Sámúẹ́lì Kejì 22:1-51

  • Dáfídì yin Ọlọ́run nítorí ìgbàlà tí ó ṣe (1-51)

    • “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi” (2)

    • Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn adúróṣinṣin (26)

22  Dáfídì kọ ọ̀rọ̀ yìí lórin+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀+ àti lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+  Ó sọ pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò+ mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀.+   Ọlọ́run mi ni àpáta+ mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,Apata+ mi àti ìwo* ìgbàlà mi,* ibi ààbò+ mi,*Àti ibi tí mo lè sá sí,+ olùgbàlà+ mi; ìwọ tí o gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.   Mo ké pe Jèhófà, ẹni tí ìyìn yẹ,Yóò sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.   Ikú yí mi ká bí ìgbì òkun;+Àwọn ọkùnrin tí kò ní láárí ya lù mí bí omi.+   Àwọn okùn Isà Òkú* yí mi ká;+Ikú dẹ pańpẹ́ síwájú mi.+   Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+Mo sì ń pe Ọlọ́run mi. Nígbà náà, ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,Igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+   Ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì síwá-sẹ́yìn, ó sì ń mì jìgìjìgì;+Àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run mì tìtì+Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+   Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,Iná tó ń jóni run jáde láti ẹnu rẹ̀,+Ẹyin iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 10  Ó tẹ ọ̀run wálẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀,+Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 11  Ó gun kérúbù,+ ó sì ń fò bọ̀. A rí i lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+ 12  Ó wá fi òkùnkùn bò ó bí àgọ́,+Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀. 13  Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀ ni ẹyin iná ti ń jó. 14  Nígbà náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sán ààrá láti ọ̀run;+Ẹni Gíga Jù Lọ mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀.+ 15  Ó ta àwọn ọfà+ rẹ̀, ó sì tú wọn ká;Mànàmáná kọ, ó sì kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 16  Ìsàlẹ̀ òkun hàn síta;+Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí Jèhófà,Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ̀.+ 17  Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+ 18  Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ. 19  Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi. 20  Ó mú mi jáde wá sí ibi ààbò;*+Ó gbà mí sílẹ̀ nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.+ 21  Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi;+Ó san èrè fún mi nítorí pé ọwọ́ mi mọ́.*+ 22  Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,Mi ò hùwà burúkú, kí n wá fi Ọlọ́run mi sílẹ̀. 23  Gbogbo ìdájọ́ rẹ̀+ wà ní iwájú mi;Mi ò ní yà kúrò nínú àwọn òfin rẹ̀.+ 24  Màá jẹ́ aláìlẹ́bi+ níwájú rẹ̀,Màá sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+ 25  Kí Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi +Àti nítorí mo jẹ́ aláìṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀.+ 26  Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin;+Ìwọ ń hùwà àìlẹ́bi sí akíkanjú ọkùnrin aláìlẹ́bi;+ 27  Ìwọ jẹ́ mímọ́ sí ẹni tí ó mọ́,+Àmọ́ ìwọ ń jẹ́ kí àwọn oníbékebèke mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n.*+ 28  Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀ là,+Ṣùgbọ́n o kì í fi ojú rere wo àwọn agbéraga, o sì ń rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.+ 29  Jèhófà, ìwọ ni fìtílà mi,+Jèhófà ló sì ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.+ 30  Ìrànlọ́wọ́ rẹ ni mo fi lè gbéjà ko àwọn jàǹdùkú;*Agbára Ọlọ́run ni mo fi lè gun ògiri.+ 31  Pípé ni ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́;+Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+ Apata ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.+ 32  Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+ Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+ 33  Ọlọ́run tòótọ́ ni odi ààbò mi tó lágbára,+Yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé.+ 34  Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+ 35  Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe. 36  O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là,Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá. + 37  O fẹ ọ̀nà fún ẹsẹ̀ mi;Kí ẹsẹ̀* mi má bàa yọ̀.+ 38  Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì pa wọ́n run;Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́. 39  Màá pa wọ́n run, màá sì fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má bàa gbérí mọ́;+Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi. 40  Wàá fún mi lókun láti jagun,+Wàá sì mú kí àwọn ọ̀tá mi ṣubú sábẹ́ mi.+ 41  Wàá mú kí àwọn ọ̀tá mi pa dà lẹ́yìn mi;*+Màá pa àwọn tó kórìíra mi run.*+ 42  Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.+ 43  Màá gún wọn kúnná bí eruku ilẹ̀;Màá lọ̀ wọ́n, màá sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà. 44  Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn mi tó ń wá àléébù.+ Wàá ṣọ́ mi kí n lè di olórí àwọn orílẹ̀-èdè;+Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+ 45  Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi;+Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nípa mi á mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi.* 46  Ọkàn àwọn àjèjì á domi;*Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn. 47  Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+ Kí a gbé Ọlọ́run tó jẹ́ àpáta ìgbàlà mi ga.+ 48  Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi;+ 49  Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ìwọ gbé mi lékè+ àwọn tó ń gbéjà kò mí;O gbà mí lọ́wọ́ oníwà ipá.+ 50  Ìdí nìyẹn tí màá fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Màá sì fi orin yin*+ orúkọ rẹ: 51  Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà* ńlá fún ọba rẹ̀;+Ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,Sí Dáfídì àti àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ títí láé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “olùgbàlà mi tó lágbára.”
Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ìyẹ́ afẹ́fẹ́.”
Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
Tàbí “mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “ìwọ ń ṣe bí ẹni tí kò gbọ́n sí àwọn oníbékebèke.”
Tàbí “akónilẹ́rù.”
Tàbí “ọrùn ẹsẹ̀.”
Tàbí “Wàá jẹ́ kí n gbá ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá mi mú.”
Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”
Ní Héb., “Tí wọ́n bá gbọ́ ìró mi, wọ́n á ṣègbọràn sí mi.”
Tàbí “Àwọn àjèjì á pòórá.”
Tàbí “kọ orin sí.”
Tàbí “ìṣẹ́gun.”
Ní Héb., “èso.”