Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Wíwo Ayé

Ìsọkúsọ Túbọ̀ Ń Gbilẹ̀ Sí I

Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Toronto Star ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn ará Àríwá Amẹ́ríkà ló ń bà lọ́kàn jẹ́ pé, “gbogbo akitiyan tí àwọn ń ṣe láti mú kí ìwà ọmọlúwàbí wà láwùjọ ò kẹ́sẹ járí.” Èyí hàn gbangba nínú bí “ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe túbọ̀ ń sọ ìsọkúsọ.” Ọ̀gbẹ́ni P. M. Forni tó jẹ́ olùdarí Ètò Ìwà Ọmọlúwàbí Láwùjọ ní Yunifásítì John Hopkins sọ pé, ìsọkúsọ ti wá wọ́pọ̀ gan-an débi pé, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò rí ohun tó burú nínú rẹ̀, bákan náà ló dà bíi pé ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ni kò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí i tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ mọ̀ ọ́n láìdáa pàápàá. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Timothy Jay ṣe, “láti bí ọmọ ọdún kan, ìyẹn ìgbà táwọn ọmọdé máa ń kọ́ ọ̀rọ̀ sọ, ni wọ́n ti máa ń sọ ìsọkúsọ. Ìgbà yìí ni wọ́n máa ń kó àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn òbí wọn àti lórí tẹlifíṣọ̀n ságbárí.” Ìwádìí kan fi hàn pé “nǹkan bí ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀rọ̀ tí àwọn àgbàlagbà ń sọ níbi iṣẹ́ ló máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, tí èyí tí wọ́n sì máa ń sọ nígbà fàájì máa ń jẹ́ ìdá mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún.” Ìwádìí mìíràn tí ìwé ìròyìn Star mẹ́nu kàn fi hàn pé, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, “ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tó ń wáyé lórí tẹlifíṣọ̀n ti ròkè sí ohun tó ju ìlọ́po márùn-ún lọ láti ọdún 1989 sí 1999.”

“Àrùn Tá A Lè Yẹra Fún”

Ìwé ìròyìn The Sun-Herald ti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Àrùn osteoporosis (àrùn tó ń sọ egungun di aláìlágbára) jẹ́ àrùn tá a lè yẹra fún. A lè dènà rẹ̀ dáadáa. Síbẹ̀, àwọn ògbógi sọ pé, tó bá fi máa di ọdún 2020, ìdá mẹ́ta àwọn tí wọ́n máa dá dúró sí ọsibítù á jẹ́ àwọn obìnrin tí egungun wọ́n ti dá.” Ìròyìn kan tí Àjọ Tó Ń Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ̀ Nípa Àrùn Osteoporosis Nílẹ̀ Ọsirélíà gbé jáde fi hàn pé, àrùn tó máa ń fa ọyún sínú egungun tó sì máa ń jẹ́ kó tètè dá yìí, “gbilẹ̀ gan-an ju ìṣòro àpọ̀jù ọ̀rá inú ara, ìṣòro níní èèwọ̀ ara tàbí ọ̀fìnkìn lọ. Títọ́jú àrùn yìí ń náni lówó ju títọ́jú àrùn àtọ̀gbẹ tàbí ikọ́ ẹ̀gbẹ lọ. Iye àwọn obìnrin tó sì ń kú nítorí pé egungun ìgbáròkó wọ́n dá pọ̀ ju iye àwọn tó ń kú látinú gbogbo àrùn jẹjẹrẹ tó ń ṣe àwọn obìnrin lọ.” Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Philip Sambrook ṣe sọ, àwọn ìwádìí lóríṣiríṣi fi hàn pé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ìdajì àwọn obìnrin àti ìdá mẹ́ta àwọn ọkùnrin ni egungun wọ́n máa dá látàrí àrùn osteoporosis nígbà ayé wọn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà dènà àrùn osteoporosis jẹ́ nípa mímú kí egungun ara lágbára bó bá ti lè ṣeé ṣe tó ní ọgbọ̀n ọdún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé nípa ṣíṣe eré ìmárale àti jíjẹ àwọn oúnjẹ àti mímu àwọn ohun mímu tó ní èròjà calcium tí ó pọ̀ tó nínú.” Ó ṣeé ṣe gan-an láti dín ewu níní àrùn osteoporosis kù nípa yíyẹra fún sìgá mímu àti mímu ọtí líle tàbí àwọn ohun tó ní èròjà kaféènì nínú lámujù. Lára àwọn ohun tó lè ṣèrànwọ́ ni ṣíṣe eré ìmárale déédéé àti jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní ọ̀pọ̀ èròjà calcium àti vitamin D nínú.

Pípolongo Ìhìn Rere ní Ojúde Òfuurufú

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń bára wọn jiyàn lórí bóyá àwọn ẹ̀dá mìíràn ń gbé ní ojúde òfuurufú, ìwé ìròyìn Berliner Morgenpost ròyìn pé, àwọn àlùfáà tó wà ní Ibi Ìdúrósí-wo-sánmà Tó Wà ní Ibùjókòó Ìjọba Póòpù ti dórí èrò náà pé, “kì í ṣe àwọn tó ń gbé ayé nìkan ni ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá sínú àgbáyé. Ọlọ́run tún dá àwọn ẹ̀dá mìíràn tí ń gbé lẹ́yìn òde ilẹ̀ ayé.” George Coyne, olùdarí ibi ìdúrósí-wo-sánmà náà sọ nínú àlàyé rẹ̀ pé, “àgbáyé tóbi gan-an ju ohun tí àwa nìkan lè máa dá gbé inú rẹ̀ lọ.” Kí wọ́n lè polongo Ìhìn Rere fún àwọn ẹ̀dá mìíràn tó wà lẹ́yìn òde ilẹ̀ ayé, àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé bíi mélòó kan ti ń fi Májẹ̀mú Tuntun ránṣẹ́ sí ojúde òfuurufú, nípa lílo àwọn àmì ìkọ̀wé pàtó kan tí wọ́n fi ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́. Ìwé ìròyìn náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, ohun tí Ibùjókòó Ìjọba Póòpù fẹ́ láti mọ̀ báyìí, “ni bóyá Jésù Kristi ti fara rẹ̀ hàn nínú àwọn pílánẹ́ẹ̀tì mìíràn pẹ̀lú.” Àti pé, níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Coyne, “bóyá Jésù Kristi ti gba àwọn tó ń gbé nínú” àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wọ̀nyẹn “náà là tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”

Yíyí Ọwọ́ Aago “Ọjọ́ Ìparun” Síwájú

Ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ ti ìlú Paris tó ń jẹ́ International Herald Tribune sọ pé, àwọn aláṣẹ ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists ti yí ọwọ́ Aago Ọjọ́ Ìparun tó lókìkí náà “síwájú sí aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú méje láti aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Àníyàn nípa bí gbogbo akitiyan láti dín ohun ìjà ogun kù ṣe ń falẹ̀ àti bí ìtòjọpelemọ àwọn ohun ìjà runlérùnnà àti ìwà ìpániláyà ṣe ń pọ̀ sí i” ló mú kí wọ́n yí ọwọ́ aago náà síwájú. Aago náà—tó ń ṣàpẹẹrẹ bí ayé ṣe sún mọ́ ìparun yán-ányán-án tó nípa ohun ìjà runlérùnnà—ni wọ́n ti sún síwá-sẹ́yìn ní ìgbà mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti fi lọ́lẹ̀ lọ́dún 1947. Lẹ́yìn tí ilẹ̀ Soviet Union pín sí orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́dún 1991, wọ́n yí ọwọ́ aago náà padà sí aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún, àmọ́ láti ọdún yẹn wá ni wọ́n ti ń yí ọwọ́ aago náà síwájú ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ tó sì ń sún mọ́ aago méjìlá òru. Ọdún 1998 ni wọ́n yí ọwọ́ aago náà kẹ́yìn, láti aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá sí aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án. Látìgbà náà wá, kìkì ohun ìjà runlérùnnà tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] péré ni wọ́n tíì pa run, nígbà tí iye tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] ṣì wà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó ní wọn níkàáwọ́.