Nọ́ńbà 27:1-23
27 Àwọn ọmọ Sélóféhádì+ wá sí tòsí, Sélóféhádì yìí ni ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè, látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù. Orúkọ àwọn ọmọ Sélóféhádì ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà.
2 Wọ́n dúró síwájú Mósè, àlùfáà Élíásárì, àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àpéjọ náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì sọ pé:
3 “Bàbá wa ti kú ní aginjù, àmọ́ kò sí lára àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jèhófà, àwọn tó ti Kórà+ lẹ́yìn. Torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ṣe kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan.
4 Kí ló dé tí orúkọ bàbá wa fi máa pa rẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ torí pé kò bímọ ọkùnrin? Fún wa ní ohun ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.”
5 Mósè wá mú ọ̀rọ̀ wọn tọ Jèhófà+ lọ.
6 Jèhófà sọ fún Mósè pé:
7 “Òótọ́ làwọn ọmọ Sélóféhádì sọ. Rí i pé o fún wọn ní ohun ìní tí wọ́n lè jogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, kí o sì mú kí ogún bàbá wọn di tiwọn.+
8 Kí o wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú láì bímọ ọkùnrin, kí ẹ jẹ́ kí ogún rẹ̀ di ti ọmọbìnrin rẹ̀.
9 Tí kò bá sì bímọ obìnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ogún rẹ̀.
10 Tí kò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin bàbá rẹ̀ ní ogún rẹ̀.
11 Tí bàbá rẹ̀ ò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù ní ogún rẹ̀, yóò sì di tirẹ̀. Èyí ni àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa tẹ̀ lé láti ṣèdájọ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.’”
12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Gun orí òkè Ábárímù+ yìí, kí o sì wo ilẹ̀ tí màá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
13 Tí o bá ti rí i, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,*+ bíi ti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ,+
14 torí nígbà tí àpéjọ náà ń bá mi jà ní aginjù Síínì, ẹ ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ tipasẹ̀ omi+ náà fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ níṣojú wọn. Èyí ni omi Mẹ́ríbà+ tó wà ní Kádéṣì + ní aginjù Síínì.”+
15 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé:
16 “Kí Jèhófà, Ọlọ́run tó ni ẹ̀mí gbogbo èèyàn* yan ọkùnrin kan ṣe olórí àpéjọ náà,
17 ẹni tí yóò máa jáde, tí yóò sì máa wọlé níwájú wọn, tí yóò máa darí wọn jáde, tí yóò sì máa kó wọn wọlé, kí àpéjọ àwọn èèyàn Jèhófà má bàa dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”
18 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.+
19 Kí o wá mú un dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti gbogbo àpéjọ, kí o sì fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ níṣojú+ wọn.
20 Kí o sì fún un+ lára àṣẹ* tí o ní, kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa gbọ́ tirẹ̀.+
21 Á sì máa dúró níwájú àlùfáà Élíásárì, ẹni tí yóò máa bá a ṣe ìwádìí níwájú Jèhófà nípasẹ̀ ohun tí Úrímù+ bá sọ. Àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń jáde, àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú gbogbo àpéjọ náà.”
22 Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́. Ó mú Jóṣúà dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti níwájú gbogbo àpéjọ náà,
23 ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì fa iṣẹ́ lé e+ lọ́wọ́ bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè+ sọ gẹ́lẹ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
^ Ní Héb., “ẹ̀mí gbogbo ẹran ara.”
^ Tàbí “iyì.”