Ìwé Kìíní sí Tímótì 6:1-21
6 Kí àwọn tó jẹ́ ẹrú* máa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn olúwa wọn,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù nípa orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.+
2 Bákan náà, kí àwọn tí olúwa wọn jẹ́ onígbàgbọ́ má ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí wọn torí wọ́n jẹ́ ará. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe ìránṣẹ́, torí àwọn tó ń jàǹfààní iṣẹ́ ìsìn rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti àyànfẹ́.
Túbọ̀ máa fi nǹkan wọ̀nyí kọ́ni, kí o sì máa gbani níyànjú.
3 Tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀kọ́ míì kọ́ni, tí kò sì fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ tó wá látọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti ẹ̀kọ́ tó bá ìfọkànsin Ọlọ́run mu,+
4 ó ń gbéra ga, kò sì lóye ohunkóhun.+ Ìjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀ ló gbà á lọ́kàn.*+ Àwọn nǹkan yìí máa ń fa owú, wàhálà, bíbanijẹ́,* ìfura burúkú,
5 ṣíṣe awuyewuye lemọ́lemọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan láàárín àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́,+ tí wọn ò mọ òtítọ́, tí wọ́n sì ń ronú pé èrè ni ìfọkànsin Ọlọ́run wà fún.+
6 Lóòótọ́, èrè ńlá wà nínú ìfọkànsin Ọlọ́run+ téèyàn bá ní ìtẹ́lọ́rùn.*
7 Torí a ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.+
8 Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ* àti aṣọ,* àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.+
9 Àmọ́ àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ máa ń kó sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn+ àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára, èyí tó ń mú kí àwọn èèyàn pa run kí wọ́n sì ṣègbé.+
10 Torí ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá, àwọn kan tí wọ́n sì ní irú ìfẹ́ yìí ti ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.+
11 Àmọ́, ìwọ tí o jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, sá fún àwọn nǹkan yìí. Ṣùgbọ́n máa wá òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà àti ìwà tútù.+
12 Ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́; di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí, èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́, tí o sì wàásù rẹ̀ dáadáa ní gbangba lójú ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí.
13 Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, ẹni tó pa ohun gbogbo mọ́ láàyè àti Kristi Jésù, ẹlẹ́rìí tó wàásù dáadáa ní gbangba níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,+
14 pé kí o pa àṣẹ náà mọ́ láìní àbààwọ́n àti láìlẹ́gàn títí di ìgbà tí Olúwa wa Jésù Kristi máa fara hàn,+
15 èyí tí ẹni tó jẹ́ aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga máa fi hàn nígbà tí àwọn àkókò rẹ̀ bá tó. Òun ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,+
16 ẹnì kan ṣoṣo tó ní àìkú,+ ẹni tó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,+ tí èèyàn kankan kò rí rí, tí wọn ò sì lè rí.+ Òun ni kí ọlá àti agbára ayérayé jẹ́ tirẹ̀. Àmín.
17 Sọ* fún àwọn ọlọ́rọ̀ inú ètò àwọn nǹkan yìí* pé kí wọ́n má ṣe gbéra ga,* kí wọ́n má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí kò dáni lójú,+ àmọ́ lé Ọlọ́run, ẹni tó ń pèsè gbogbo ohun tí à ń gbádùn fún wa lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.+
18 Sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe rere, àní kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere, kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́,* kí wọ́n ṣe tán láti máa fúnni,+
19 kí wọ́n máa to ìṣúra tí kò lè díbàjẹ́ jọ láti fi ṣe ìpìlẹ̀ tó dáa fún ọjọ́ iwájú,+ kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.+
20 Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ,+ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́ àti àwọn ohun tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn pè ní “ìmọ̀” èyí tó ń ta ko òtítọ́.+
21 Àwọn kan sì ti kúrò nínú ìgbàgbọ́ torí wọ́n ń fi irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn.
Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú rẹ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “tó wà lábẹ́ àjàgà ẹrú.”
^ Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
^ Tàbí “Ó nífẹ̀ẹ́ òdì fún jíjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ èébú.”
^ Ní Grk., “ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”
^ Tàbí “ohun ìgbẹ́mìíró.”
^ Tàbí “ibùgbé.” Ní Grk., “ìbora.”
^ Tàbí “ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ.”
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Pàṣẹ.”
^ Tàbí “kí wọ́n má ṣe háwọ́.”