Nehemáyà 10:1-39
10 Àwọn tó fọwọ́ sí i, tí wọ́n sì gbé èdìdì wọn lé e+ ni:
Nehemáyà, tó jẹ́ gómìnà,* ọmọ Hakaláyà
Àti Sedekáyà,
2 Seráyà, Asaráyà, Jeremáyà,
3 Páṣúrì, Amaráyà, Málíkíjà,
4 Hátúṣì, Ṣebanáyà, Málúkù,
5 Hárímù,+ Mérémótì, Ọbadáyà,
6 Dáníẹ́lì,+ Gínétónì, Bárúkù,
7 Méṣúlámù, Ábíjà, Míjámínì,
8 Maasáyà, Bílígáì àti Ṣemáyà; àwọn yìí jẹ́ àlùfáà.
9 Àwọn ọmọ Léfì tó fọwọ́ sí i ni: Jéṣúà ọmọ Asanáyà, Bínúì látinú àwọn ọmọ Hénádádì, Kádímíélì+
10 àti arákùnrin wọn Ṣebanáyà, Hodáyà, Kélítà, Pẹláyà, Hánánì,
11 Máíkà, Réhóbù, Haṣabáyà,
12 Sákúrì, Ṣerebáyà,+ Ṣebanáyà,
13 Hodáyà, Bánì àti Bẹnínù.
14 Àwọn olórí àwọn èèyàn náà tó fọwọ́ sí i ni: Páróṣì, Pahati-móábù,+ Élámù, Sátù, Bánì,
15 Búnì, Ásígádì, Bébáì,
16 Ádóníjà, Bígífáì, Ádínì,
17 Átérì, Hẹsikáyà, Ásúrì,
18 Hodáyà, Háṣúmù, Bísáì,
19 Hárífù, Ánátótì, Nébáì,
20 Mágípíáṣì, Méṣúlámù, Hésírì,
21 Meṣesábélì, Sádókù, Jádúà,
22 Pẹlatáyà, Hánánì, Ánáyà,
23 Hóṣéà, Hananáyà, Háṣúbù,
24 Hálóhéṣì, Pílíhà, Ṣóbékì,
25 Réhúmù, Háṣábínà, Maaseáyà,
26 Áhíjà, Hánánì, Ánánì,
27 Málúkù, Hárímù àti Báánà.
28 Ìyókù àwọn èèyàn náà, ìyẹn àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì* àti gbogbo àwọn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wọn ká kí wọ́n lè pa Òfin Ọlọ́run tòótọ́ mọ́,+ pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn, gbogbo àwọn tó ní ìmọ̀ àti òye,*
29 dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn olókìkí àárín wọn, wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé wọ́n á máa rìn nínú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, èyí tó wá nípasẹ̀ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ àti pé àwọn á rí i pé àwọn ń pa gbogbo àṣẹ Jèhófà Olúwa wa mọ́ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀.
30 A kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, a kò sì ní fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.+
31 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá kó ọjà tàbí oríṣiríṣi ọkà wá ní ọjọ́ Sábáàtì, a kò ní ra ohunkóhun lọ́wọ́ wọn ní Sábáàtì+ tàbí ní ọjọ́ mímọ́.+ A tún máa fi irè oko wa tó bá jáde ní ọdún keje+ sílẹ̀ àti gbogbo gbèsè tí ẹnikẹ́ni bá jẹ wá.+
32 Bákan náà, a gbé àṣẹ kan kalẹ̀ fún ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé, a ó máa mú ìdá mẹ́ta ṣékélì* wá lọ́dọọdún fún iṣẹ́ ìsìn ilé* Ọlọ́run wa,+
33 fún búrẹ́dì onípele,*+ ọrẹ ọkà ìgbà gbogbo,+ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ti Sábáàtì+ pẹ̀lú ti òṣùpá tuntun+ àti fún àwọn àsè tí a yàn,+ àwọn ohun mímọ́ àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ láti ṣe ètùtù fún Ísírẹ́lì àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa.
34 A tún ṣẹ́ kèké lórí bí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn èèyàn náà á ṣe máa mú igi wá sí ilé Ọlọ́run wa, ní agboolé-agboolé àwọn bàbá wa, ní àkókò tí a yàn lọ́dọọdún, láti máa fi dáná lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin.+
35 A ó tún máa mú àkọ́so èso ilẹ̀ wa àti àkọ́so èso oríṣiríṣi igi wá lọ́dọọdún sí ilé Jèhófà+
36 àti àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa àti ti ẹran ọ̀sìn wa+ pẹ̀lú àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran wa àti ti agbo ẹran wa bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin. A ó mú wọn wá sí ilé Ọlọ́run wa, sọ́dọ̀ àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run wa.+
37 Bákan náà, a ó máa mú àkọ́so ọkà tí a kò lọ̀ kúnná+ wá àti àwọn ọrẹ pẹ̀lú èso oríṣiríṣi igi+ àti wáìnì tuntun pẹ̀lú òróró,+ a ó sì kó wọn wá fún àwọn àlùfáà ní àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ní ilé Ọlọ́run wa,+ a ó sì kó ìdá mẹ́wàá irè oko ilẹ̀ wa fún àwọn ọmọ Léfì,+ torí àwọn ni wọ́n ń gba ìdá mẹ́wàá ní gbogbo ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀.
38 Kí àlùfáà, ọmọ Áárónì, wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì mú ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá ti ilé Ọlọ́run wa,+ kí wọ́n sì kó o sí àwọn yàrá* tó wà ní ilé ìkẹ́rùsí.
39 Inú àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì máa mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá,+ ibẹ̀ sì ni kí àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ máa wà títí kan àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn akọrin. A kò sì ní pa ilé Ọlọ́run wa tì.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Tíṣátà,” orúkọ oyè tí àwọn ará Páṣíà fún gómìnà ìpínlẹ̀.
^ Tàbí “Nétínímù.” Ní Héb., “àwọn tí a fi fúnni.”
^ Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó dàgbà tó láti lóye.”
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Ìyẹn, búrẹ́dì àfihàn.
^ Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”
^ Tàbí “àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun.”