Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èlíṣà sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.”​—2Ọb 6:16

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wa Pọ̀ Ju Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wọn

Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wa Pọ̀ Ju Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wọn

Àwọn ọmọ ogun ọ̀tá yí Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ ká (2Ọb 6:13, 14; it-1 716 ¶4)

Èlíṣà ò bẹ̀rù, ó sì fún ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun (2Ọb 6:15-17; w13 8/15 30 ¶2; wo àwòrán iwájú ìwé)

Jèhófà dáàbò bo Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu (2Ọb 6:18, 19; it-1 343 ¶1)

Àwọn ọ̀tá wa kéré sí Jèhófà gan-an. Ká sọ pé a lè rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run, ká sì rí bí Jèhófà ṣe ń lo àwọn áńgẹ́lì láti dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀, àá rí i pé kò sídìí fún wa láti bẹ̀rù.