Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lílo Jí! Lọ́nà Tó Dára

Lílo Jí! Lọ́nà Tó Dára

Lílo Jí! Lọ́nà Tó Dára

ỌMỌ ọdún mẹ́rìndínlógún ni Vanessa tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ń gbé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ní kó kọ ìròyìn kan wá níléèwé lórí ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra. Ó sọ pé: “Mo ṣe àwọn ìwádìí díẹ̀, àmọ́ ẹ̀tahóró làwọn ìsọfúnni tí mo rí kó jọ. Mo fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn òbí mi létí, wọ́n sì sọ pé kí n lọ wá kókó ọ̀rọ̀ náà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa.”

Nípa wíwá inú àwọn ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún Vanessa láti rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìsọfúnni tó máa lò fún ìròyìn rẹ̀. Ó wá sọ pé: “Àmọ́ apá kan lásán lèyí jẹ́ lára iṣẹ́ àṣetiléwá náà o, torí pé mo tún ní láti sọ̀rọ̀ níwájú olùkọ́ mi àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mí tí wọ́n jẹ́ ogún!” Ọgbọ́n wo ni Vanessa máa ta sí èyí?

Bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo lágbàáyé, Vanessa máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí sísọ̀rọ̀ ní gbangba ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí wọ́n máa ń ṣe láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Vanessa sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa ń múra wa sílẹ̀ dáadáa láti jáde lọ wàásù ká sì bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. A tún máa ń gba ìmọ̀ràn lórí apá ibi tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé lórí káwọn èèyàn bàa lè lóye wa dáadáa.” Kí ni àbájáde iṣẹ́ àṣekára tí Vanessa ṣe lórí ìròyìn tí wọ́n ní kó kọ wá láti iléèwé rẹ̀? Ó sọ pé: “Èmi ni mo gba máàkì tó pọ̀ jù lọ.”

Vanessa jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n ń lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì àtàwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí mìíràn tí wọ́n ń gbà lọ́nà tó dára. Ó yẹ ká gbóríyìn fún irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọ́n ń fi ìṣílétí tó wà nínú Oníwàásù 12:1 sílò, èyí tó sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”