Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tó Bá Ń Kólòlò
Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tó Bá Ń Kólòlò
“Bí mo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kólòlò báyìí, àyà mi á bẹ̀rẹ̀ sí í já, èyí á wá mú kí n túbọ̀ máa kólòlò sí i. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti já sínú kòtò ńlá kan, mi ò sì lè jáde níbẹ̀. Nígbà kan, mo tiẹ̀ lọ sọ́dọ̀ afìṣemọ̀rònú kan bóyá á rí nǹkan ṣe sí i. Ó sọ pé àfi kí n lọ wá ọ̀rẹ́bìnrin kan, tí màá lè máa bá ní àjọṣepọ̀ kí n lè túbọ̀ dá ara mi lójú! Bí mi ò ṣe pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́ nìyẹn. Mo kàn fẹ́ káwọn èèyàn gbà mí bí mo ṣe rí.”—Rafael, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32].
WO BÓ ṣe máa rí lára rẹ bó bá jẹ́ pé ṣe lò ń làágùn lákọlákọ torí pé o kàn fẹ́ júwe ọ̀nà fún onímọ́tò tó béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ rẹ, tó sì jẹ́ pé ṣe lọ̀rọ̀ máa ń kọ́ ẹ lẹ́nu tó o bá ń sọ̀rọ̀ tó fi jẹ́ pé ìró àkọ́kọ́ ni wàá máa tún pè ṣáá. Irú ipò táwọn èèyàn tí iye wọ́n tó ọgọ́ta mílíọ̀nù kárí ayé wà nìyẹn, ìyẹn àwọn tó ń kólòlò. Èyí fi hàn pé, bá a bá kó ọgọ́rùn-ún èèyàn jọ, ẹnì kan nínú wọn máa jẹ́ akólòlò. a Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn máa ń fi wọn ṣẹ̀sín, wọ́n sì máa ń dẹ́yẹ sí wọn. Wọ́n tiẹ̀ máa ń wò wọ́n bí ẹni tí kò ní làákàyè bí àwọn èèyàn yòókù, torí pé àwọn akólòlò kì í fẹ́ lo ọ̀rọ̀ tó máa fún wọn níṣòro, ọ̀rọ̀ tó rọrùn ni wọ́n sábà máa ń lò.
Kí ló ń fa ìkólòlò? Ṣé ó ṣeé wò sàn? Ṣé nǹkan kan wà tí àwọn akólòlò lè ṣe tí ọ̀rọ̀ á fi túbọ̀ dá ṣáká lẹ́nu wọn? Kí sì ni àwọn ẹlòmíì lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?
Ǹjẹ́ A Tiẹ̀ Mọ Ohun Tó Ń Fà Á?
Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló ń jẹ́ káwọn èèyàn máa kólòlò àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ lé àwọn ẹ̀mí náà jáde kí onítọ̀hún tó lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro yìí. Nígbà Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú, àwọn èèyàn sọ pé ahọ́n ló ń fà á. Kí ni wọ́n wá ṣe sí i? Ńṣe ni wọ́n máa ń fi irin gbígbóná jó àwọn akólòlò lẹ́nu pẹ̀lú àwọn èròjà oríṣiríṣi! Láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e àwọn oníṣẹ́ abẹ máa ń gé àwọn iṣan àti ẹran ahọ́n, wọ́n tiẹ̀ tún máa ń ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀nà ọ̀fun pàápàá láti wo ìkólòlò. Àmọ́, gbogbo àwọn ọ̀nà rírorò wọ̀nyí kò yanjú ìṣòro náà.
Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé oríṣiríṣi nǹkan ló lè mú kéèyàn máa kólòlò, kì í ṣe ohun kan ṣoṣo. Àìbalẹ̀ ọkàn lè fà á. Ó sì tún lè jẹ́ àjogúnbá, torí èyí tó ju ìdajì lọ nínú àwọn tó ń kólòlò ló jẹ́ pé wọ́n ní mọ̀lẹ́bí tó ní irú ìṣòro yìí. Bákan náà, ìwádìí tí àwọn oníṣègùn tó máa ń ya àwòrán ọpọlọ ṣe fi hàn pé bí ọpọlọ àwọn akólòlò ṣe ń ṣiṣẹ́ lórí èdè yàtọ̀. Dókítà Nathan Lavid sọ nínú ìwé rẹ̀ Understanding Stuttering pé, àwọn kan “lè ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ kí ọpọlọ wọn tó sọ fún wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n pe ọ̀rọ̀.” b
Torí náà, ó lè máà jẹ́ pé ọ̀nà tí ẹnì kan gbà ń ronú ni olórí ohun tó ń fa ìkólòlò, bí àwọn kan ti rò tẹ́lẹ̀. Ìwé kan tó n jẹ́, No Miracle Cures sọ pé, “Ohun tá à ń sọ ni pé, kì í ṣe nǹkan táwọn èèyàn gbà gbọ́ ló ń fa ìkólòlò, a ò sì lè fipá mú àwọn akólòlò láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já gaara.” Àmọ́, ìṣòro yìí lè ní ipa tí kò dáa lórí èrò àti ìṣe wọn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé àwọn ò ní lè ṣe àwọn nǹkan kan, irú bíi bíbá àwùjọ sọ̀rọ̀ tàbí sísọ̀rọ̀ lórí fóònù.
Ìrànwọ́ fún Àwọn Tó Ń Kólòlò
Ó múnú ẹni dùn láti mọ̀ pé àwọn tó ń kólòlò lè kọrin, wọ́n lè súfèé, wọ́n lè bá ara wọn tàbí ohun ọ̀sìn wọn sọ̀rọ̀, wọ́n lè sọ̀rọ̀ láàárín àwùjọ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa sín ẹlòmíì jẹ́ kí wọ́n má sì fi bẹ́ẹ̀ kólòlò tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ kólòlò rárá. Bákan náà, tá a bá kó ọmọ mẹ́wàá tó ń kólòlò jọ, mẹ́jọ nínú wọn máa ń borí ìṣòro yẹn láìjẹ́ pé wọ́n gba ìtọ́jú kankan. Àmọ́, àwọn tó kù wá ń kọ́?
Lóde òní, wọ́n máa ń ṣe àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan fáwọn tó ń kólòlò táá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn máa sunwọ̀n sí i. Lára àwọn ọgbọ́n tí wọ́n máa ń dá ni pé, wọ́n máa ń dẹ àgbọ̀n, ètè àti ahọ́n wọn, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí èémí wọn wá láti abonú. Wọ́n tún lè kọ́ àwọn tó níṣòro yìí láti kọ́kọ́ fa atẹ́gùn díẹ̀ sínú abonú wọn lẹ́yìn náà kí wọ́n mí síta díẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Láfikún sí i, wọ́n lè fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa fa àwọn fáwẹ̀lì gùn àti àwọn kọ́ńsónáǹtì kan. Bí ọ̀rọ̀ bá ṣe túbọ̀ ń yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu ni ọ̀rọ̀ wọn á máa lọ geere.
Ó lè má ju wákàtí bíi mélòó kan téèyàn á fi ṣe èyí. Àmọ́, láti lè lo àwọn àbá tó wà lókè yìí nígbà tí ọkàn ẹni kò lélẹ̀ lè gba pé kéèyàn fi dánra wò fún ọ̀pọ̀ wákàtí.
Ìgbà wo ló yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí? Ṣé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kàn fi ọmọ tó ń kólòlò sílẹ̀ bóyá ìṣòro náà á yanjú bó ṣe ń dàgbà? Ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn pé ìṣòro náà máa ń ṣàdédé yanjú lára àwọn ọmọ tó kólòlò fún nǹkan bí ọdún márùn-ún. Ìwé No Miracle Cures sọ pé, “Nígbà tí ọmọ kan tó ń kólòlò bá fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́fà, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ọ̀rọ̀ kò já geere lẹ́nu rẹ̀ mọ́, bí kò bá gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ sísọ.” Torí náà, “á dáa kí wọ́n tètè gbé àwọn ọmọ tó bá ń kólòlò lọ sọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ sísọ àti èdè bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.” Méjì nínú mẹ́wàá lára àwọn ọmọdé tó ń kólòlò ni wọ́n ṣì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi dàgbà. Mẹ́fà sí mẹ́jọ nínú mẹ́wàá lára irú àwọn ọmọ yìí ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ sísọ máa ń ṣiṣẹ́ fún. c
Má Ṣe Ju Ara Rẹ Lọ
Robert Quesal tó jẹ́ onímọ̀ nípa àrùn inú ara tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, tóun náà sì tún máa ń kólòlò
sọ pé, fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń kólòlò, kò yẹ kí wọ́n máa retí pé àwọn á lè yanjú ìṣòro náà débi pé ọ̀rọ̀ ò ní máa kọ́ wọn lẹ́nu mọ́ rárá. Rafael tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí kò tíì borí ìṣòro yìí pátápátá, àmọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti túbọ̀ ń já geere. Ó sọ pé: “Ìṣòro mi túbọ̀ máa ń pọ̀ sí i nígbà tí mo bá fẹ́ kàwé tàbí tí mo bá fẹ́ sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ tàbí kẹ̀ nígbà témi àti obìnrin tó rẹwà bá jọ ń sọ̀rọ̀. Mo máa ń ṣọ́ra ṣe gan-an torí àwọn èèyàn máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ti wá ń gbìyànjú láti má ṣe ju ara mi lọ, mi ò sì ka ara mi sí pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ. Torí náà, ní báyìí tí mo bá kólòlò nígbà tí mo bá fẹ́ pe ọ̀rọ̀ kan, mo lè rẹ́rìn-ín, àmọ́ màá fara balẹ̀ kí n tó tún máa bọ́rọ̀ mi lọ.”Ohun tí Rafael sọ yìí bá ohun tí Àjọ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Akólòlò Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ mu, wọ́n sọ pé, “Bí ẹni tó ń kólòlò bá borí ìbẹ̀rù pé ọ̀rọ̀ lè kọ́ òun lẹ́nu ó máa rọrùn fún un láti borí ìṣòro yìí ju tó bá kàn ń tiraka pé òun ò fẹ́ ṣe àṣìṣe.”
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ọ̀rọ̀ máa ń kọ́ lẹ́nu kò jẹ́ kíyẹn dí wọn lọ́wọ́ fífi ìgbésí ayé wọn ṣe ohun tó nítumọ̀. Àwọn kan nínú wọn tiẹ̀ ti di olókìkí, lára wọn ni onímọ̀ ẹ̀kọ́ físíìsì náà, Alàgbà Isaac Newton, olórí ìlú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Winston Churchill àti òṣèré ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà James Stewart. Àwọn míì ti kọ́ àwọn ohun míì tí kò la ọ̀rọ̀ sísọ lọ, irú bíi lílo àwọn ohun èlò ìkọrin, yíya àwòrán tàbí kíkọ́ èdè àwọn adití. Ó yẹ kí àwa tá a lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọyì báwọn tó ń kólòlò ṣe máa ń sapá tó kí wọ́n tó lè sọ̀rọ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fún wọn níṣìírí ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tá a bá lè ṣe é dé.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bá a bá kó èèyàn mẹ́wàá tó ń kólòlò jọ, á lé ní mẹ́jọ lára wọn tó máa jẹ́ ọkùnrin.
b Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwádìí táwọn èèyàn ṣe lórí ohun tó ń fa ìkólòlò àti ìtọ́jú rẹ̀ lè jọra, síbẹ̀ wọ́n lè má fohùn ṣọ̀kan nígbà gbogbo. Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú tàbí èrò kan ló dára jù o.
c Nígbà míì àwọn oníṣègùn tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn tó ń kólòlò lè dábàá pé kí wọ́n lo ẹ̀rọ tí kò ní jẹ́ kí wọ́n tètè gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn fúnra wọn bá sọ tàbí kí wọ́n lo oògùn tó máa dín àìbalẹ̀ ọkàn tó máa ń bá ọ̀rọ̀ sísọ rìn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
ÌRÀNLỌ́WỌ́ WO LO LÈ ṢE FÚN ẸNI TÓ BÁ Ń KÓLÒLÒ?
● Jẹ́ kí wọ́n fara balẹ̀, má sì kán wọn lójú nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Kòókòó jàn-ánjàn-án tó pọ̀ nínú ayé lónìí sábà máa ń dá kún ìṣòro wọn.
● Dípò tí wàá fi sọ fún ẹni tó ń kólòlò pé kó máa rọra sọ̀rọ̀, ṣe ni kí ìwọ fúnra rẹ máa rọra sọ̀rọ̀, nípa bẹ́ẹ̀ òun náà á lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ. Fetí sílẹ̀ dáadáa. Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Má ṣe bá a parí ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ. Dákẹ́ díẹ̀ kó o tó fèsì.
● Yẹra fún ṣíṣe àríwísí, má sì máa ṣàtúnṣe sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Máa wo ojú rẹ̀ bó ṣe yẹ, kó o sì jẹ́ kí ìfaraṣàpèjúwe àti ọrọ̀ tó o bá sọ fi hàn pé ohun tó ń sọ ló jẹ ọ́ lógún kì í ṣe bó ṣe sọ ọ́.
● Kíkólòlò kì í ṣe ohun má-jẹ̀ẹ́-a-gbọ́. Bó o bá ń rẹ́rìn-ín músẹ́, tó sì jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ sọ fún ẹni tó ń kólòlò pé o lóye ìṣòro rẹ̀, ara á tu onítọ̀hún dáadáa. O lè sọ pé: “Nígbà míì, kì í rọrùn láti sọ ohun tá a fẹ́ sọ.”
● Ju gbogbo rẹ̀ lọ, fi í lọ́kàn balẹ̀ pé o mọyì rẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“NÍ KẸ̀RẸ̀KẸ̀RẸ̀ MI KÌ Í FI BẸ́Ẹ̀ KÓLÒLÒ MỌ́”
Ọdún bíi mélòó kan ni Víctor fi jẹ́ akólòlò láwọn ìgbà tí wàhálà ńlá kan fi ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wọn, àmọ́ ó borí ìṣòro yìí láìgba ìtọ́jú kankan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Víctor, torí náà, ó forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, tí wọ́n máa ń ṣe ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ nínú àwọn ìjọ wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí àtimáa gba ìtọ́jú lórí ọ̀rọ̀ sísọ la ṣe dá ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, ó máa ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè sunwọ̀n sí i nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kí wọ́n sì lè máa fi ìdánilójú sọ̀rọ̀.
Orúkọ ìwé tí wọ́n máa ń lò ní ilé ẹ̀kọ́ yìí ni Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, “Ohun Tí O Lè Ṣe Bí O Bá Ń kólòlò,” ìwé náà sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí o má ṣe jẹ́ kó sú ọ láti máa sapá. . . . Bí a bá yan ọ̀rọ̀ fún ọ láti sọ, múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa. Fi gbogbo ọkàn sí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ. . . . Bó bá di pé o bẹ̀rẹ̀ sí kólòlò bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ, gbìyànjú láti máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀. Dẹ iṣan àgbọ̀n rẹ. Máa lo gbólóhùn kúkúrú. Dín ìwọ̀n tó o fi ń lo àwọn ọ̀rọ̀ ìyanu bíi ‘hún-ùn’ àti ‘áà’ kù.”
Ṣé ilé ẹ̀kọ́ yìí ran Víctor lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ ni mo máa ń fi sọ́kàn, àmọ́ mo máa ń fi ohun tí mo fẹ́ sọ sọ́kàn débi pé, mo máa ń gbàgbé pé mo níṣòro. Mo tún máa ń fi ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ dánra wò dáadáa. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mi kì í fi bẹ́ẹ̀ kólòlò mọ́.”