Sáàmù 28:1-9

  • Ọlọ́run gbọ́ àdúrà onísáàmù

    • “Jèhófà ni agbára mi àti apata mi” (7)

Ti Dáfídì. 28  Ìwọ ni mò ń ké pè, Jèhófà, Àpáta+ mi;Má di etí rẹ sí mi. Tí o ò bá dá mi lóhùn,Ṣe ni màá dà bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò.*+   Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́Bí mo ṣe ń gbé ọwọ́ mi sókè sí yàrá inú lọ́hùn-ún ti ibi mímọ́ rẹ.+   Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú àwọn ẹni ibi, pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ohun búburú,+Àwọn tó ń bá ọmọnìkejì wọn sọ̀rọ̀ àlàáfíà, àmọ́ tó jẹ́ pé ibi ló wà lọ́kàn wọn.+   San ohun tí wọ́n ṣe pa dà fún wọn,+Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ibi wọn. San iṣẹ́ ọwọ́ wọn pa dà fún wọn,Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ṣe.+   Nítorí pé wọn kò fiyè sí àwọn iṣẹ́ Jèhófà,+Wọn ò sì ka iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ sí.+ Yóò ya wọ́n lulẹ̀, kò sì ní gbé wọn ró.   Ìyìn ni fún Jèhófà,Torí ó ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.   Jèhófà ni agbára mi+ àti apata mi;+Òun ni ọkàn mi gbẹ́kẹ̀ lé.+ Ó ti ràn mí lọ́wọ́, ọkàn mi sì ń yọ̀,Torí náà, màá fi orin mi yìn ín.   Jèhófà ni agbára àwọn èèyàn rẹ̀;Ó jẹ́ ibi ààbò, ó ń fún ẹni àmì òróró rẹ̀ ní ìgbàlà ńlá.+   Gba àwọn èèyàn rẹ là, kí o sì bù kún ogún rẹ.+ Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn sí apá rẹ títí láé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “sàréè.”