Àkọsílẹ̀ Jòhánù 5:1-47
5 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, àjọyọ̀ kan + tí àwọn Júù máa ń ṣe wáyé, Jésù sì gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù.
2 Adágún omi kan wà ní Jerúsálẹ́mù níbi Ibodè Àgùntàn+ tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà lédè Hébérù, ó ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* márùn-ún.
3 Inú ibẹ̀ ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn aláìsàn, afọ́jú, arọ àti àwọn tó rọ lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ dùbúlẹ̀ sí.
4 * ——
5 Àmọ́ ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì (38).
6 Jésù rí ọkùnrin yìí tó dùbúlẹ̀ síbẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tó ti ń ṣàìsàn, ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Ṣé o fẹ́ kí ara rẹ yá?”+
7 Ọkùnrin aláìsàn náà dá a lóhùn pé: “Ọ̀gá, mi ò lẹ́ni tó lè gbé mi sínú adágún omi náà tó bá ti rú, torí tí n bá ti ń lọ síbẹ̀, ẹlòmíì á ti sọ̀ kalẹ̀ ṣáájú mi.”
8 Jésù sọ fún un pé: “Dìde! Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.”+
9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ara ọkùnrin náà yá, ó gbé ẹní* rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.
Ọjọ́ Sábáàtì ni.
10 Torí náà, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọkùnrin tó wò sàn náà pé: “Sábáàtì nìyí, kò sì bófin mu fún ọ láti gbé ẹní* náà.”+
11 Àmọ́ ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹni tó wò mí sàn náà ló sọ fún mi pé, ‘Gbé ẹní* rẹ, kí o sì máa rìn.’”
12 Wọ́n bi í pé: “Ta lẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Gbé e, kí o sì máa rìn’?”
13 Àmọ́ ọkùnrin tí ara rẹ̀ ti yá náà ò mọ ẹni náà, torí Jésù ti wọ àárín àwọn èrò tó wà níbẹ̀.
14 Lẹ́yìn náà, Jésù rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ara rẹ ti yá. Má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí nǹkan tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ sí ọ.”
15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé Jésù ló wo òun sàn.
16 Torí èyí, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí Jésù, torí pé ó ń ṣe àwọn nǹkan yìí lọ́jọ́ Sábáàtì.
17 Àmọ́, ó dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di báyìí, èmi náà ṣì ń ṣiṣẹ́.”+
18 Ìdí nìyí tí àwọn Júù fi túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, torí kì í ṣe pé kò pa Sábáàtì mọ́ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń pe Ọlọ́run ní Baba rẹ̀,+ ó ń sọ pé òun àti Ọlọ́run dọ́gba.+
19 Torí náà, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Ọmọ ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀, àfi ohun tó bá rí tí Baba ń ṣe nìkan.+ Torí ohunkóhun tí Ẹni yẹn bá ṣe, àwọn nǹkan yìí ni Ọmọ náà ń ṣe lọ́nà kan náà.
20 Torí Baba ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọmọ,+ ó sì ń fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án, ó sì máa fi àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju èyí lọ hàn án, kí ẹnu lè yà yín.+
21 Torí bí Baba ṣe ń jí àwọn òkú dìde gẹ́lẹ́, tó sì ń mú kí wọ́n wà láàyè,+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ń sọ àwọn tí òun bá fẹ́ di alààyè.+
22 Torí Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni, àmọ́ ó ti fi gbogbo ìdájọ́ lé Ọmọ lọ́wọ́,+
23 kí gbogbo ẹ̀dá lè máa bọlá fún Ọmọ bí wọ́n ṣe ń bọlá fún Baba. Ẹnikẹ́ni tí kò bá bọlá fún Ọmọ, kò bọlá fún Baba tó rán an.+
24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.+
25 “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú máa gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, tí àwọn tó fiyè sílẹ̀ sì máa yè.
26 Torí bí Baba ṣe ní ìyè nínú ara rẹ̀,*+ bẹ́ẹ̀ náà ló yọ̀ǹda fún Ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀.+
27 Ó sì ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́,+ torí òun ni Ọmọ èèyàn.+
28 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀,+
29 tí wọ́n á sì jáde wá, àwọn tó ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.+
30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+
31 “Tí èmi nìkan bá jẹ́rìí nípa ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òótọ́.+
32 Ẹlòmíì wà tó ń jẹ́rìí nípa mi, mo sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tó ń jẹ́ nípa mi.+
33 Ẹ ti rán àwọn èèyàn sí Jòhánù, ó sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.+
34 Àmọ́ mi ò gba ẹ̀rí látọ̀dọ̀ èèyàn, ṣùgbọ́n mo sọ àwọn nǹkan yìí kí ẹ lè rígbàlà.
35 Fìtílà tó ń jó, tó sì ń tàn yòò ni ọkùnrin yẹn, ó sì wù yín pé kí ẹ yọ̀ gidigidi nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀.+
36 Àmọ́ mo ní ẹ̀rí tó tóbi ju ti Jòhánù lọ, torí àwọn iṣẹ́ tí Baba mi yàn fún mi pé kí n ṣe, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí, ń jẹ́rìí sí i pé Baba ló rán mi.+
37 Baba tó sì rán mi ti fúnra rẹ̀ jẹ́rìí nípa mi.+ Ẹ ò tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, ẹ ò sì fojú rí bó ṣe rí,+
38 ẹ ò sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín, torí pé ẹ ò gba ẹni tó rán gbọ́.
39 “Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́,+ torí ẹ rò pé ó máa jẹ́ kí ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun; àwọn yìí* gan-an ló sì ń jẹ́rìí nípa mi.+
40 Síbẹ̀, ẹ ò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi+ kí ẹ lè ní ìyè.
41 Èmi kì í gba ògo látọ̀dọ̀ èèyàn,
42 àmọ́ mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín.
43 Mo wá ní orúkọ Baba mi, àmọ́ ẹ ò gbà mí. Tí ẹlòmíì bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ máa gba ẹni yẹn.
44 Báwo lẹ ṣe máa gbà gbọ́, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀ ń gba ògo látọ̀dọ̀ ara yín, ẹ ò sì wá ògo tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run+ kan ṣoṣo náà?
45 Ẹ má rò pé màá fẹ̀sùn kàn yín lọ́dọ̀ Baba; ẹnì kan wà tó ń fẹ̀sùn kàn yín, Mósè ni,+ ẹni tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé.
46 Àní, tí ẹ bá gba Mósè gbọ́, ẹ máa gbà mí gbọ́, torí ó kọ̀wé nípa mi.+
47 Àmọ́ tí ẹ ò bá gba ohun tó kọ gbọ́, báwo lẹ ṣe máa gba ohun tí mo sọ gbọ́?”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìloro.”
^ Tàbí “ibùsùn.”
^ Tàbí “ibùsùn.”
^ Tàbí “ibùsùn.”
^ Tàbí “ibùsùn.”
^ Tàbí “ṣe ní ẹ̀bùn ìwàláàyè nínú ara rẹ̀.”
^ Ìyẹn, Ìwé Mímọ́.