Sáàmù 61:1-8

  • Ọlọ́run jẹ́ ilé gogoro alágbára sí àwọn ọ̀tá

    • “Màá wà nínú àgọ́ rẹ” (4)

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Ti Dáfídì. 61  Ọlọ́run, gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ mi. Fetí sí àdúrà mi.+   Màá ké pè ọ́ láti ìkángun ayéNígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá bá* ọkàn mi.+ Darí mi lọ sórí àpáta tó ga jù mí lọ.+   Nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi,Ilé gogoro alágbára tó ń dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.+   Màá wà* nínú àgọ́ rẹ títí láé;+Màá fi abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ ṣe ibi ààbò.+ (Sélà)   Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi. O ti fún mi ní ogún tó jẹ́ ti àwọn tó bẹ̀rù orúkọ rẹ.+   Wàá mú kí ẹ̀mí ọba gùn,*+Àwọn ọdún rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti ìran dé ìran.   Yóò jókòó lórí ìtẹ́* níwájú Ọlọ́run títí láé;+Fún un ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́,* kí wọ́n lè máa dáàbò bò ó.+   Nígbà náà, màá fi orin yin* orúkọ rẹ títí láé+Bí mo ṣe ń san àwọn ẹ̀jẹ́ mi láti ọjọ́ dé ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àárẹ̀ mú.”
Tàbí “Màá jẹ́ àlejò.”
Ní Héb., “fi kún ọjọ́ ayé ọba.”
Tàbí “máa gbé.”
Tàbí “Yan ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ fún un.”
Tàbí “kọ orin sí.”