Diutarónómì 32:1-52
32 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, màá sì sọ̀rọ̀;Kí ayé sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 Ìtọ́ni mi máa rọ̀ bí òjò;Ọ̀rọ̀ mi á sì sẹ̀ bí ìrì,Bí òjò winniwinni sórí koríkoÀti ọ̀wààrà òjò sórí ewéko.
3 Torí màá kéde orúkọ Jèhófà.+
Ẹ sọ bí Ọlọ́run+ wa ṣe tóbi tó!
4 Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ̀,Torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo+ ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.
Ọlọ́run olóòótọ́,+ tí kì í ṣe ojúsàájú;+Olódodo àti adúróṣinṣin ni.+
5 Àwọn ló hùwà ìbàjẹ́.+
Wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀, àwọn ló kan àbùkù.+
Ìran alárèékérekè àti oníbékebèke ni wọ́n!+
6 Ṣé bó ṣe yẹ kí ẹ ṣe sí Jèhófà+ nìyí,Ẹ̀yin òmùgọ̀ àti aláìlọ́gbọ́n èèyàn?+
Ṣebí òun ni Bàbá yín tó mú kí ẹ wà,+Ẹni tó dá yín, tó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in?
7 Ẹ rántí ìgbà àtijọ́;Ẹ ronú nípa ọdún àwọn ìran tó ti kọjá.
Bi bàbá rẹ, á sì sọ fún ọ;+Bi àwọn àgbààgbà rẹ, wọ́n á sì jẹ́ kí o mọ̀.
8 Nígbà tí Ẹni Gíga Jù Lọ fún àwọn orílẹ̀-èdè ní ogún+ wọn,Nígbà tó ya àwọn ọmọ Ádámù* sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,+Ó pààlà fún àwọn èèyàn+Gẹ́gẹ́ bí iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
9 Torí àwọn èèyàn Jèhófà ni ìpín+ rẹ̀;Jékọ́bù ni ogún+ rẹ̀.
10 Ó rí i nínú aginjù,+Ní aṣálẹ̀,+ tó ṣófo, tó ń hu.
Ó yí i ká kó lè dáàbò bò ó, ó tọ́jú rẹ̀,+Ó sì ṣọ́ ọ bí ọmọlójú+ rẹ̀.
11 Bí ẹyẹ idì ṣe ń ru ìtẹ́ rẹ̀ sókè,Tó ń rá bàbà lórí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́,Tó ń na àwọn ìyẹ́ rẹ̀ jáde láti fi gbé wọn,Tó ń gbé wọn sórí apá+ rẹ̀,
12 Jèhófà nìkan ló ń darí rẹ̀;*+Kò sí ọlọ́run àjèjì kankan pẹ̀lú rẹ̀.+
13 Ó mú kó gun àwọn ibi gíga+ ayé,Kó lè jẹ irè oko.+
Ó fi oyin inú àpáta bọ́ ọÀti òróró látinú akọ àpáta,
14 Bọ́tà ọ̀wọ́ ẹran àti wàrà agbo ẹran,Pẹ̀lú àgùntàn tó dáa jù,*Àwọn àgbò Báṣánì àti àwọn òbúkọ,Pẹ̀lú àlìkámà*+ tó dáa jù;*O sì mu wáìnì tó tinú ẹ̀jẹ̀* èso àjàrà jáde.
15 Nígbà tí Jéṣúrúnì* sanra tán, ó di ọlọ̀tẹ̀, ó sì ń tàpá.
O ti sanra, o ti ki, o sì ti kún.+
Ó wá pa Ọlọ́run tì, ẹni tó dá a,+Ó sì fojú àbùkù wo Àpáta ìgbàlà rẹ̀.
16 Wọ́n fi àwọn ọlọ́run àjèjì+ mú un bínú;Wọ́n ń fi àwọn ohun ìríra+ múnú bí i.
17 Àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run,+Wọ́n ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀,Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí,Sí àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín ò mọ̀.
18 O gbàgbé Àpáta+ tó jẹ́ bàbá rẹ,O ò sì rántí Ọlọ́run tó bí ọ.+
19 Nígbà tí Jèhófà rí i, ó kọ̀ wọ́n,+Torí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́.
20 Ó wá sọ pé, ‘Màá fojú pa mọ́ fún wọn;+Màá wo ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn.
Torí ìran oníwà burúkú ni wọ́n,+Àwọn aláìṣòótọ́ ọmọ.+
21 Wọ́n ti fi ohun tí kì í ṣe ọlọ́run+ mú mi bínú;*Wọ́n ti fi àwọn òrìṣà+ wọn tí kò ní láárí múnú bí mi.
Torí náà, màá fi àwọn tí kì í ṣe èèyàn+ mú kí wọ́n jowú;Màá fi orílẹ̀-èdè òmùgọ̀+ mú wọn bínú.
22 Torí ìbínú mi ti mú kí iná+ sọ,Ó sì máa jó wọnú Isà Òkú,*+Ó máa jó ayé àti èso rẹ̀ run,Iná á sì ran ìpìlẹ̀ àwọn òkè.
23 Màá fi kún àwọn ìyọnu wọn;Màá sì ta gbogbo ọfà mi lù wọ́n.
24 Ebi+ máa tán wọn lókun,Akọ ibà máa gbé wọn mì, wọ́n á sì pa run+ pátápátá.
Màá rán eyín àwọn ẹranko sí wọn,+Àti oró àwọn ẹran tó ń fàyà fà lórí ilẹ̀.
25 Ní ìta, idà máa mú kí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wọ́n;+Nínú ilé, jìnnìjìnnì+ á bò wọ́n,Ọ̀dọ́kùnrin àti wúńdíá,Ọmọ ọwọ́ àti ẹni tó ní ewú lórí.+
26 Ǹ bá sọ pé: “Màá tú wọn ká;Màá mú kí àwọn èèyàn gbàgbé wọn,”
27 Tí kì í bá ṣe pé mò ń bẹ̀rù ohun tí ọ̀tá máa ṣe,+Torí àwọn elénìní lè túmọ̀ rẹ̀ sí nǹkan míì.+
Wọ́n lè sọ pé: “Ọwọ́ wa ti mókè;+Jèhófà kọ́ ló ṣe gbogbo èyí.”
28 Torí orílẹ̀-èdè tí kò ní làákàyè* ni wọ́n,Kò sí ẹni tó ní òye láàárín wọn.+
29 Ká sọ pé wọ́n gbọ́n ni!+ Wọn ì bá ro ọ̀rọ̀ yìí dáadáa.+
Kí wọ́n ro ibi tó máa já sí.+
30 Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún kan (1,000),Kí ẹni méjì sì mú kí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sá?+
Tí kì í bá ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,+Tí Jèhófà sì ti fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́.
31 Torí àpáta wọn kò dà bí Àpáta+ wa,Àwọn ọ̀tá wa pàápàá ti mọ èyí.+
32 Torí inú àjàrà Sódómù ni àjàrà wọn ti wá
Àti látinú ilẹ̀ onípele Gòmórà.+
Àwọn èso àjàrà onímájèlé ni èso àjàrà wọn,Àwọn òṣùṣù wọn korò.+
33 Oró ejò ni wáìnì wọn,Oró burúkú àwọn ṣèbé.
34 Ṣebí ọ̀dọ̀ mi ni mo tọ́jú rẹ̀ sí,Tí mo sé e mọ́ ilé ìkẹ́rùsí+ mi?
35 Tèmi ni ẹ̀san àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀,+Ní àkókò náà tí ẹsẹ̀ wọn máa yọ̀ tẹ̀rẹ́,+Torí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,Ohun tó sì ń dúró dè wọ́n máa tètè dé.’
36 Torí Jèhófà máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn+ rẹ̀,Ó sì máa káàánú* àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,Tó bá rí i pé okun wọn ti ń tán,Tó sì rí i pé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àtàwọn tó ti rẹ̀ ló ṣẹ́ kù.
37 Ó máa wá sọ pé, ‘Àwọn ọlọ́run+ wọn dà,Àpáta tí wọ́n sá di,
38 Tó máa ń jẹ ọ̀rá àwọn ẹbọ wọn,*Tó ń mu wáìnì ọrẹ ohun mímu+ wọn?
Jẹ́ kí wọ́n dìde wá ràn yín lọ́wọ́.Kí wọ́n di ibi ààbò fún yín.
39 Ẹ rí i báyìí pé èmi, àní èmi ni ẹni náà,+Kò sí ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+
Mo lè pani, mo sì lè sọni di alààyè.+
Mo lè dá ọgbẹ́+ síni lára, mo sì lè woni sàn,+Kò sí ẹnì kankan tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.+
40 Torí mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ọ̀run,Mo sì búra pé: “Bí mo ti wà láàyè títí láé,”+
41 Tí mo bá pọ́n idà mi tó ń kọ mànà,Tí mo sì múra ọwọ́ mi sílẹ̀ láti ṣèdájọ́,+Màá san àwọn ọ̀tá+ mi lẹ́san,Màá sì fìyà jẹ àwọn tó kórìíra mi.
42 Màá mú kí ọfà mi mu ẹ̀jẹ̀ yó,Idà mi á sì jẹ ẹran,
Pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa àti àwọn ẹrú,Pẹ̀lú orí àwọn aṣáájú ọ̀tá.’
43 Ẹ bá àwọn èèyàn+ rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Torí ó máa gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,Ó máa san àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ lẹ́san,Ó sì máa ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀.”*
44 Mósè ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí àwọn èèyàn+ náà létí, òun àti Hóṣéà*+ ọmọ Núnì.
45 Lẹ́yìn tí Mósè bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tán,
46 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo fi kìlọ̀ fún yín lónìí+ sọ́kàn, kí ẹ lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín pé, kí wọ́n rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin+ yìí.
47 Torí èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí kò wúlò fún yín, àmọ́ òun ló máa mú kí ẹ wà láàyè,+ ọ̀rọ̀ yìí sì máa mú kí ẹ̀mí yín gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.”
48 Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ yìí kan náà pé:
49 “Gun òkè Ábárímù+ yìí lọ, Òkè Nébò,+ tó wà ní ilẹ̀ Móábù, tó dojú kọ Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénáánì, tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kó di tiwọn.+
50 O máa kú sórí òkè tí o fẹ́ gùn yìí, a ó sì kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,* bí Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ṣe kú sórí Òkè Hóórì+ gẹ́lẹ́, tí wọ́n sì kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀,
51 torí pé ẹ̀yin méjèèjì kò jẹ́ olóòótọ́ sí mi láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, níbi omi Mẹ́ríbà+ ti Kádéṣì ní aginjù Síínì, torí pé ẹ ò fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
52 Ọ̀ọ́kán ni wàá ti rí ilẹ̀ náà, àmọ́ o ò ní wọ ilẹ̀ tí mo fẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “ìran èèyàn.”
^ Ìyẹn, Jékọ́bù.
^ Ní Héb., “ọ̀rá àgùntàn.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Ní Héb., “ọ̀rá kíndìnrín àlìkámà.”
^ Tàbí “omi.”
^ Ó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” orúkọ oyè tí wọ́n fún Ísírẹ́lì.
^ Tàbí “mú kí n jowú.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “tó kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn.”
^ Tàbí “pèrò dà nípa.”
^ Tàbí “ẹbọ wọn tó dáa jù.”
^ Tàbí “wẹ ilẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́.”
^ Orúkọ tí Jóṣúà ń jẹ́ gangan. Hóṣéà ni ìkékúrú Hòṣáyà, ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Jáà Gbà Là; Jáà Ti Gbà Là.”
^ Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.