Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
Ohun ìyanu gbáà ló jẹ́ pé Bíbélì ṣì wà títí dòní, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò sì yí pa dà. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá (1,900) ọdún tí wọ́n ti kọ ọ́. Orí àwọn nǹkan tó lè tètè bà jẹ́ bí awọ àti ohun kan tí wọ́n ń pè ní òrépèté ni wọ́n kọ Bíbélì sí láyé àtijọ́. Lóde òní, ìwọ̀nba èèyàn ló ń sọ àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì níbẹ̀rẹ̀. Bákan náà, àwọn alágbára kan bí àwọn olú ọba, títí kan àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti gbìyànjú gan-an láti pa Bíbélì run.
ÁWO ni ìwé tó ju gbogbo ìwé lọ yìí ṣe la gbogbo ìṣòro yẹn kọjá, tó sì wá di ìwé tó gbajúmọ̀ jù lọ láyé? Jẹ́ ká wo ohun méjì tó mú kó rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn Adàwékọ Kò Jẹ́ Kí Bíbélì Pa Run
Àwọn tó ní Bíbélì àfọwọ́kọ àtijọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tọ́jú àwọn àkájọ ìwé náà, wọ́n sì dà á kọ sínú ọ̀pọ̀ àkájọ ìwé míì. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọba tó ń jẹ ní Ísírẹ́lì àtijọ́ máa “kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan, látinú èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà tọ́jú.”—Diutarónómì 17:18.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló fẹ́ràn kí wọ́n máa ka Ìwé Mímọ́, torí wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn akọ̀wé tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló fara balẹ̀ ṣe àdàkọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa akọ̀wé kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ́sírà, ó sọ pé ó jẹ́ “adàwékọ tó mọ Òfin Mósè dunjú, èyí tó wá látọ̀dọ̀Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:6) Àwọn kan tún wà tí wọ́n ń pè ní Másórétì. Àwọn ló ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tàbí “Májẹ̀mú Láéláé” láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà àti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá Sànmánì Kristẹni. Ohun táwọn máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń ka lẹ́tà ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan kí àṣìṣe má bàa wà nínú ohun tí wọ́n kọ. Bí wọ́n ṣe fara balẹ̀ ṣe àdàkọ yìí jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ péye, ìyẹn sì wà lára ohun tó jẹ́ kí Bíbélì wà títí dòní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá gbìyànjú gan-an láti pa á run.
Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 168 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Antiochus Kẹrin tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Síríà gbìyànjú láti dáná sun gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó bá rí ní gbogbo ilẹ̀ Palẹ́sìnì. Ìtàn àwọn Júù kan sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n máa ń fa àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá ti rí ya tí wọ́n á sì dáná sun ún.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n gbéṣẹ́ yìí fún ò láàánú rárá . . . Tí wọ́n bá rí Ìwé Mímọ́ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni . . . ńṣe ni wọ́n máa pa á.” Àmọ́ ṣá o, àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ kan kò pa run, wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn Júù tó ń gbé Palẹ́sìnì àtàwọn tó ń gbé láwọn ilẹ̀ míì.
Kò pẹ́ lẹ́yìn táwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí “Májẹ̀mú Tuntun” parí iṣẹ́ wọn la wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀dà àwọn lẹ́tà tí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn láti kọ ti wà káàkiri, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtàwọn ìwé ìtàn. Bí àpẹẹrẹ, ìlú Éfésù tàbí tòsí rẹ̀ ni Jòhánù ti kọ Ìwé Ìhìn Rere tó kọ. Àmọ́, wọ́n rí àjákù ìwé Ìhìn Rere yẹn ní ilẹ̀ Íjíbítì tó fi nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) máìlì jìnnà sí ìlú Éfésù. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé àjákù yìí jẹ́ ara ẹ̀dà tí wọ́n kọ ní nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún lẹ́yìn tí Jòhánù kọ ìwé rẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé àwọn Kristẹni tó wà láwọn ilẹ̀ tó jìnnà gan-an ní àwọn ẹ̀dà ìwé tí ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn èèyàn láti kọ nígbà yẹn.
Nítorí pé wọ́n ti pín Bíbélì káàkiri ni kò jẹ́ kó pa run lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún tí Jésù ti kúrò láyé. Bí àpẹẹrẹ, láàárọ̀ February 23 ọdún 303 S.K. wọ́n sọ pé Olú Ọba Róòmù Diocletian ní kí àwọn ọmọ ogun ẹ̀ lọ fọ́ ilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì kan kí wọ́n sì sun àwọn ẹ̀dà Bíbélì tó wà níbẹ̀. Diocletian rò pé òun lè pa ẹ̀sìn Kristẹni run tóun bá ti pa Ìwé Mímọ́ run. Lọ́jọ́ kejì, ó pàṣẹ pé kí wọ́n gba gbogbo Bíbélì tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù, kí wọ́n sì sun ún ní gbangba. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ẹ̀ ni wọ́n rí sun, torí náà wọ́n ṣe àwọn ẹ̀dà míì. Kódà, apá tó pọ̀ nínú méjì lára ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n dà kọ láìpẹ́ sígbà yẹn ṣì wà títí dòní. Ọ̀kan wà ní Róòmù, èkejì sì wà níbi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní British Library tó wà ní London, nílẹ̀ England.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tíì rí Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, ọ̀pọ̀ odindin Bíbélì tí wọ́n dà kọ tàbí apá kan ẹ̀ ló ṣì wà títí dòní. Àwọn kan lára wọn ti gbó. Àmọ́, ṣé ohun tó wà nínú Bíbélì ti yí pa dà torí pé àwọn èèyàn ti dà á kọ léraléra? Ọ̀mọ̀wé William Henry Green sọ nípa Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pé: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ pé nínú gbogbo àwọn ìwé àtijọ́ tí wọ́n ṣe àdàkọ rẹ̀, kò sí èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà tó péye bíi Bíbélì. Sir Frederic Kenyon, tó jẹ́ aṣáájú lára àwọn tó mọ̀ nípa Bíbélì àfọwọ́kọ sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó ní: “Kò pẹ́ tí wọ́n kọ àwọn ìwé yẹn tán táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn kan lára àdàkọ tó ṣì wà títí dòní. Torí náà, kò sí iyèméjì kankan pé Ìwé Mímọ́ tá a ní lónìí péye bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀. A lè sọ pé a ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pátápátá pé ojúlówó ni Májẹ̀mú Tuntun, òótọ́ pọ́ńbélé sì ni gbogbo ohun tó wà nínú ẹ̀.” Ó tún sọ pé: “A lè fi ìdánilójú sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì jóòótọ́ . . . Kò sí ìwé tó ti pẹ́ kankan tá a lè fi wé e.”
Ìtúmọ̀ Bíbélì
Ohun pàtàkì kejì tó jẹ́ kí Bíbélì di ìwé tí aráyé mọ̀ jù lọ ni pé ó wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Èyí sì bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, torí pé gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run fẹ́ kó mọ òun, kí wọ́n sì máa jọ́sìn òun ní “ẹ̀mí àti òtítọ́,” láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí tàbí èdè tí wọ́n ń sọ.—Jòhánù 4:23, 24; Míkà 4:2.
Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n túmọ̀ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì ni wọ́n pè ní Bíbélì Septuagint. Wọ́n ṣe é nítorí àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì tí wọ́n ń gbé lẹ́yìn odi Palẹ́sìnì, wọ́n sì parí rẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Nígbà tó yá, wọ́n parí kíkọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì lódindi sí ọ̀pọ̀ èdè. Àmọ́ nígbà tó yá, dípò kí àwọn ọba àtàwọn àlùfáà sa gbogbo ipá wọn káwọn èèyàn lè ní Bíbélì lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa mọ́. Àwọn àlùfáà fi àwọn ọmọ ìjọ wọn sínú òkùnkùn, wọn ò jẹ́ kí wọ́n mọ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn ò sì jẹ́ káwọn èèyàn túmọ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn èdè tó yé àwọn èèyàn dáadáa.
Àwọn ọkùnrin onígboyà kan fi ẹ̀mí ara wọn wéwu kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sí èdè tó yé àwọn èèyàn dáadáa láì bẹ̀rù ohun tí àwọn aṣáájú Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba lè fi wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1530, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ William Tyndale, tó kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì Oxford, túmọ̀ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Láìka ọ̀pọ̀ àtakò sí, òun ló kọ́kọ́ túmọ̀ Bíbélì láti èdè Hébérù sí èdè Gẹ̀ẹ́sì ní tààràtà. Tyndale tún ni atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tó kọ́kọ́ lo orúkọ náà, Jèhófà. Ẹlòmíì tún ni ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó ń jẹ́ Casiodoro de Reina tó jẹ́ onímọ̀ nípa Bíbélì. Àwọn Kátólíìkì ń ta kò ó, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á torí pé òun lẹni àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ Bíbélì sí èdè Sípáníìṣì. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn àjò káàkiri, ó lọ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì, Farańsé, Holland àti Switzerland kó lè parí iṣẹ́ ìtúmọ̀ * náà.
Lóde òní, wọ́n túbọ̀ ń túmọ̀ Bíbélì sí èdè tó pọ̀ sí i, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ẹ̀dà ni wọ́n sì ń tẹ̀ jáde. Bíbélì ṣì wà títí dòní, òun sì ni ìwé táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ kárí ayé, ìyẹn jẹ́rìí sí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ dári àpọ́sítélì Pétérù láti sọ pé: “Koríko máa ń gbẹ, òdòdó sì máa ń rẹ̀ dà nù, àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà wà títí láé.”—1 Pétérù 1:24, 25.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 14 Wọ́n gbé ìtúmọ̀ tí Reina ṣe jáde lọ́dún 1569, Cipriano de Valera sì ṣàtúnṣe ìtúmọ̀ náà lọ́dún 1602.
[Àpótí/Àwòrán]
BÍBÉLÌ WO NI KÍ N KÀ?
Ọ̀pọ̀ èdè ló ní oríṣiríṣi Bíbélì. Àwọn Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ tó ṣòro láti lóye tàbí àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ò lò mọ́. Àwọn Bíbélì míì lo ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti kà, àmọ́ ìtumọ̀ wọn ò péye. Àwọn Bíbélì mìí sì wà tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, bí ìgbà téèyàn kàn ń fi ọ̀rọ̀ rọ́pò ọ̀rọ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kí ìtumọ̀ náà péye.
Àmọ́, ní ti Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures (Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun) táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, inú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní tààràtà ni àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè kan tá ò mọ orúkọ wọn ti túmọ̀ rẹ̀. Ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì yẹn ni wọ́n wá lò láti túmọ̀ Bíbélì náà sí nǹkan bí ọgọ́ta (60) èdè. Ṣùgbọ́n, àwọn tó túmọ̀ Bíbélì náà sí àwọn èdè míì fi èyí tí wọ́n tú wéra pẹ̀lú àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn tó ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ ọ̀rọ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan látinú àwọn Bíbélì àfọ́wọ́kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ nígbà tó bá yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kí ìtumọ̀ náà lè yéni. Wọ́n túmọ̀ Bíbélì náà lọ́nà táá fi yé àwọn tó ń kà á bíi pé Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ gan-an ni wọ́n ń kà.
Àwọn onímọ̀ nípa èdè ṣàyẹ̀wò àwọn ìtumọ́ Bíbélì lóríṣiríṣi, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ìtumọ́ náà péye, wọ́n sì yẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wò fínnífínní. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ yẹn ni Jason David BeDuhn, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ẹ̀kọ́ ìsìn ní yunifásítì Northern Arizona nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Lọ́dún 2003, ó mú ìwé kan tó ní ojú ìwé igba (200) jáde, ó sì tẹ àwọn nǹkan tó rí nínú ìwádìí tó ṣe sínú ẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn Bíbélì mẹ́sàn-án tí wọ́n ń lò jù lọ láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.” * Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa ń fa àríyànjiyàn láàárín àwọn èèyàn ni ìwádìí rẹ̀ dá lé lórí, torí pé “ibẹ̀ ló ti ṣeé ṣe káwọn atúmọ̀ èdè ti yí ọ̀rọ̀ pa dà.” Ó ń ka àwọn àwọn ẹsẹ náà níkọ̀ọ̀kan, ó ń fi ohun tí wọ́n tú u sí lédè Gẹ̀ẹ́sì wé ohun tó wà níbẹ̀ lédè Gíríìkì, ó sì ṣàyèwò wọn bóyá àwọn atúmọ̀ èdè ti yí ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ náà pa dà. Kí ló rí?
Ọ̀jọ̀gbọ́n BeDuhn sọ pé èrò ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan tàwọn onímọ̀ nípa Bíbélì ni pé ìgbàgbọ́ tàbí ẹ̀sìn àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ló mú kó yàtọ̀ sáwọn Bíbélì yòókù. Ó wá sọ pé: “Ohun tó mú kó yàtọ̀ ni pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun péye gan-an, ó sì gbé èrò inú Bíbélì àfọwọ́kọ ti ìpilẹ̀sẹ̀ yọ.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀jọ̀gbọ́n BeDuhn kò fara mọ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn ẹsẹ kan nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ó sọ pé Bíbélì yìí “ló péye jù lọ nínú gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó fi wéra.” Torí náà, ó pè é ní “ìtumọ̀ Bíbélì tó dára jù lọ.”
Ọ̀mọ̀wé Benjamin Kedar, ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èdè Hébérù, sọ ohun kan náà nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ní ọdún 1989, ó ní: “Ìtumọ̀ yìí kò ní àbùlà, ó yéni gan-an, ó sì péye. . . . Mo wo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun látòkèdélẹ̀, mi ò rí ibì kankan tọ́ka sí tí wọ́n ti fi kún un tàbí yí ohun tó yẹ kó wà níbẹ̀ pa dà.”
Bi ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi ń ka Bíbélì? Ṣé ohun tó ṣe pàtàkì sí mi ni pé kí Bíbélì ṣáà ti rọrùn kà, láìmọ̀ bóyá ó péye àbí kò péye? Àbí mo fẹ́ ka Bíbélì tó gbé ohun tó wà nínú ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ́nà tó péye?’ (2 Pétérù 1:20, 21) Ohun tó o bá fẹ́ ló máa jẹ́ kó o mọ ìtumọ̀ Bíbélì tó yẹ kó o kà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 22 Ó ṣàyẹ̀wò Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ míì, àwọn sì ni Bíbélì The Amplified New Testament, The Living Bible, The New American Bible With Revised New Testament, New American Standard Bible, The Holy Bible—New International Version, The New Revised Standard Version, The Bible in Today’s English Version, àti Bíbélì King James.
[Àwòrán]
“Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” ti wà ní èdè tó pọ̀
[Àwòrán]
Ìwé àfọwọ́kọ ti àwọn Másórétì
[Àwòrán]
Àjákù ìwé tó ní Lúùkù 12:7 nínú, “. . . ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”
[Àwòrán]
Àwòrán ọwọ́ iwájú: National Library of Russia, St. Petersburg; méjì tó tẹ̀ lé e: Bibelmuseum, Münster; èyí tó wà lẹ́yìn pátápátá: © The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin