Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ohun Tí Mo Lè Ṣe Táá Jẹ́ Ká Túbọ̀ Lórúkọ Rere

Ohun Tí Mo Lè Ṣe Táá Jẹ́ Ká Túbọ̀ Lórúkọ Rere

Àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (1Kọ 4:9) A lè bi ara wa pé, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti ìwà mi ń bọlá fún Jèhófà?’ (1Pe 2:12) Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orúkọ rere, ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba orúkọ rere wa jẹ́.—Onw 10:1.

Nínú àwọn ipò tá a tò sísàlẹ̀ yìí, kọ ohun tó yẹ kí Kristẹni kan ṣe àti ìlànà Bíbélì tó lè ràn án lọ́wọ́:

  • Ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fìbínú sọ̀rọ̀ sí ẹ

  • Tí mọ́tò rẹ bá dọ̀tí, tí ilé rẹ ò ṣeé rí tàbí tí aṣọ ẹ rí wúruwùru

  • Ìjọba ṣòfin kan tó ṣòro fún ẹ láti pa mọ́

Báwo làwọn tó ń ṣèwádìí ní Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ṣe ń mú ká túbọ̀ ní orúkọ rere?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́, A SÌ NÍ Ọ̀WỌ̀ TÓ JINLẸ̀ FÚN ÒTÍTỌ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ló wú ẹ lórí nínú gbogbo ohun tí ètò Ọlọ́run ń ṣe láti rí i dájú pé ohun tó péye tó sì jẹ́ òótọ́ là ń tẹ̀ jáde?