Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Borí Ẹ̀tanú

Ìfẹ́ Borí Ẹ̀tanú

Ìfẹ́ Borí Ẹ̀tanú

“Ẹ̀sìn tuntun kan fara hàn fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn: kì í ṣe ti orílẹ̀-èdè tó ń gbé ìfọkànsìn fún ìlú là ń sọ, bí kò ṣe àwùjọ àwọn èèyàn kan tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn, tí wọn ò fi ti àwùjọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà ìran téèyàn ti wá ṣe: tọkùnrin tobìnrin tí wọ́n ń pé jọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá kan ṣoṣo, láti jọ́sìn ọlọ́run wọn.” —Ìwé A History of Christianity, látọwọ́ Paul Johnson.

NÍGBÀ tí ojúlówó ẹ̀sìn Kristẹni ń gbilẹ̀ káàkiri Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ohun àgbàyanu ló jẹ́ lójú àwọn èèyàn láti rí àwùjọ àwọn èèyàn alálàáfíà tí wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run níṣọ̀kan jákèjádò ayé. Ohun tó mú kí àwùjọ àwọn olùjọsìn yìí wà ní àlàáfíà ni pé wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́, tó kọjá èrò ara ẹni lásán, àmọ́ tó dá lórí àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi kọ́ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kórìíra Jésù Kristi tí wọ́n sì ṣẹ̀tanú sí i lọ́nà rírorò, ìwà tó hù àtàwọn ohun tó fi kọ́ni bá àwọn ìlànà yẹn mu. (1 Pétérù 2:21-23) Ohun kan ni pé, Gálílì ló ti wá, àwọn ọ̀tọ̀kùlú ẹlẹ́sìn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù sì máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ará Gálílì tí ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ àgbẹ̀ àti apẹja. (Jòhánù 7:45-52) Àmọ́, Jésù jẹ́ olùkọ́ títayọ táwọn gbáàtúù èèyàn mọyì rẹ̀. Nítorí èyí, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn jowú Jésù débi pé wọ́n tan irọ́ kálẹ̀ nípa rẹ̀ wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á!—Máàkù 15:9, 10; Jòhánù 9:16, 22; 11:45-53.

Síbẹ̀, Jésù kò “fi ibi san ibi.” (Róòmù 12:17) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn Farisí kan lára àwọn ẹ̀ya Júù tó ṣàtakò sí Jésù tọ̀ ọ́ lọ láti fi àìṣẹ̀tàn bi í ní ìbéèrè, ó dá wọn lóhùn ní pẹ̀lẹ́tù. (Jòhánù 3:1-21) Kódà, Jésù bá àwọn Farisí jẹun, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó ti ṣe ẹ̀tanú sí i rí wà lára wọn. Lọ́nà wo? Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àṣà àwọn Júù ni pé kí wọ́n wẹ ẹsẹ̀ àlejò; síbẹ̀, Farisí yìí kọ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ Jésù. Ṣe Jésù torí ẹ̀ bínú? Rárá o. Kódà, ó lo àǹfààní tó ní nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn láti kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè jẹ́ aláàánú, kí wọ́n sì máa dárí jini.—Lúùkù 7:36-50; 11:37.

Jésù Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Wọ́n Tẹ́ńbẹ́lú

Ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jésù táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ni ìtàn aláàánú ará Samáríà, nínú èyí tí ará Samáríà kan ti fowó ara ẹ̀ tọ́jú Júù kan táwọn ọlọ́ṣà lù tí wọ́n sì jà lólè. (Lúùkù 10:30-37) Kí ló mú kí ohun tí ará Samáríà yẹn ṣe jẹ́ ìwà ọmọlúwàbí? Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé, nígbà yẹn, ńṣe làwọn Júù àtàwọn ará Samáríà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ara wọn. Kódà, báwọn Júù bá fẹ́ pẹ̀gàn ẹnì kan, wọ́n máa ń pè é ní “Ará Samáríà.” Wọ́n pe Jésù pàápàá bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 8:48) Pẹ̀lú gbogbo èyí tó wà nílẹ̀ yìí, ó dájú pé àkàwé Jésù nípa aládùúgbò tí kò ṣe ojúsàájú yìí ló ṣe wẹ́kú jù lọ.

Jésù fi ohun tó ń kọ́ni ṣèwà hù torí pé ó wo adẹ́tẹ̀ kan tó jẹ́ ará Samáríà sàn. (Lúùkù 17:11-19) Láfikún sí ìyẹn, ó kọ́ àwọn ará Samáríà míì tí wọ́n mọrírì ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èyí tó tiẹ̀ wá jọjú jù lọ ni pé ó bá obìnrin ará Samáríà kan jíròrò fún àkókò gígùn. (Jòhánù 4:7-30, 39-42) Kí ló mú kó jọjú? Àwọn rábì tàbí olùkọ́ àwọn Júù ò jẹ́ bá obìnrin èyíkéyìí sọ̀rọ̀ ní gbangba, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìbátan wọn tímọ́tímọ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé obìnrin tó jẹ́ ará Samáríà!

Ojú wo tiẹ̀ ni Ọlọ́run fi ń wo ẹni tó bá ń ṣe ẹ̀tanú àmọ́ tó ń tiraka láti mú ẹ̀tanú náà kúrò lọ́kàn? Lẹ́ẹ̀kan sí i, Bíbélì là wá lọ́yẹ̀ lórí kókó yìí, ohun tó sọ sì tuni nínú.

Ọlọ́run Ń Ṣe Sùúrù fún Wa

Ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tí kì í ṣe Júù bẹ̀rẹ̀ sí í di onígbàgbọ́, ìwà ẹ̀tanú táwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ti ní sí wọn tipẹ́tipẹ́ kọ́kọ́ mú kí wọ́n kórìíra wọn. Báwo ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe yanjú ìṣòro tó lè fa ìpínyà yìí? Ó fi sùúrù kọ́ ìjọ Kristẹni lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 15:1-5) Sùúrù yìí sèso rere, torí gẹ́gẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn án níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, “wọn ò fi ti àwùjọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà ìran téèyàn ti wá ṣe.” Nítorí náà, “àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Ìṣe 16:5.

Kí la rí kọ́ nínú èyí? Pé ká má ṣe juwọ́ sílẹ̀, àmọ́ ká máa bá a nìṣó láti gbọ́kàn lé Ọlọ́run, tó ń fìwà ọ̀làwọ́ fún gbogbo àwọn tó ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́” ní ọgbọ́n àti agbára láti hùwà títọ́. (Jákọ́bù 1:5, 6) Ǹjẹ́ o rántí Jennifer, Timothy, John àti Olga tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú èyí àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí? Nígbà tí Jennifer fi máa tó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, ó ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kéèyàn máa ka àwọn ọ̀rọ̀ èébú nípa ẹ̀yà téèyàn ti wá àti béèyàn ṣe rí sí bàbàrà. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, nígbà táwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi ọmọbìnrin míì ṣe yẹ̀yẹ́, Jennifer gbèjà ẹ̀, ó sì pẹ̀tù sí i nínú.

Kí ló ran Timothy lọ́wọ́ tí kò fi dá sí àwọn tó ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́? Ó sọ pé: “Bí mo bá dá wọn lóhùn, màá kẹ́gàn bá orúkọ Jèhófà Ọlọ́run, ohun tí mi ò sì fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Bákan náà, gbogbo ìgbà ni mo máa ń rántí pé a gbọ́dọ̀ ‘máa fi ire ṣẹ́gun ibi,’ ká má sì jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun wa.”—Róòmù 12:21.

John pẹ̀lú borí ẹ̀tanú tó ní sí ọmọ Haúsá tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì. Ó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún ọdún, mo bá àwọn Haúsá kan pàdé, a sì dọ̀rẹ́ ara wa. Èmi àti ọ̀kan lára wọn jọ ṣiṣẹ́ kan tí wọ́n gbé fún wa níléèwé, kò sì sí wàhálà kankan. Ní báyìí, ẹni téèyàn jẹ́ ni mo máa ń wò, mi kì í wo ìlú tó ti wá.”

Olga àti ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ò ṣojo nígbà táwọn alátakò tó kórìíra wọn ṣenúnibíni sí wọn, àmọ́ wọ́n dúró ṣinṣin, ó dá wọn lójú pé àwọn èèyàn kan máa mọrírì ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn ń kọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì mọrírì rẹ̀ lóòótọ́. Olga sọ pé: “Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan tọ̀ mí wá ó sì gbé àpò kékeré kan tó rẹwà lé mi lọ́wọ́. Wọ́n gbẹ́ àwọn ànímọ́ Kristẹni bí ìwà rere, inú rere, ìfẹ́ àti àlàáfíà sára àwọn òkúta náà. Lẹ́yìn náà ló wá sọ fún mi pé òun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọdékùnrin tó sọ mi lókùúta àti pé òun ti di Kristẹni arákùnrin mi báyìí. Yàtọ̀ sí àpò tó kó òkúta yìí sí, òun àti ìyàwó rẹ̀ tún fún mi ní òdòdó róòsì funfun méjìlá.”

Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní sí Ẹ̀tanú àti Àìbánilò-Lọ́gbọọgba Mọ́!

Ẹ̀tanú àti àìbánilò-lọ́gbọọgba máa tó dohun tí kò sí mọ́. Lọ́nà wo? Ohun kan ni pé Jésù Kristi tó fi hàn pé òun ò ní “ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú,” ló máa jẹ́ Olùṣàkóso. (Aísáyà 11:1-5) Síwájú sí i, àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé tí Jésù máa ṣàkóso lé lórí, á máa fàwọn ànímọ́ bíi ti Jésù ṣèwà hù lọ́nà pípé, torí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Bàbá rẹ̀, ni wọ́n á ti máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́.—Aísáyà 11:9.

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti Jésù ti bẹ̀rẹ̀ báyìí, a sì ń tipasẹ̀ rẹ̀ mú àwọn èèyàn Ọlọ́run gbára dì láti wà láàyè títí láé nínú ètò àwọn nǹkan tá a sọ dọ̀tun pátápátá. Torí náà, o ò ṣe jẹ́ kí wọ́n máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o bàa lè jàǹfààní látinú ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yìí? a Òótọ́ ni pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú; ohun tó sì fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ.”—1 Tímótì 2:3, 4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ lákòókò tó tẹ́ ẹ lọ́rùn àti níbi tó o fẹ́, o lè kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ládùúgbò tàbí kó o kọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn àdírẹ́sì tá a tò sí ojú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí. Tàbí kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nípa lílo àdírẹ́sì ìkànnì wọn, ìyẹn www.watchtower.org.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Àkóbá tí ẹ̀tanú àti àìbánilò-lọ́gbọọgba ń ṣe fún aráyé máa tó dópin

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

ÀWỌN ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN TÓ YẸ KÉÈYÀN MÁA FI ṢÈWÀ HÙ

“Má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:17-21) Kí la lè rí kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? Báwọn míì bá ń ṣe búburú sí ẹ, rere ni kó o máa fi san án. Jésù Kristi sọ pé: “Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.” Síbẹ̀, kò kórìíra wọn pa dà.—Jòhánù 15:25.

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ . . . ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gálátíà 5:26) Ìlara àti owú tí kò tọ́ máa ń ba àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sì sábà máa ń yọrí sí ẹ̀tanú.—Máàkù 7:20-23.

“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí mi?’ Bẹ́ẹ̀ ni kíwọ náà máa ṣe sí wọn, láìka ọjọ́ orí, àwọ̀, èdè, tàbí àṣà wọn sí.

“Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá.” (Róòmù 15:7) Ṣó o máa ń sapá láti túbọ̀ mọ onírúurú èèyàn tí ìlú ìbílẹ̀ àti àṣà wọn yàtọ̀, pàápàá àwọn tá a jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run?—2 Kọ́ríńtì 6:11.

“Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ohun yòówù káwọn míì máa ṣe sí ẹ, Ọlọ́run ò ní kọ̀ ẹ́ sílẹ̀ láé, bó o bá jẹ́ adúróṣinṣin.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ará Samáríà kan tó jẹ́ aládùúgbò rere ran Júù kan táwọn ọlọ́ṣà jà lólè lọ́wọ́