Ìwé Kìíní Jòhánù 2:1-29
2 Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́* lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi,+ ẹni tó jẹ́ olódodo.+
2 Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ tiwa nìkan, àmọ́ fún gbogbo ayé pẹ̀lú.+
3 Tí a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wá mọ̀ ọ́n.
4 Òpùrọ́ ni ẹni tó bá sọ pé, “Mo ti wá mọ̀ ọ́n,” síbẹ̀ tí kò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, òótọ́ ò sí nínú ẹni náà.
5 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ti di pípé nínú ẹni náà.+ Èyí la fi mọ̀ pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+
6 Ẹni tó bá sọ pé òun wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa rìn bí ẹni yẹn ṣe rìn.+
7 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, àṣẹ tí mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín kì í ṣe tuntun, àmọ́ ó jẹ́ àṣẹ àtijọ́ tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀.+ Àṣẹ àtijọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ gbọ́.
8 Síbẹ̀, àṣẹ tuntun ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín, ó jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ àti nínú tiyín, torí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti tàn báyìí.+
9 Ẹni tó bá sọ pé òun wà nínú ìmọ́lẹ̀, síbẹ̀ tó kórìíra+ arákùnrin rẹ̀, inú òkùnkùn ló ṣì wà.+
10 Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀ nínú rẹ̀.
11 Àmọ́ ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn, ó ń rìn nínú òkùnkùn,+ kò sì mọ ibi tó ń lọ,+ torí òkùnkùn ò jẹ́ kó ríran.
12 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, mò ń kọ̀wé sí yín torí a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.+
13 Mò ń kọ̀wé sí ẹ̀yin bàbá, torí ẹ ti wá mọ ẹni tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀. Mò ń kọ̀wé sí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, torí ẹ ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+ Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin ọmọdé, torí ẹ ti wá mọ Baba.+
14 Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin bàbá, torí ẹ ti wá mọ ẹni tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀. Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, torí ẹ jẹ́ alágbára,+ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú yín,+ ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+
15 Ẹ má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé tàbí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé.+ Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, kò ní ìfẹ́ Baba;+
16 torí gbogbo ohun tó wà nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú+ àti fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn*—kò wá látọ̀dọ̀ Baba, àmọ́ ó wá látọ̀dọ̀ ayé.
17 Bákan náà, ayé ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.+
18 Ẹ̀yin ọmọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí, bí ẹ sì ṣe gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀,+ kódà ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ti fara hàn báyìí,+ ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí lóòótọ́.
19 Wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa, àmọ́ wọn kì í ṣe ara wa;*+ torí ká ní wọ́n jẹ́ ara wa ni, wọn ò ní fi wá sílẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa kó lè hàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló jẹ́ ara wa.+
20 Ẹni mímọ́ ti yàn yín,+ gbogbo yín sì ní ìmọ̀.
21 Kì í ṣe torí pé ẹ ò mọ òótọ́+ ni mo ṣe kọ̀wé sí yín, àmọ́ torí pé ẹ mọ̀ ọ́n àti pé kò sí irọ́ kankan nínú òótọ́.+
22 Ta ni òpùrọ́ tí kì í bá ṣe ẹni tó sọ pé Jésù kọ́ ni Kristi?+ Ẹni yìí ni aṣòdì sí Kristi,+ ẹni tó sẹ́ Baba àti Ọmọ.
23 Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ Ọmọ kò ní Baba.+ Ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun mọ Ọmọ+ ní Baba pẹ̀lú.+
24 Ní tiyín, àwọn nǹkan tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú yín.+ Tí àwọn nǹkan tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ kò bá kúrò nínú yín, ẹ̀yin àti Ọmọ máa wà ní ìṣọ̀kan, ẹ sì máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.
25 Bákan náà, ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún wa ni ìyè àìnípẹ̀kun.+
26 Torí àwọn tó fẹ́ ṣì yín lọ́nà ni mo ṣe kọ àwọn nǹkan yìí sí yín.
27 Ní tiyín, yíyàn tó yàn yín+ kò kúrò nínú yín, ẹ ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni máa kọ́ yín; àmọ́, yíyàn tó yàn yín ń kọ́ yín ní ohun gbogbo,+ òótọ́ ni, kì í ṣe irọ́. Kí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe kọ́ yín gẹ́lẹ́.+
28 Torí náà, ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ká lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà + nígbà tí a bá fi í hàn kedere, kí a má bàa fi ìtìjú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó bá wà níhìn-ín.
29 Tí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ tún máa mọ̀ pé gbogbo ẹni tó bá ń fi òdodo ṣe ìwà hù ni a bí látọ̀dọ̀ rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “agbẹnusọ.”
^ Tàbí “ètùtù; ohun tí a fi ń tuni lójú.”
^ Tàbí “fífi ohun téèyàn ní fọ́nnu.”
^ Tàbí “wọn kì í ṣe tiwa.”