Ìsíkíẹ́lì 33:1-33
33 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn ọmọ èèyàn rẹ sọ̀rọ̀,+ kí o sì sọ fún wọn pé,“‘Ká sọ pé mo mú idà wá sórí ilẹ̀ kan,+ tí gbogbo èèyàn ilẹ̀ náà mú ọkùnrin kan, tí wọ́n sì fi ṣe olùṣọ́ wọn,
3 tó sì rí idà tó ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ náà, tó fun ìwo, tó sì kìlọ̀ fún àwọn èèyàn.+
4 Tí ẹnì kan bá gbọ́ tí ìwo dún àmọ́ tí kò fetí sí ìkìlọ̀,+ tí idà wá, tó sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn òun fúnra rẹ̀.+
5 Ó gbọ́ tí ìwo dún, àmọ́ kò gba ìkìlọ̀. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní ọrùn rẹ̀. Ká ní ó gba ìkìlọ̀ ni, ì bá gba ẹ̀mí* ara rẹ̀ là.
6 “‘Àmọ́ tí olùṣọ́ náà bá rí i pé idà ń bọ̀, tí kò fun ìwo,+ tí àwọn èèyàn kò sì rí ìkìlọ̀ gbà, tí idà sì dé, tó sì gba ẹ̀mí* ẹnì kan nínú wọn, ẹni yẹn á kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àmọ́ màá béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.’*+
7 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì, nígbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, kí o bá mi kìlọ̀ fún wọn.+
8 Tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Ìwọ ẹni burúkú, ó dájú pé wàá kú!’+ àmọ́ tí ìwọ kò sọ ohunkóhun láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ọwọ́ rẹ ni màá ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
9 Àmọ́ tí o bá kìlọ̀ fún ẹni burúkú pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà tí kò sì yí pa dà, ẹni burúkú náà yóò kú torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ó dájú pé ìwọ yóò gba ẹ̀mí* rẹ là.+
10 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘O ti sọ pé: “Ọ̀tẹ̀ wa àti ẹ̀ṣẹ̀ wa ti dẹ́rù pa wá, ó ń mú kó rẹ̀ wá;+ báwo la ṣe máa wá wà láàyè?”’+
11 Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “inú mi ò dùn sí ikú ẹni burúkú,+ bí kò ṣe pé kí ẹni burúkú yí ìwà rẹ̀ pa dà,+ kó sì máa wà láàyè.+ Ẹ yí pa dà, ẹ yí ìwà búburú yín pa dà,+ ṣé ó wá yẹ kí ẹ kú ni, ilé Ísírẹ́lì?”’+
12 “Ìwọ ọmọ èèyàn, sọ fún àwọn ọmọ èèyàn rẹ pé, ‘Bí olódodo bá ṣọ̀tẹ̀, òdodo rẹ̀ kò ní gbà á là;+ bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà burúkú ẹni burúkú kò ní mú kó kọsẹ̀ nígbà tó bá fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀;+ olódodo kò sì ní lè máa wà láàyè nítorí òdodo rẹ̀ lọ́jọ́ tó bá dẹ́ṣẹ̀.+
13 Tí mo bá sọ fún olódodo pé: “Ó dájú pé ìwọ yóò máa wà láàyè,” tó wá gbẹ́kẹ̀ lé òdodo rẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa,*+ mi ò ní rántí ìkankan nínú iṣẹ́ òdodo rẹ̀, àmọ́ yóò kú torí ohun tí kò dáa tó ṣe.+
14 “‘Tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: “Ó dájú pé wàá kú,” tó wá fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo,+
15 tí ẹni burúkú náà wá dá ohun tí wọ́n fi ṣe ìdúró pa dà,+ tó dá àwọn nǹkan tó jí pa dà,+ tó ń hùwà tó dáa láti fi hàn pé òun ń tẹ̀ lé àṣẹ tó ń fúnni ní ìyè, ó dájú pé yóò máa wà láàyè.+ Kò ní kú.
16 Èmi kò ní ka èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sí i lọ́rùn.*+ Ó dájú pé yóò máa wà láàyè torí ó ṣe ohun tó tọ́, ó sì ṣe òdodo.’+
17 “Àmọ́ àwọn èèyàn rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́,’ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀nà tiwọn ni kò tọ́.
18 “Tí olódodo bá fi òdodo tó ń ṣe sílẹ̀, tó sì wá ń ṣe ohun tí kò dáa, yóò kú nítorí ìwà rẹ̀.+
19 Àmọ́ tí ẹni burúkú bá yí pa dà kúrò nínú iṣẹ́ ibi rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó jẹ́ òdodo, yóò máa wà láàyè torí ohun tó ṣe.+
20 “Àmọ́ ẹ ti sọ pé, ‘Ọ̀nà Jèhófà kò tọ́.’+ Èmi yóò fi ìwà kálukú dá a lẹ́jọ́, ìwọ ilé Ísírẹ́lì.”
21 Nígbà tó yá, ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá tí a ti wà ní ìgbèkùn, ọkùnrin kan tó sá àsálà kúrò ní Jerúsálẹ́mù wá bá mi,+ ó sì sọ pé: “Wọ́n ti pa ìlú náà run!”+
22 Àmọ́ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí ọkùnrin tó sá àsálà náà wá, ọwọ́ Jèhófà wá sára mi, ó sì ti la ẹnu mi kí ọkùnrin náà tó wá bá mi ní àárọ̀. Ẹnu mi wá là, mi ò sì yadi mọ́.+
23 Ni Jèhófà bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
24 “Ọmọ èèyàn, àwọn tó ń gbé ibi àwókù yìí+ ń sọ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹnì kan péré ni Ábúráhámù, síbẹ̀ ó gba ilẹ̀ náà.+ Àmọ́ àwa pọ̀; ó dájú pé wọ́n ti fún wa ní ilẹ̀ náà kó lè di ohun ìní wa.’
25 “Torí náà, sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ tòun ti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ ẹ̀ ń gbé ojú yín sókè sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* yín, ẹ sì ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín?
26 Ẹ ti gbẹ́kẹ̀ lé idà yín,+ ẹ̀ ń ṣe ohun tó ń ríni lára, kálukú yín sì ti bá ìyàwó ọmọnìkejì rẹ̀ sùn.+ Ẹ sì wá rò pé ilẹ̀ náà máa di tiyín?”’+
27 “Ohun tí ìwọ yóò sọ fún wọn ni pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí mo ti wà láàyè, wọ́n á fi idà pa àwọn tó ń gbé inú àwókù náà; èmi yóò sọ àwọn tó wà lórí pápá gbalasa di oúnjẹ fún àwọn ẹranko; àrùn yóò sì pa àwọn tó wà nínú ibi ààbò àti ihò inú àwọn àpáta.+
28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ òpin á sì dé bá ìgbéraga rẹ̀, àwọn òkè Ísírẹ́lì yóò di ahoro,+ ẹnikẹ́ni ò sì ní gba ibẹ̀ kọjá.
29 Wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, nígbà tí mo bá mú kí ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá,+ nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe.”’+
30 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, àwọn èèyàn rẹ ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ògiri àti ní ẹnu ọ̀nà àwọn ilé.+ Wọ́n ń sọ fún ara wọn, kálukú ń sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’
31 Wọn yóò rọ́ wá bá ọ, kí wọ́n lè jókòó síwájú rẹ bí èèyàn mi; wọ́n á sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní ṣe ohun tí wọ́n gbọ́.+ Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ dídùn fún ọ,* àmọ́ bí wọ́n ṣe máa jèrè tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn wọn.
32 Wò ó! Lójú wọn, o dà bí orin ìfẹ́, tí wọ́n fi ohùn dídùn kọ, tí wọ́n sì fi ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ lọ́nà tó já fáfá. Wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé e.
33 Ó máa ṣẹ, tó bá ti wá ṣẹ, wọ́n á wá mọ̀ pé wòlíì kan ti wà láàárín wọn.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “tó sì mú un lọ.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọrùn olùṣọ́ náà ni màá ka ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “tí kò sì ṣe òdodo.”
^ Ní Héb., “rántí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá.”
^ Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.
^ Tàbí “sọ̀rọ̀ ìfẹ́ orí ahọ́n.”