Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
“Ẹ TI GBỌ́ PÉ AṢÒDÌ SÍ KRISTI Ń BỌ̀.”—1 JÒHÁNÙ 2:18.
BÍ WỌ́N bá sọ fún ọ pé arúfin kan ń bọ̀ lọ́nà ibi tóo ń gbé, kí lo máa ṣe? Ó ṣeé ṣe kóo fẹ́ wádìí kínníkínní nípa bó ṣe rí àti ọgbọ́n tó ń lò. Ńṣe ni wàá wà lójúfò.
Bọ́ràn ṣe rí lónìí nìyẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù ti kìlọ̀ fún wa pé: “Gbogbo àgbéjáde onímìísí tí kò bá jẹ́wọ́ Jésù kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síwájú sí i, èyí ni àgbéjáde onímìísí ti aṣòdì sí Kristi èyí tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, nísinsìnyí ó ti wà ní ayé ná.” (1 Jòhánù 4:3) Ǹjẹ́ irú aṣòdì sí Kristi bẹ́ẹ̀, tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run tó sì ń tan àwọn èèyàn jẹ, tí kò jẹ́ káráyé rímú mí tiẹ̀ wà?
Ìgbà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jòhánù lo ọ̀rọ̀ náà “aṣòdì sí Kristi” nínú méjì lára àwọn lẹ́tà rẹ̀. Ó tọ́ka sí ẹni tó ń tako ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Jésù Kristi àti àwọn afàwọ̀rajà tí wọ́n sọ ara wọn di Kristi tàbí tí wọ́n sọ pé òun ló rán wọn. Bíbélì fún wa láwọn ìsọfúnni tó ṣe é gbára lé nípa aṣòdì sí Kristi. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àwọn ọ̀daràn ṣe máa ń rí nígbà mìíràn ni, dípò táwọn èèyàn ò bá fi wádìí òótọ́ nípa ẹni àràmàǹdà yìí àhesọ lásán ni wọ́n ń sọ.
Wọ́n Ń Fi Àtamọ́ Mọ́ Àtamọ̀
Látìgbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù làwọn èèyàn ti ń sọ pé ẹnì kan pàtó làwọn ọ̀rọ̀ Jòhánù nípa aṣòdì sí Kristi ń tọ́ka sí. Oríṣiríṣi èèyàn ni wọ́n ti pè bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ lérò pé Nero Olú Ọba Róòmù ni aṣòdì sí Kristi. Nígbà tó yá, ìkórìíra tó légbá kan tòun ti ìpayà tí Adolf Hitler kó bá àwọn èèyàn mú kí ọ̀pọ̀ sọ pé òun ni aṣòdì sí Kristi náà. Àní wọ́n tiẹ̀ lo ọ̀rọ̀ ọ̀hún fún ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Jámánì náà Friedrich Nietzsche. Àwọn mìíràn sì gbà gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi kò tíì dé, pé olóṣèlú tí kò lójú àánú kankan ló máa jẹ́, pé ńṣe ló máa dé wẹ́rẹ́ láti ṣàkóso gbogbo ayé. Wọ́n rò pé ẹranko ẹhànnà tí Ìṣípayá orí kẹtàlá mẹ́nu kàn ń tọ́ka sí aṣòdì sí Kristi tí Jòhánù sọ. Wọ́n sọ pé àmì ẹ́ẹ́fà, ẹ́ẹ́fà àti ẹ́ẹ́fà ló máa fi aṣáájú ìwà ibi yìí hàn.
Ohun tí gbogbo àwọn tó ní èrò yìí ń sọ ni pé aṣòdì sí Kristi kan péré ni Jòhánù sọ pé yóò wà. Àmọ́ kí làwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn? Ronú lórí 1 Jòhánù 2:18, tó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀, nísinsìnyí pàápàá ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ni ó ti wà.” Òdodo ọ̀rọ̀, “ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi,” ló fa wàhálà tẹ̀mí tó wáyé ní ọ̀rúndún kìíní, kì í ṣe ẹyọ kan. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn aṣòdì sí Kristi ni wọ́n para pọ̀ di ẹgbẹ́ aṣòdì sí Kristi, kì í ṣe ẹyọ kan ṣoṣo. Lápapọ̀, wọ́n ti pa àwọn èèyàn lára nípa tẹ̀mí lọ́nà tó bùáyà. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Àwọn wo ló tún para pọ̀ jẹ́ aṣòdì sí Kristi?
Ẹ jẹ́ ká wò ó bóyá ẹranko ẹhànnà inú ìwé Ìṣípayá orí kẹtàlá ni. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ́ ọ pé: “Ẹranko ẹhànnà tí mo rí dà bí àmọ̀tẹ́kùn, ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ti béárì, ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu kìnnìún.” (Ìṣípayá 13:2) Kí làwọn ẹranko wọ̀nyí dúró fún?
Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa Bíbélì ti rí bí Ìṣípayá orí kẹtàlá ṣe bára mu pẹ̀lú Dáníẹ́lì orí keje. Ọlọ́run fi ìran kan tó jẹ́ ti àwọn ẹranko ìṣàpẹẹrẹ han Dáníẹ́lì, tó ní nínú àwọn bí àmọ̀tẹ́kùn, béárì, àti kìnnìún. (Dáníẹ́lì 7:2-6) Báwo ni wòlíì Ọlọ́run ṣe túmọ̀ wọn? Ó kọ ọ́ pé àwọn ẹranko ẹhànnà wọ̀nyẹn dúró fún àwọn ọba ayé, tàbí ìjọba. (Dáníẹ́lì 7:17) A ò ṣì sọ nígbà náà táa bá sọ pé àwọn ìjọba ẹ̀dá ènìyàn ni ẹranko ẹhànnà inú ìwé Ìṣípayá dúró fún. Níwọ̀n bí àwọn ìjọba wọ̀nyí ti ń ṣòdì sí Ìjọba Ọlọ́run, apá kan aṣòdì sí Kristi ni wọ́n.
Ta Tún Ni Aṣòdì sí Kristi?
Nígbà tí Ọmọ Ọlọ́run wá sáyé, àìmọye ọ̀tá ló ní. Pẹ̀lú pé kò ṣeé fojú rí, ó ṣì láwọn ọ̀tá lónìí. Wo àwọn tó tún wà lára àwọn ọ̀tá wọ̀nyí.
Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ta ni òpùrọ́ bí kì í bá ṣe ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù ni Kristi? Èyí ni aṣòdì sí Kristi, ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.” (1 Jòhánù 2:22) Àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn aṣáájú ìsìn èké ti sọ àwọn ẹ̀kọ́ Jésù tó yéni kedere di ẹ̀tàn tí ìsìn gbé kalẹ̀. Àwọn wọ̀nyí kọ àwọn òtítọ́ Bíbélì sílẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí forúkọ Ọlọ́run àti Kristi tan irọ́ kálẹ̀. Wọ́n sẹ́ àjọṣe tó wà láàárín Bàbá àti Ọmọ nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn náà wà lára aṣòdì sí Kristi.
Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Lúùkù 21:12, pé: “Àwọn ènìyàn yóò gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí yín, ní fífà yín lé àwọn sínágọ́gù àti ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ . . . nítorí orúkọ mi.” Láti ọ̀rúndún kìíní làwọn Kristẹni ti ń fara da inúnibíni tó gbóná janjan. (2 Tímótì 3:12) Kristi làwọn tó ń dáná inúnibíni bẹ́ẹ̀ ń takò. Apá kan aṣòdì sí Kristi làwọn náà.
“Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì kó jọ pẹ̀lú mi ń tú ká.” (Lúùkù 11:23) Ohun tí Jésù ń sọ níbí ni pé gbogbo àwọn tó tako òun àtàwọn ète rẹ̀ àtọ̀runwá wà lára àwọn aṣòdì sí Kristi. Kí ló máa gbẹ̀yìn àwọn wọ̀nyí?
Kí Ló Máa Gbẹ̀yìn Àwọn Aṣòdì sí Kristi?
Sáàmù 5:6, sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò pa àwọn tí ń purọ́ run. Ẹni ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ẹni ẹ̀tàn ni Jèhófà ń ṣe họ́ọ̀ sí.” Ṣé èyí kan àwọn aṣòdì sí Kristi? Bẹ́ẹ̀ ni. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.” (2 Jòhánù 17) Nítorí irọ́ táwọn aṣòdì sí Kristi ń pa àti ìwà màkàrúrù wọn ni Ọlọ́run Olódùmarè ṣe máa pa wọ́n run.
Bí àkókò ìdájọ́ yẹn ti ń sún mọ́ tòsí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà ẹ̀tàn àti wàhálà látọ̀dọ̀ aṣòdì sí àwọn Kristẹni, pàápàá jù lọ látọ̀dọ̀ àwọn apẹ̀yìndà sọ ìgbàgbọ́ wọn dòbu. Ìkìlọ̀ Jòhánù gba àfiyèsí kánjúkánjú, torí ó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ ara yín, kí ẹ má bàa pàdánù àwọn ohun tí a ti ṣiṣẹ́ láti mú jáde, ṣùgbọ́n kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.”—2 Jòhánù 8.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Nero ní ojú ewé 2 àti 12: Lọ́lá àṣẹ Visitors of the Ashmolean Museum, Oxford