Àkọsílẹ̀ Mátíù 20:1-34

  • Àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà àjàrà gba iye owó kan náà (1-16)

  • Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (17-19)

  • Wọ́n ń wá ipò nínú Ìjọba náà (20-28)

    • Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn (28)

  • Ó wo ọkùnrin afọ́jú méjì sàn (29-34)

20  “Torí Ìjọba ọ̀run dà bíi baálé ilé kan tó jáde lọ ní àárọ̀ kùtù láti gba àwọn òṣìṣẹ́ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.+  Lẹ́yìn tó bá àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣàdéhùn pé òun máa fún wọn ní owó dínárì* kan fún ọjọ́ kan, ó ní kí wọ́n lọ sínú ọgbà àjàrà òun.  Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹta,* ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró ní ibi ọjà, tí wọn ò ríṣẹ́ ṣe;  ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, màá sì fún yín ní ohunkóhun tó bá tọ́.’  Torí náà, wọ́n lọ. Ó tún jáde ní nǹkan bíi wákàtí kẹfà* àti wákàtí kẹsàn-án,* ó sì ṣe ohun kan náà.  Níkẹyìn, ní nǹkan bíi wákàtí kọkànlá,* ó jáde lọ, ó sì rí àwọn míì tí wọ́n dúró, ó sọ fún wọn pé, ‘Kí ló dé tí ẹ dúró síbí látàárọ̀, tí ẹ ò ríṣẹ́ ṣe?’  Wọ́n sọ fún un pé, ‘Torí kò sẹ́ni tó gbà wá síṣẹ́ ni.’ Ó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’  “Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà sọ fún ọkùnrin tó fi ṣe alábòójútó pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o sì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn,+ bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn tó dé kẹ́yìn títí dórí àwọn ẹni àkọ́kọ́.’  Nígbà tí àwọn ọkùnrin tó dé ní wákàtí kọkànlá wá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì* kan. 10  Nígbà tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ wá dé, wọ́n rò pé àwọn máa gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, àmọ́ owó dínárì* kan ni wọ́n san fún àwọn náà. 11  Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé fún baálé ilé náà, 12  wọ́n sì sọ pé, ‘Iṣẹ́ wákàtí kan ni àwọn tó dé kẹ́yìn yìí ṣe; síbẹ̀ iye kan náà lo fún àwa tí a ṣiṣẹ́ kára látàárọ̀ nínú ooru tó mú gan-an!’ 13  Àmọ́ ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, mi ò hùwà àìtọ́ sí ọ. Àdéhùn owó dínárì* kan la jọ ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 14  Gba ohun tó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ. Iye tí mo fún ẹni tó dé kẹ́yìn yìí náà ni màá fún ọ. 15  Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àwọn nǹkan mi ṣe ohun tó wù mí ni? Àbí ṣé ojú rẹ ń ṣe ìlara* torí mo jẹ́ ẹni rere* ni?’+ 16  Lọ́nà yìí, àwọn ẹni ìkẹyìn máa di ẹni àkọ́kọ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì máa di ẹni ìkẹyìn.”+ 17  Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá (12) náà sí ẹ̀gbẹ́ kan láwọn nìkan, ó sì sọ fún wọn lójú ọ̀nà pé:+ 18  “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un,+ 19  wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi;+ a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 20  Ìyá àwọn ọmọ Sébédè+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ wá bá a, obìnrin náà tẹrí ba* fún un, ó sì béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.+ 21  Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo fẹ́?” Ó fèsì pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”+ 22  Jésù dáhùn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mo máa tó mu?”+ Wọ́n sọ fún un pé: “A lè mu ún.” 23  Ó sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa mu ife mi,+ àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí Baba mi ti ṣètò rẹ̀ fún.”+ 24  Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bínú sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà.+ 25  Àmọ́ Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn.+ 26  Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín;+ àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín,+ 27  ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+ 28  Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ èèyàn ò ṣe wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kó sì fi ẹ̀mí* rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”+ 29  Bí wọ́n ṣe ń kúrò ní Jẹ́ríkò, èrò rẹpẹtẹ tẹ̀ lé e. 30  Wò ó! àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!”+ 31  Àmọ́ àwọn èrò náà bá wọn wí, wọ́n ní kí wọ́n dákẹ́; àmọ́ ṣe ni wọ́n tún ń kígbe sókè pé: “Olúwa, ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì!” 32  Torí náà, Jésù dúró, ó pè wọ́n, ó sì sọ pé: “Kí lẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 33  Wọ́n sọ fún un pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.” 34  Àánú wọn ṣe Jésù, ó sì fọwọ́ kan ojú wọn,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n pa dà ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀.
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán.
Ìyẹn, nǹkan bí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.
Ní Grk., “burú.”
Tàbí “jẹ́ ọ̀làwọ́.”
Tàbí “forí balẹ̀.”
Tàbí “ọkàn.”