Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 8:1-13
8 Ní báyìí, ní ti oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà:+ A mọ̀ pé gbogbo wa la ní ìmọ̀.+ Ìmọ̀ máa ń gbéra ga, àmọ́ ìfẹ́ ń gbéni ró.+
2 Tí ẹnì kan bá rò pé òun mọ ohun kan, kò tíì mọ̀ ọ́n bó ṣe yẹ kó mọ̀ ọ́n.
3 Àmọ́ tí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run mọ ẹni náà.
4 Ní báyìí, ní ti jíjẹ oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé òrìṣà kò jẹ́ nǹkan kan+ nínú ayé àti pé kò sí Ọlọ́run míì àfi ọ̀kan ṣoṣo.+
5 Torí bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí à ń pè ní ọlọ́run wà, ì báà jẹ́ ní ọ̀run tàbí ní ayé,+ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” àti ọ̀pọ̀ “olúwa” ṣe wà,
6 ní tiwa, Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà,+ Baba,+ ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, tí àwa náà sì wà fún un;+ Olúwa kan ló wà, Jésù Kristi, ipasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo fi wà,+ tí àwa náà sì wà nípasẹ̀ rẹ̀.
7 Síbẹ̀, gbogbo èèyàn kọ́ ló mọ̀ bẹ́ẹ̀.+ Ní ti àwọn kan, torí pé òrìṣà ni wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, wọ́n máa ń wo oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ bí ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ èyí sì ń da ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò lágbára láàmú.*+
8 Àmọ́ oúnjẹ kọ́ ló máa mú wa sún mọ́ Ọlọ́run;+ tí a kò bá jẹun, kò bù wá kù, tí a bá sì jẹun, kò sọ wá di ẹni ńlá.+
9 Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyè sára, kí ẹ̀tọ́ tí ẹ ní láti yan ohun tó wù yín má di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tó jẹ́ aláìlera.+
10 Nítorí bí ẹnì kan bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun nínú tẹ́ńpìlì òrìṣà, ṣé kò ní mú kí ẹ̀rí ọkàn ẹni yẹn le débi pé á lọ jẹ oúnjẹ tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà?
11 Torí náà, ìmọ̀ rẹ ló mú kí ẹni tó jẹ́ aláìlera ṣègbé, arákùnrin rẹ tí Kristi kú fún.+
12 Tí ẹ bá ṣẹ àwọn arákùnrin yín lọ́nà yìí, tí ẹ sì kó bá ẹ̀rí ọkàn+ wọn tí kò lágbára, Kristi lẹ ṣẹ̀ sí.
13 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tí oúnjẹ bá máa mú arákùnrin mi kọsẹ̀, mi ò ní jẹ ẹran mọ́ láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “sọ ẹ̀rí ọkàn wọn tí kò lágbára di ẹlẹ́gbin.”