Sámúẹ́lì Kìíní 1:1-28
1 Ọkùnrin kan wà, ó wá láti ìlú Ramataimu-sófíímù*+ ní agbègbè olókè Éfúrémù,+ orúkọ rẹ̀ ni Ẹlikénà,+ ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfì, ó jẹ́ ará Éfúrémù.
2 Ó ní ìyàwó méjì, ọ̀kan ń jẹ́ Hánà, èkejì sì ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò bímọ.
3 Lọ́dọọdún, ọkùnrin yẹn máa ń lọ láti ìlú rẹ̀ sí Ṣílò+ láti jọ́sìn,* kó sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ibẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ ti ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+
4 Lọ́jọ́ kan tí Ẹlikénà rúbọ, ó pín lára ẹran tó fi rúbọ fún Pẹ̀nínà ìyàwó rẹ̀ àti gbogbo ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀,+
5 ṣùgbọ́n ó fún Hánà ní ìpín kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, torí pé Hánà ló fẹ́ràn jù, àmọ́ Jèhófà kò tíì fún Hánà ní ọmọ.*
6 Yàtọ̀ síyẹn, orogún rẹ̀ ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i nítorí pé Jèhófà kò tíì fún un ní ọmọ.
7 Ohun tó máa ń ṣe nìyẹn lọ́dọọdún, nígbàkigbà tí Hánà bá lọ sí ilé Jèhófà,+ orogún rẹ̀ máa ń pẹ̀gàn rẹ̀ débi pé ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun.
8 Àmọ́ Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Hánà, kí ló ń pa ẹ́ lẹ́kún, kí ló dé tó ò jẹun, kí ló ń bà ẹ́ nínú jẹ́?* Ṣé mi ò sàn ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ fún ọ ni?”
9 Nígbà náà, Hánà dìde lẹ́yìn tí wọ́n ti parí jíjẹ àti mímu ní Ṣílò. Ní àkókò yẹn, àlùfáà Élì jókòó lórí ìjókòó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì*+ Jèhófà.
10 Inú Hánà bà jẹ́* gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sì ń sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
11 Ó wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, tí o bá bojú wo ìnira tó dé bá ìránṣẹ́ rẹ, tí o rántí mi, tí o kò gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ, tí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọ ọkùnrin,+ ṣe ni màá fi fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kan orí rẹ̀.”+
12 Ní gbogbo àkókò tó fi ń gbàdúrà níwájú Jèhófà, Élì ń wo ẹnu rẹ̀.
13 Hánà ń gbàdúrà nínú ọkàn rẹ̀, ètè rẹ̀ nìkan ló ń mì, a kò sì gbọ́ ohùn rẹ̀. Torí náà, Élì rò pé ó mutí yó ni.
14 Élì sọ fún un pé: “Ìgbà wo ni ọtí máa tó dá lójú rẹ? Má mutí mọ́.”
15 Ni Hánà bá dáhùn pé: “Kò rí bẹ́ẹ̀, olúwa mi! Ìdààmú ńlá ló bá mi;* kì í ṣe pé mo mu wáìnì tàbí ọtí kankan, ohun tó wà lọ́kàn mi ni mò ń tú jáde níwájú Jèhófà.+
16 Má rò pé obìnrin tí kò ní láárí ni ìránṣẹ́ rẹ, àdúrà ni mò ń gbà títí di báyìí nítorí ìrora àti ìdààmú ńlá tó dé bá mi.”
17 Ni Élì bá dáhùn pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fún ọ ní ohun tí o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”+
18 Hánà fèsì pé: “Kí ìránṣẹ́ rẹ rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ.” Obìnrin náà sì bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.
19 Lẹ́yìn náà, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, wọ́n forí balẹ̀ níwájú Jèhófà, wọ́n sì pa dà sí ilé wọn ní Rámà.+ Ẹlikénà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Hánà ìyàwó rẹ̀, Jèhófà sì ṣíjú àánú wò ó.*+
20 Láàárín ọdún kan,* Hánà lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ+ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì,* torí ó sọ pé, “ọwọ́ Jèhófà ni mo ti béèrè rẹ̀.”
21 Nígbà tó yá, Ẹlikénà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀ lọ láti rú ẹbọ ọdọọdún sí Jèhófà,+ kí ó sì mú ọrẹ tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ wá.
22 Àmọ́ Hánà kò lọ,+ torí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé: “Gbàrà tí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọdékùnrin náà, màá mú un wá, á fara hàn níwájú Jèhófà, á sì máa gbé ibẹ̀ láti ìgbà náà lọ.”+
23 Ẹlikénà ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ohun tí o bá mọ̀ pé ó dára jù* ni kí o ṣe. Dúró sí ilé títí wàá fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí Jèhófà jẹ́ kó rí bí o ṣe sọ.” Torí náà, obìnrin náà dúró sí ilé, ó sì ń tọ́jú ọmọ rẹ̀ títí ó fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.
24 Gbàrà tó gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, ó mú un lọ sí Ṣílò pẹ̀lú akọ màlúù ọlọ́dún mẹ́ta àti ìyẹ̀fun tó kún òṣùwọ̀n eéfà* kan àti ìṣà* wáìnì+ ńlá kan. Ó wá sí ilé Jèhófà ní Ṣílò,+ ó sì mú ọmọdékùnrin náà dání.
25 Wọ́n pa akọ màlúù náà, wọ́n sì mú ọmọdékùnrin náà wá sọ́dọ̀ Élì.
26 Hánà wá sọ fún Élì pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi! Bí o ti wà láàyè,* olúwa mi, èmi ni obìnrin tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ ní ibí yìí láti gbàdúrà sí Jèhófà.+
27 Ọmọdékùnrin yìí ni mo gbàdúrà nípa rẹ̀, Jèhófà sì fún mi ní ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+
28 Èmi náà sì wá láti fi í fún Jèhófà. Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló máa fi jẹ́ ti Jèhófà.”
Ọkùnrin náà* sì forí balẹ̀ níbẹ̀ fún Jèhófà.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “láti Rámà, ó jẹ́ ará Súfì.”
^ Tàbí “forí balẹ̀.”
^ Ní Héb., “ti sé ilé ọmọ Hánà.”
^ Tàbí “lọ́kàn jẹ́?”
^ Ìyẹn, àgọ́ ìjọsìn.
^ Tàbí “Ọkàn Hánà gbọgbẹ́.”
^ Tàbí “Obìnrin tí ìnira ńlá bá ẹ̀mí rẹ̀ ni mí.”
^ Ní Héb., “rántí rẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Nígbà tó yá.”
^ Ó túmọ̀ sí “Orúkọ Ọlọ́run.”
^ Ní Héb., “Ohun tó bá dára ní ojú rẹ.”
^ Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
^ Ó dà bíi jọ́ọ̀gì omi.
^ Tàbí “Bí ọkàn rẹ ti wà láàyè.”
^ Ó ṣe kedere pé Ẹlikénà ló ń tọ́ka sí.