Ìwé Kìíní Pétérù 5:1-14
5 Torí náà, bí èmi náà ti jẹ́ alàgbà, tí mo fojú ara mi rí àwọn ìyà tí Kristi jẹ, tí mo sì máa pín nínú ògo tí a máa ṣí payá,+ mò ń rọ àwọn alàgbà tó wà láàárín yín* pé:
2 Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run+ tó wà níkàáwọ́ yín, kí ẹ máa ṣe alábòójútó,* kì í ṣe tipátipá àmọ́ kó jẹ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; + kó má ṣe jẹ́ nítorí èrè tí kò tọ́,+ àmọ́ kí ẹ máa fi ìtara ṣe é látọkàn wá;
3 ẹ má ṣe jẹ ọ̀gá lórí àwọn tó jẹ́ ogún Ọlọ́run,+ àmọ́ kí ẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.+
4 Tí a bá sì fi olórí olùṣọ́ àgùntàn+ hàn kedere, ẹ máa gba adé ògo tí kì í ṣá.+
5 Bákan náà, kí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin máa tẹrí ba fún àwọn àgbà ọkùnrin.*+ Àmọ́ kí gbogbo yín gbé ìrẹ̀lẹ̀* wọ̀* nínú àjọṣe yín, torí Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.+
6 Torí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kó lè gbé yín ga ní àkókò tó yẹ,+
7 ẹ máa kó gbogbo àníyàn* yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ torí ó ń bójú tó yín.*+
8 Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò!+ Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá yín ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tó ń ké ramúramù, ó ń wá bó ṣe máa pani jẹ.*+
9 Àmọ́ ẹ kọjú ìjà sí i,+ kí ẹ dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ mọ̀ pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará yín* nínú ayé.+
10 Àmọ́ lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run onínúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tó pè yín sí ògo àìlópin rẹ̀+ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun,+ ó máa sọ yín di alágbára,+ ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.
11 Kí agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
12 Mo fi ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí mo kọ yìí ránṣẹ́ sí yín nípasẹ̀ Sílífánù,*+ arákùnrin olóòótọ́, kí n lè fún yín níṣìírí, kí n sì lè jẹ́rìí taratara pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìyí. Ẹ dúró gbọn-in nínú rẹ̀.
13 Obìnrin tó wà ní Bábílónì, tó jẹ́ àyànfẹ́ bíi tiyín ń kí yín. Máàkù+ ọmọ mi náà ń kí yín.
14 Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.
Kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi ní àlàáfíà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gba àwọn alàgbà tó wà láàárín yín níyànjú.”
^ Tàbí “ẹ máa tọ́jú wọn dáadáa.”
^ Tàbí “àwọn alàgbà.”
^ Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
^ Tàbí “fi ìrẹ̀lẹ̀ di ara yín lámùrè.”
^ Tàbí “ohun tó ń jẹ yín lọ́kàn; ìdààmú.”
^ Tàbí “ó bìkítà fún yín.”
^ Tàbí “ó ń wá ẹni tó máa pa jẹ.”
^ Ní Grk., “ẹgbẹ́ àwọn ará yín.”
^ Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.