Sí Àwọn Ará Fílípì 2:1-30
2 Nígbà náà, tí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi, tí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, tí àjọṣe tẹ̀mí* èyíkéyìí bá wà, tí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú bá wà,
2 ẹ jẹ́ kí èrò yín àti ìfẹ́ yín ṣọ̀kan kí ẹ lè mú ayọ̀ mi kún, kí ẹ wà níṣọ̀kan délẹ̀délẹ̀,* kí ẹ sì ní èrò kan náà lọ́kàn.+
3 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú+ tàbí ìgbéraga+ mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀* máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ,+
4 bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì,+ kì í ṣe tiyín nìkan.+
5 Ẹ ní èrò yìí nínú yín, irú èyí tí Kristi Jésù náà ní,+
6 ẹni tó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run,+ kò ronú rárá láti já nǹkan gbà, ìyẹn, pé kó bá Ọlọ́run dọ́gba.+
7 Ó tì o, àmọ́ ó fi gbogbo ohun tó ní sílẹ̀, ó gbé ìrísí ẹrú wọ̀,+ ó sì di èèyàn.*+
8 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tó wá ní ìrí èèyàn,* ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ojú ikú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.*+
9 Torí ìdí yìí gan-an ni Ọlọ́run ṣe gbé e sí ipò gíga,+ tó sì fún un ní orúkọ tó lékè gbogbo orúkọ mìíràn,+
10 kó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù, kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ti àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà láyé pẹ̀lú àwọn tó wà lábẹ́ ilẹ̀,+
11 kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa+ fún ògo Ọlọ́run tó jẹ́ Baba.
12 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, bí ẹ ṣe ń ṣègbọràn ní gbogbo ìgbà, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, àmọ́ ní báyìí, ẹ túbọ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mi ò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.
13 Torí Ọlọ́run ni ẹni tó ń fún yín lágbára nítorí ìdùnnú rẹ̀, ó ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.
14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú+ àti ìjiyàn,+
15 kí ẹ lè jẹ́ aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́ mímọ́, ọmọ Ọlọ́run+ tí kò ní àbààwọ́n láàárín ìran onímàgòmágó àti oníwà ìbàjẹ́,+ láàárín àwọn tí ẹ ti ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé,+
16 bí ẹ ṣe ń di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.+ Nígbà náà, màá lè ní ìdí láti yọ̀ ní ọjọ́ Kristi, bí mo ṣe mọ̀ pé mi ò sáré lásán, mi ò sì ṣiṣẹ́ kára lásán.
17 Àmọ́, bí a tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu+ sórí ẹbọ+ àti iṣẹ́ mímọ́* tí ìgbàgbọ́ yín ń mú kí ẹ ṣe, inú mi ń dùn, mo sì bá gbogbo yín yọ̀.
18 Bákan náà, ó yẹ kí inú tiyín náà máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
19 Ní báyìí, mo ní ìrètí pé, tí Jésù Olúwa bá fẹ́, màá rán Tímótì+ sí yín láìpẹ́, kí ara mi lè yá gágá nígbà tí mo bá gbọ́ ìròyìn nípa yín.
20 Nítorí mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi tirẹ̀ tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín.
21 Torí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Jésù Kristi.
22 Àmọ́, ẹ mọ ẹ̀rí tó fi hàn nípa ara rẹ̀, pé bí ọmọ+ lọ́dọ̀ bàbá ni ó ṣẹrú pẹ̀lú mi kí ìhìn rere lè máa tẹ̀ síwájú.
23 Nítorí náà, òun ni mo retí pé màá rán ní gbàrà tí mo bá ti mọ ibi tí ọ̀rọ̀ mi máa já sí.
24 Lóòótọ́, ó dá mi lójú nínú Olúwa pé èmi fúnra mi máa wá láìpẹ́.+
25 Àmọ́ ní báyìí, mo rí i pé á dáa kí n rán Ẹpafíródítù sí yín, arákùnrin mi tí a jọ ń ṣiṣẹ́ àti ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ó tún jẹ́ aṣojú yín àti ìránṣẹ́ tó ń bá mi ṣe ohun tí mo bá fẹ́ ṣe,+
26 nítorí ó ń wù ú láti rí gbogbo yín, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn torí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn.
27 Òótọ́ ni pé ó ṣàìsàn débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú; àmọ́ Ọlọ́run ṣàánú rẹ̀, kódà, kì í ṣe òun nìkan, ó ṣàánú èmi náà, kí n má bàa ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́.
28 Nítorí náà, mò ń rán an ní kíá láìjáfara, kí inú yín lè dùn lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tí ẹ bá rí i, kí àníyàn tèmi náà sì lè dín kù.
29 Torí náà, ẹ fi ayọ̀ gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ bí ẹ ṣe máa ń gba àwọn ọmọlẹ́yìn Olúwa, ẹ sì máa ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n,+
30 torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nítorí iṣẹ́ Kristi,* ó fi ẹ̀mí* rẹ̀ wewu kó lè ṣe àwọn ohun tí ẹ̀yin ì bá ṣe fún mi ká ní ẹ wà níbí.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “àjọpín nínú ẹ̀mí.”
^ Tàbí “kí ọkàn yín ṣọ̀kan.”
^ Tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.”
^ Ní Grk., “ó sì wá wà ní ìrí èèyàn.”
^ Ní Grk., “nígbà tó rí ara rẹ̀ ní ìrísí èèyàn.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “iṣẹ́ fún àwọn èèyàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “iṣẹ́ Olúwa.”
^ Tàbí “ọkàn.”