Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Awon Eranko

Awon Eranko

Gbogbo wa la máa ń jàǹfààní lára àwọn ẹranko lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ǹjẹ́ a máa jíhìn fún ohun tá a bá ṣe sí àwọn ẹranko?

Báwo ló sẹ yẹ ká máa ṣe sí àwọn ẹranko?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan gbà pé bó bá ṣe wù wá la lè ṣe àwọn ẹranko. Àmọ́ àwọn míì sọ pé bá a ṣe ń ṣe sí àwọn èèyàn náà ló yẹ ká máa ṣe sí àwọn ẹranko.

  • Ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹranko sọ pé ó yẹ káwọn ẹranko ní “ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin, kò sì yẹ ká kàn máa fi wọ́n ṣòwò lásán.” Ó kúkú wá la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ pé: “A ò gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ẹranko bí ohun ìní wa.”

  • Obìnrin olówó kan tó ń jẹ́ Leona Helmsleyn ṣe ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí àṣejù. Ńṣe ló pín ogún tí ó tó mílíọ̀nù méjìlá owó dọ́là [ìyẹn nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì náírà] fún ajá rẹ̀, ó sì tún ṣèwé pé lẹ́yìn tí ajá náà bá kú, kí wọ́n sin òkú rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ibi tí wọ́n sìn òkú òun sí.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Báwo lo ṣe rò pé ó yẹ ká máa ṣe sí àwọn ẹranko?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá sọ́ fún àwa èèyàn pé kí á “máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Níbàámu pẹ̀lú èyí, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run ka àwa èèyàn sí pàtàkì ju àwọn ẹranko lọ.

Ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú èyí tá a mẹ́nu kàn lókè yìí tún ti kókó yìí lẹ́yìn. Níbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

Torí pé Ọlọ́run dá “ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,” ọ̀nà tá à ń gbà lo àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bí ọgbọ́n, ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo ṣàrà ọ̀tọ̀. Bákan náà, ó máa ń wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run ká sì máa hùwà dáadáa. Àmọ́ àwọn ẹranko kò lè ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ torí pé Ọlọ́run kò dá wọn “ní àwòrán rẹ̀.” Èyí fi hàn pé à níyì ju àwọn ẹranko lọ, a ò sì lè máa kẹ́ wọn bí ẹni kẹ́ èèyàn.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé a lè máa ṣe àwọn ẹranko ṣúkaṣùka? Rárá o.

  • Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ní kí wọ́n jẹ́ kí àwọn ẹran ọ̀sìn máa sinmi. Ó tún ní kí wọ́n máa fún wọn ní oúnjẹ, kí wọ́n sì máa tọ́jú wọn kí wọ́n má bàa ṣèṣe.—Ẹ́kísódù 23:4, 5; Diutarónómì 22:10; 25:4.

“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò máa fi ṣe iṣẹ́ rẹ; ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, kí ìwọ ṣíwọ́, kí akọ màlúù rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ lè sinmi.”Ẹ́kísódù 23:12.

Ṣé ó burú láti pa àwọn ẹranko?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn ọlọ́dẹ àtàwọn apẹja kan máa ń pa àwọn ẹranko láti fi dára yá. Àwọn míì sì gbà pẹ̀lú ohun tí òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tó ń jẹ́ Leo Tolstoy sọ pé “ìwà burúkú gbáà” ni kéèyàn pa ẹran, kó sì tún jẹ ẹ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run fàyè gba pípa àwọn ẹranko tó bá fẹ́ wu ẹ̀mí èèyàn léwu àti pé, a lè fi awọ ẹranko ṣe aṣọ. (Ẹ́kísódù 21:28; Máàkù 1:6) Bíbélì sọ pé èèyàn lè pa ẹran jẹ. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 9:3 sọ pé: “Gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ fún yín.” Kódà, Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti pa ẹja, wọ́n sì jẹ ẹ́.—Jòhánù 21:4-13.

Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Torí náà, Ọlọ́run ò fẹ́ ká kàn máa pa àwọn ẹranko fún ìdárayá.

Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ka ẹ̀mí àwọn ẹranko sí pàtàkì.

  • Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, ó ní: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀ àti ẹran agbéléjẹ̀ ní irú tirẹ̀ àti olúkúlùkù ẹran tí ń rìn ká ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì wá rí i pé ó dára.”Jẹ́nẹ́sísì 1:25.

  • Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa Jèhófà pé: “Ó ń fi oúnjẹ àwọn ẹranko fún wọn.” (Sáàmù 147:9) Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ayé yìí mú kí oúnjẹ pọ̀ yanturu fún àwọn ẹranko, kí wọ́n sì ríbi wọ̀ sí.

  • Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Ènìyàn àti ẹranko ni ìwọ gbà là, Jèhófà.” (Sáàmù 36:6) A rí àpẹẹrẹ èyí nígbà Ìkún-omi ọjọ́ Nóà tí Ọlọ́run gba èèyàn mẹ́jọ là, tó sì dá gbogbo onírúurú ẹranko sí, kó tó pa àwọn èèyàn búburú run.—Jẹ́nẹ́sísì 6:19.

Èyí fi hàn pé Jèhófà ka àwọn ẹranko sí, kò sì fẹ́ ká máa ṣe wọ́n ṣúkaṣùka.

‘Olódodo ń bójú tó ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀.’ Òwe 12:10.