Sáàmù 138:1-8

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ga, ó ń ṣìkẹ́ èèyàn

    • ‘O dáhùn àdúrà mi’ (3)

    • ‘Bí mo tiẹ̀ wà nínú ewu, o gbà mí sílẹ̀’ (7)

Ti Dáfídì. 138  Màá fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́.+ Níṣojú àwọn ọlọ́run mìíràn,Màá kọ orin ìyìn.*  Màá forí balẹ̀ ní ìdojúkọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ,*+Màá sì yin orúkọ rẹ,+Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ. Torí o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ àti orúkọ rẹ ga ju gbogbo nǹkan míì lọ.*  Ní ọjọ́ tí mo pè, o dá mi lóhùn;+O mú kí n* nígboyà, o sì mú kí n lágbára.+  Gbogbo ọba ayé yóò yìn ọ́, Jèhófà,+Nítorí wọ́n á ti gbọ́ àwọn ìlérí tí o ṣe.  Wọ́n á máa fi àwọn ọ̀nà Jèhófà kọrin,Nítorí pé ògo Jèhófà pọ̀.+  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ga, ó ń kíyè sí àwọn onírẹ̀lẹ̀,+Àmọ́, ó jìnnà sí àwọn agbéraga.+  Bí mo bá tiẹ̀ ń rìn nínú ewu, wàá dá ẹ̀mí mi sí.+ O na ọwọ́ rẹ sórí àwọn ọ̀tá mi tó ń bínú;Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò gbà mí là.  Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn fún mi ṣẹ. Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà títí láé;+Má ṣe pa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “Láìfi ti àwọn ọlọ́run mìíràn pè, màá kọrin sí ọ.”
Tàbí “ibi mímọ́ rẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “o ti gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ ìwọ fúnra rẹ lọ.”
Tàbí “ọkàn mi.”