Àkọsílẹ̀ Mátíù 12:1-50
12 Ní àkókò yẹn, Jésù gba oko ọkà kọjá ní Sábáàtì. Ebi wá ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn erín ọkà* jẹ.+
2 Nígbà tí àwọn Farisí rí èyí, wọ́n sọ fún un pé: “Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu lọ́jọ́ Sábáàtì.”+
3 Ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+
4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,*+ èyí tí kò bófin mu fún òun àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?+
5 Àbí ẹ ò tíì kà á nínú Òfin pé ní àwọn Sábáàtì, àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì sọ Sábáàtì di aláìmọ́, a ò sì dá wọn lẹ́bi?+
6 Àmọ́ mo sọ fún yín pé ohun kan tó tóbi ju tẹ́ńpìlì lọ wà níbí.+
7 Ṣùgbọ́n ká ní ẹ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni, ‘Àánú ni mo fẹ́,+ kì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ ò ní dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.
8 Torí Ọmọ èèyàn ni Olúwa Sábáàtì.”+
9 Lẹ́yìn tó kúrò níbẹ̀, ó lọ sínú sínágọ́gù wọn,
10 wò ó! ọkùnrin kan wà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ!+ Kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án, wọ́n bi í pé, “Ṣé ó bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní Sábáàtì?”+
11 Ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá ní àgùntàn kan, tí àgùntàn náà sì já sínú kòtò ní Sábáàtì, ṣé ẹnì kan wà nínú yín tí kò ní dì í mú, kó sì gbé e jáde?+
12 Ṣé èèyàn ò wá ṣeyebíye ju àgùntàn lọ? Torí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tó dáa ní Sábáàtì.”
13 Ó wá sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa dà rí bíi ti ọwọ́ kejì.
14 Àmọ́ àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
15 Nígbà tí Jésù mọ èyí, ó kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn tún tẹ̀ lé e,+ ó sì wo gbogbo wọn sàn,
16 àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun,+
17 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé:
18 “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí mo* tẹ́wọ́ gbà!+ Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀,+ ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè.
19 Kò ní jiyàn,+ kò ní pariwo, ẹnikẹ́ni ò sì ní gbọ́ ohùn rẹ̀ láwọn ọ̀nà tó wà ní gbangba.
20 Kò ní fọ́ esùsú* kankan tó ti ṣẹ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú,+ tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe, títí ó fi máa ṣe ìdájọ́ òdodo láṣeyọrí.
21 Ní tòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè máa ní ìrètí nínú orúkọ rẹ̀.”+
22 Lẹ́yìn náà, wọ́n mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ọkùnrin náà fọ́jú, kò sì lè sọ̀rọ̀. Ó wo ọkùnrin náà sàn, ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì ń ríran.
23 Ó ya gbogbo èrò náà lẹ́nu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Ṣé kì í ṣe Ọmọ Dáfídì nìyí?”
24 Nígbà tí àwọn Farisí gbọ́ èyí, wọ́n sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí kò lè lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí kò bá ní agbára Béélísébúbù,* alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”+
25 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tó bá pínyà sí ara rẹ̀ máa pa run, gbogbo ìlú tàbí ilé tó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kò ní dúró.
26 Lọ́nà kan náà, tí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀ nìyẹn; báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe máa wá dúró?
27 Bákan náà, tó bá jẹ́ agbára Béélísébúbù ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọ́n fi máa jẹ́ adájọ́ yín.
28 Àmọ́ tó bá jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni mo fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, Ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì lóòótọ́.+
29 Àbí báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbógun wọ ilé ọkùnrin alágbára, kó sì fipá gba àwọn ohun ìní rẹ̀, tí kò bá kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà mọ́lẹ̀? Ìgbà yẹn ló máa tó lè kó o lẹ́rù nínú ilé rẹ̀.
30 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí lọ́dọ̀ mi ń ta kò mí, ẹnikẹ́ni tí kò bá sì dara pọ̀ mọ́ mi ń fọ́n ká.+
31 “Nítorí èyí, mò ń sọ fún yín pé, gbogbo oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì la máa dárí rẹ̀ ji àwọn èèyàn, àmọ́ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí kò ní ìdáríjì.+
32 Bí àpẹẹrẹ, ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ èèyàn máa rí ìdáríjì;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò ní rí ìdáríjì, àní, nínú ètò àwọn nǹkan yìí* tàbí èyí tó ń bọ̀.+
33 “Nínú kí ẹ mú kí igi dára, kí èso rẹ̀ sì dára, àbí kí ẹ mú kí igi jẹrà, kí èso rẹ̀ sì jẹrà, torí èso igi la fi ń mọ igi.+
34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo lẹ ṣe lè sọ àwọn ohun tó dáa nígbà tó jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín? Torí lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.+
35 Ẹni rere máa ń mú ohun rere jáde látinú ìṣúra rere rẹ̀, àmọ́ ẹni burúkú máa ń mú ohun burúkú jáde látinú ìṣúra burúkú rẹ̀.+
36 Mò ń sọ fún yín pé ní Ọjọ́ Ìdájọ́, àwọn èèyàn máa jíhìn+ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò wúlò tí wọ́n sọ;
37 torí ọ̀rọ̀ yín la máa fi pè yín ní olódodo, ọ̀rọ̀ yín la sì máa fi dá yín lẹ́bi.”
38 Àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wá fún un lésì pé: “Olùkọ́, a fẹ́ rí àmì kan látọ̀dọ̀ rẹ.”+
39 Ó sọ fún wọn pé: “Ìran burúkú àti alágbèrè* kò yéé wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan àfi àmì wòlíì Jónà.+
40 Bí Jónà ṣe wà nínú ikùn ẹja ńlá náà fún ọjọ́ mẹ́ta,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ èèyàn máa wà ní àárín ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.+
41 Àwọn ará Nínéfè máa dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, wọ́n á sì dá a lẹ́bi, torí pé wọ́n ronú pìwà dà nígbà tí Jónà wàásù fún wọn.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Jónà lọ wà níbí.+
42 A máa gbé ọbabìnrin gúúsù dìde láti ṣèdájọ́ ìran yìí, ó sì máa dá a lẹ́bi, torí ó wá láti ìkángun ayé kó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n Sólómọ́nì.+ Àmọ́ ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.+
43 “Tí ẹ̀mí àìmọ́ kan bá jáde nínú ẹnì kan, á gba àwọn ibi tí kò lómi kọjá láti wá ibi ìsinmi, àmọ́ kò ní rí ìkankan.+
44 Á wá sọ pé, ‘Màá pa dà lọ sí ilé mi tí mo ti kúrò,’ tó bá sì dé, á rí i pé ilé náà ṣófo, àmọ́ wọ́n ti gbá a mọ́, wọ́n sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.
45 Á wá lọ mú ẹ̀mí méje míì dání, tí wọ́n burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí wọ́n bá sì wọlé, wọ́n á máa gbé ibẹ̀; ipò ẹni yẹn nígbẹ̀yìn á wá burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.+ Bó ṣe máa rí fún ìran burúkú yìí náà nìyẹn.”
46 Nígbà tó ṣì ń bá àwọn èrò náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ dúró síta, wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa bá a sọ̀rọ̀.+
47 Ẹnì kan wá sọ fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró níta, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”
48 Ó dá ẹni tó bá a sọ̀rọ̀ lóhùn pé: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?”
49 Ó wá na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé: “Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+
50 Torí ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tó wà ní ọ̀run, ẹni yẹn ni arákùnrin mi, arábìnrin mi àti ìyá mi.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, orí ọkà.
^ Tàbí “búrẹ́dì àfihàn.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ìyẹn, koríko etí omi.
^ Orúkọ tí wọ́n ń pe Sátánì.
^ Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “aláìṣòótọ́.”
^ Ní Grk., “ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.”