Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Lélẹ̀ Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Lélẹ̀ Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Lélẹ̀ Fún Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun wá sí ayé ‘kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún òun, bí kò ṣe kí òun lè ṣe ìránṣẹ́, kí òun sì fi ọkàn òun fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Mátíù 20:28) Tọkàntọkàn ló fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún àǹfààní àwa èèyàn.

Báwo ni Jésù ṣe fi ikú rẹ̀ pèsè ìràpadà? Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Torí ta ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀? Kí sì ni ikú Jésù lè ṣe fún ẹ?

Tayọ̀tayọ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi pè ọ́ láti wá gbọ́ ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè yìí. Ọjọ́ Tuesday, March 30, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ ni Ìrántí Ikú Kristi bọ́ sí lọ́dún yìí. Lọ́jọ́ náà, a máa gbọ́ ìdáhùn látinú Ìwé Mímọ́ sáwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ẹ jù lọ láti ṣèrántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Jọ̀wọ́ béèrè ibi tí wọ́n ti máa ṣe é àti àkókò tí wọ́n máa ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.