àwọn ọ̀tá wọn run. Bí a ṣe máa pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ pa wọ́n lára nìyí.
6 Àwọn yìí ní àṣẹ láti sé òfúrufú* pa+ kí òjò kankan má bàa rọ̀+ ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ní àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀+ àti láti fi gbogbo oríṣiríṣi ìyọnu kọ lu ayé ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fẹ́.
7 Nígbà tí wọ́n bá jẹ́rìí tán, ẹranko tó jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ máa bá wọn jagun, ó máa ṣẹ́gun wọn, ó sì máa pa wọ́n.+
8 Òkú wọn sì máa wà lójú ọ̀nà ìlú ńlá náà, èyí tí wọ́n ń pè ní Sódómù àti Íjíbítì lọ́nà ti ẹ̀mí, níbi tí wọ́n ti kan Olúwa wọn pẹ̀lú mọ́gi.
9 Àwọn kan látinú àwọn èèyàn àti àwọn ẹ̀yà àti àwọn ahọ́n* àti àwọn orílẹ̀-èdè máa fi ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀+ wo òkú wọn, wọn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n tẹ́ òkú wọn sínú ibojì.
10 Àwọn tó ń gbé ní ayé yọ̀ torí wọn, wọ́n ṣe àjọyọ̀, wọ́n sì máa fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn, torí pé àwọn wòlíì méjì yìí ti dá àwọn tó ń gbé ayé lóró.
11 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọnú wọn,+ wọ́n dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù sì ba àwọn tó rí wọn gidigidi.
12 Wọ́n wá gbọ́ ohùn kan tó ké jáde sí wọn láti ọ̀run pé: “Ẹ máa bọ̀ lókè níbí.” Wọ́n sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú àwọsánmà,* àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn.*
13 Ní wákàtí yẹn, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀, ìdá mẹ́wàá ìlú náà sì ṣubú; ẹgbẹ̀rún méje (7,000) èèyàn ni ìmìtìtì ilẹ̀ náà pa, ẹ̀rù sì ba àwọn yòókù, wọ́n yin Ọlọ́run ọ̀run lógo.
14 Ìyọnu kejì+ ti kọjá. Wò ó! Ìyọnu kẹta ń bọ̀ kíákíá.
15 Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+
16 Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọ́run dojú bolẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run,
17 wọ́n ní: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà* Ọlọ́run, Olódùmarè, ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ torí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti ń jọba.+
18 Àmọ́ inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ náà sì bínú, àkókò wá tó láti ṣèdájọ́ àwọn òkú àti láti san èrè+ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì+ àti àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn tó ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá àti láti run àwọn tó ń run ayé.”*+
19 A ṣí ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní ọ̀run, a sì rí àpótí májẹ̀mú rẹ̀ nínú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì rẹ̀.+ Mànàmáná kọ yẹ̀rì, a sì gbọ́ ohùn, ààrá sán, ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé, òjò yìnyín rẹpẹtẹ sì rọ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọ̀pá ìdíwọ̀n.”
^ Ìyẹn, koríko etí omi.
^ Ní Grk., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “ọ̀run.”
^ Tàbí “àwọn èdè.”
^ Tàbí “ìkùukùu.”
^ Tàbí “sì ń wò wọ́n.”
^ Tàbí “láti pa àwọn tó ń pa ayé run.”