Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Àwọn Ọlọ́pàá?

Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Àwọn Ọlọ́pàá?

Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Àwọn Ọlọ́pàá?

BÁWO layé ì bá ṣe rí ná, ká ní kò sáwọn ọlọ́pàá? Ó dáa, kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1997 nígbà tí ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún ọlọ́pàá daṣẹ́ sílẹ̀ nílùú Recife, nílẹ̀ Brazil, tí kò sì sí ọlọ́pàá kankan tó ń ṣọ́ àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù kan níbẹ̀?

Ìwé ìròyìn The Washington Post sọ pé: “Iye ènìyàn tí wọ́n ń pa lójúmọ́ lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́ta láàárín ọjọ́ márùn-ún tí kò fi sí àwọn agbófinró ní ìlú ńlá tó wà létíkun yìí. Báńkì mẹ́jọ làwọn olè fọ́. Ńṣe làwọn àjọ ìpàǹpá ya lu àwọn ilé ìtajà, wọ́n ṣe àwọn èèyàn bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú, wọ́n sì tún lọ hùwà ìpáǹle láwọn àdúgbò táwọn olówó ń gbé, wọ́n kàn ń yìnbọn ṣáá ni. Kò sẹ́ni tó pa òfin ìrìnnà mọ́. . . . Ìwà ọ̀daràn ọ̀hún mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àyè mọ́ ní mọ́ṣúárì láti kó òkú sí. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn tí wọ́n ti yìnbọn fún àtàwọn tí wọ́n ti gún lọ́bẹ wà nílẹ̀ káàkiri ilé ìwòsàn ìjọba tó tóbi jù lọ ní ìlú náà.” Wọ́n ní adájọ́ àgbà ibẹ̀ sọ pé: “Irú ìwà kò-sẹ́ni-tó-máa-mú-mi bí irú èyí kò ṣẹlẹ̀ rí níbí.”

Ibi tó wù ká máa gbé, ọ̀pọ̀ èèyàn kàn máa ń fi ọ̀làjú bojú ni, ìwà ibi ló kún inú wọn. A nílò ààbò àwọn ọlọ́pàá. Òótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa la ti gbọ́ nípa ìwà ìkà, ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìdágunlá táwọn ọlọ́pàá kan máa ń hù, àti bí wọ́n ṣe máa ń ṣi agbára lò. Àwọn ìwà yìí pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè kan ju àwọn mìíràn lọ. Àmọ́ kí là bá ṣe ká ní kò sí àwọn ọlọ́pàá? Àbí kì í ṣòótọ́ ni pé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá máa ń ṣàǹfààní fún wa lọ́pọ̀ ìgbà? Jí! fọ̀rọ̀ wá àwọn ọlọ́pàá díẹ̀ lẹ́nu wò láwọn apá ibì kan láyé, nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ yìí.

Iṣẹ́ Tó Ń Ṣe Àwùjọ Láǹfààní

Ivan tó ń ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bí iṣẹ́ náà ṣe ní oríṣiríṣi ẹ̀ka ló jẹ́ kó fà mí mọ́ra. Àwọn èèyàn kì í mọ̀ pé kìkì ìdá ogún sí ìdá ọgbọ̀n péré nínú ọgọ́rùn-ún ni bíbójútó ìwà ọ̀daràn kó nínú iṣẹ́ ọlọ́pàá. Apá tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ló jẹ́ láti ṣe aráàlú àti àwùjọ láǹfààní. Lójoojúmọ́, tí mo bá ń wa mọ́tò yí àdúgbò ká, mo lè rí òkú tó kú lójijì, ìjàǹbá tó ṣẹlẹ̀ lójú pópó, àti ìwà ọ̀daràn, tí màá sì bójú tó wọn. Tàbí kẹ̀, mo lè rí àgbàlagbà kan tó nílò ìrànlọ́wọ́ kí n sì tọ́jú rẹ̀. Èyí tó máa ń dùn mọ́ mi nínú jù ni kí n rí ọmọ tó sọ nù kí n sì mú un padà sọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ tàbí kí n ran ẹnì kan tó kó sọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn lọ́wọ́ láti kojú ìdààmú ọkàn rẹ̀.”

Ọlọ́pàá ni Stephen tẹ́lẹ̀ rí nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó sọ pé: “Táwọn èèyàn bá wá bá ẹ pé kó o jọ̀ọ́ kó o ran àwọn lọ́wọ́, níwọ̀n bó o ti jẹ́ ọlọ́pàá, o ní ohun èlò àti àkókò láti ṣe gbogbo ìrànwọ́ tó o bá lè ṣe. Ìyẹn ló jẹ́ kí iṣẹ́ náà fà mí mọ́ra. Mo fẹ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro. Dé ìwọ̀n àyè kan, mo lérò pé mo ti dáàbò bo àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìwà ọ̀daràn. Àwọn èèyàn tí mo ti mú ti lé ní ẹgbẹ̀rún kan láàárín ọdún márùn-ún. Àmọ́ rírí àwọn ọmọ tó sọ nù he, ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tó ní àìsàn tí wọ́n ń pè ní Alzheimer, tí wọn ò mọ̀nà ilé mọ́, àti rírí àwọn ọkọ̀ tí wọ́n jí gbé gbà padà máa ń múnú mi dùn gan-an. Ohun mìíràn tó tún máa ń mú ara mi yá gágá ni kí n máa lépa àwọn ọ̀daràn tí wọ́n fura sí, kí ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n.”

Roberto tó ń ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá ní Bolivia sọ pé: “Mo fẹ́ láti ran àwọn èèyàn tó wà nípò pàjáwìrì lọ́wọ́. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ọlọ́pàá gan-an nítorí pé wọ́n máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn kúrò lọ́wọ́ ewu. Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí, ní àárín ìlú tí àwọn ọ́fíìsì ìjọba wà, èmi ni olórí àwọn ọlọ́pàá tó máa ń káàkiri ìgboro. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ la máa ń kojú wàhálà àwọn tó ń ṣe ìwọ́de lórí ọ̀ràn ìṣèlú. Iṣẹ́ mi ni pé kí n yára wá ojútùú sí i kí ọ̀rọ̀ tóó di bó-ò-lọ-o-yà-fún-mi. Mo rí i pé tí mo bá hùwà ọmọlúwàbí sáwọn tó jẹ́ aṣáájú nínú ìwọ́de ọ̀hún tí mo sì pẹ̀tù sí wọn nínú, ìjààgboro tí ì bá mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fara pa kì í ṣẹlẹ̀. Èyí máa ń múnú mi dùn gan-an.”

Iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá pọ̀, ó sì pín sí ẹ̀ka oríṣiríṣi. Bẹ̀rẹ̀ látorí títú ológbò tó há sórí igi sílẹ̀ títí lọ dórí yíyọ àwọn tí àwọn apániláyà jí gbé nínú ewu àti kíkojú àwọn adigunjalè tó ń fọ́ báńkì. Síbẹ̀, látìgbà tíṣẹ́ ọlọ́pàá tá a mọ̀ lóde òní ti bẹ̀rẹ̀, nǹkan méjì ló máa ń wà lọ́kàn àwọn èèyàn. Ìyẹn ni pé bí wọ́n ṣe ń retí pé káwọn ọlọ́pàá pèsè ààbò fún wọn ni ẹ̀rù tún ń bà wọ́n pé wọ́n lè ṣi agbára wọn lò. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e á sọ ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]

Ojú ìwé 2 àti 3: Dídarí ọkọ̀ lójú pópó ní Hong Kong; àwọn ọlọ́pàá tó ń pẹ̀tù sí ìjààgboro nílẹ̀ Gíríìsì; àwọn ọlọ́pàá ní Gúúsù Áfíríkà

[Credit Line]

Linda Enger/Index Stock Photography

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n kó lásìkò táwọn ọlọ́pàá daṣẹ́ sílẹ̀ nílùú Salvador, nílẹ̀ Brazil, ní July 2001

[Credit Line]

Manu Dias/Agência A Tarde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Stephen, Amẹ́ríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Roberto, Bolivia