Àkọsílẹ̀ Lúùkù 17:1-37
17 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò sí bí àwọn ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ ò ṣe ní wá. Àmọ́, ẹni tí wọ́n tipasẹ̀ rẹ̀ wá gbé!
2 Ó máa sàn fún un gan-an tí wọ́n bá so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, tí wọ́n sì jù ú sínú òkun ju pé kó mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré yìí kọsẹ̀.+
3 Ẹ kíyè sí ara yín. Tí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, bá a wí,+ tó bá sì ronú pìwà dà, dárí jì í.+
4 Kódà, tó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́, tó sì pa dà wá bá ọ ní ìgbà méje, tó ń sọ pé, ‘Mo ti ronú pìwà dà,’ o gbọ́dọ̀ dárí jì í.”+
5 Àwọn àpọ́sítélì wá sọ fún Olúwa pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”+
6 Olúwa wá sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún igi mọ́líbẹ́rì dúdú yìí pé, ‘Fà tu, kí o sì lọ fìdí sọlẹ̀ sínú òkun!’ ó sì máa gbọ́ tiyín.+
7 “Èwo nínú yín, tó ní ẹrú kan tó ń túlẹ̀ tàbí tó ń tọ́jú agbo ẹran, ló máa sọ fún un tó bá dé láti oko pé, ‘Máa bọ̀ níbí kíá, kí o sì wá jẹun lórí tábìlì’?
8 Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣebí ó máa sọ fún un pé, ‘Ṣètò nǹkan fún mi kí n lè jẹ oúnjẹ alẹ́, gbé épírọ́ọ̀nù kan wọ̀, kí o sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi títí màá fi parí jíjẹ àti mímu, lẹ́yìn náà o wá lè jẹ, kí o sì mu’?
9 Kò ní dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹrú náà, torí pé iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un ló ṣe, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Bákan náà, tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún yín, kí ẹ sọ pé: ‘Ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun ni wá. Ohun tó yẹ ká ṣe ni a ṣe.’”+
11 Nígbà tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó gba àárín Samáríà àti Gálílì kọjá.
12 Bó sì ṣe ń wọ abúlé kan, ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n ní àrùn ẹ̀tẹ̀ wá pàdé rẹ̀, àmọ́ wọ́n dúró lókèèrè.+
13 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọ pé: “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú wa!”
14 Nígbà tó rí wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.”+ Bí wọ́n ṣe ń lọ, ara wọn mọ́.+
15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé ara òun ti yá, ó pa dà, ó sì gbóhùn sókè, ó yin Ọlọ́run lógo.
16 Ó sì wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ Jésù, ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ará Samáríà ni.+
17 Jésù fún un lésì pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá la wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ibo làwọn mẹ́sàn-án yòókù wà?
18 Ṣé kò sí ẹlòmíì tó pa dà wá yin Ọlọ́run lógo yàtọ̀ sí ọkùnrin yìí tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ni?”
19 Ó wá sọ fún un pé: “Dìde, kí o sì máa lọ; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+
20 Nígbà tí àwọn Farisí bi í nípa ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀,+ ó dá wọn lóhùn pé: “Dídé Ìjọba Ọlọ́run kò ní pàfiyèsí tó ṣàrà ọ̀tọ̀;
21 àwọn èèyàn ò sì ní máa sọ pé, ‘Wò ó níbí!’ tàbí, ‘Lọ́hùn-ún!’ Torí pé, wò ó! Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.”+
22 Ó wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ọjọ́ ń bọ̀ tó máa wù yín pé kí ẹ rí ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn, àmọ́ ẹ ò ní rí i.
23 Àwọn èèyàn á máa sọ fún yín pé, ‘Wò ó lọ́hùn-ún!’ tàbí, ‘Wò ó níbí!’ Ẹ má ṣe jáde lọ, ẹ má sì sáré tẹ̀ lé wọn.+
24 Torí bí mànàmáná ṣe ń kọ láti apá kan ọ̀run dé apá ibòmíì ní ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ èèyàn+ máa rí ní ọjọ́ rẹ̀.+
25 Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ jìyà púpọ̀, ìran yìí sì máa kọ̀ ọ́.+
26 Bákan náà, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rí ní àwọn ọjọ́ Ọmọ èèyàn:+
27 wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, à ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì,+ Ìkún Omi sì dé, ó pa gbogbo wọn run.+
28 Bákan náà, bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ní àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì:+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé.
29 Àmọ́ lọ́jọ́ tí Lọ́ọ̀tì kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.+
30 Bẹ́ẹ̀ náà ló máa rí ní ọjọ́ tí a bá ṣí Ọmọ èèyàn payá.+
31 “Ní ọjọ́ yẹn, kí ẹni tó wà lórí ilé, àmọ́ tí àwọn ohun ìní rẹ̀ wà nínú ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó o, bákan náà, ẹni tó bá wà nínú pápá ò gbọ́dọ̀ pa dà sí àwọn ohun tó wà lẹ́yìn.
32 Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.+
33 Ẹnikẹ́ni tó bá ń wá bó ṣe máa dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀ máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù rẹ̀ máa pa á mọ́ láàyè.+
34 Mò ń sọ fún yín, ní òru yẹn, ẹni méjì máa wà lórí ibùsùn kan náà; a máa mú ọ̀kan lọ, àmọ́ a máa pa ìkejì tì.+
35 Obìnrin méjì á máa lọ nǹkan lórí ọlọ kan náà; a máa mú ọ̀kan lọ, àmọ́ a máa pa ìkejì tì.”
36 * ——
37 Torí náà, wọ́n dá a lóhùn pé: “Ibo ni, Olúwa?” Ó sọ fún wọn pé: “Ibi tí òkú bá wà, ibẹ̀ náà ni àwọn ẹyẹ idì máa kóra jọ sí.”+