JÍ! November 2015 | Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
Èrò tí kò tọ́ nípa owó lè mú ká máa ṣìwà hù.
KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
Àwọn ìbéèrè méje wà tó o lè fi yẹ ara rẹ wò bóyá èrò tó yẹ ló ní nípa owó.
TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Bí Awọ Aláǹgbá Thorny Devil Ṣe Ń Fa Omi Mu
Báwo ni aláǹgbá yìí ṣe ń fa omi láti ẹsẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹnu rẹ̀?
ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ
Ìgbà Tó Yẹ Kó O Pa Dà Sọ́dọ̀ Àwọn Òbí Rẹ
Ṣé nǹkan ṣòro fún ẹ nígbà tó filé lẹ̀ láti lọ máa dá gbé? Àwọn ìmọ̀ràn yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Èèyàn Rẹ Bá Ń Ṣàìsàn
Ìdààmú máa ń bá ẹnì tó bá lọ rí dókítà tàbí tí wọ́n dá dúró sí ilé ìwòsàn. Báwo lo ṣe lè ran èèyàn rẹ tó wà nírú ipò yìí lọ́wọ́?
OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Nípa Ìdílé
Àwọn ìṣòro wo làwọn ìdílé sábà máa ń kojú? Ibo ni wọ́n ti lè rí ìmọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́?
Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì
Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Wo ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣeéṣe kó o ti béèrè nípa wa.
Eré Ọwọ́ fún Àwọn Ọmọdé
Lo àwọn eré ọwọ́ tó gbádùn mọ́ni tó dá lórí Bíbélì yìí láti fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà rere.