Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

A Rí “Péálì Kan Tó Níye Lórí Gan-An”

A Rí “Péálì Kan Tó Níye Lórí Gan-An”

Ẹ̀KA ọ́fíìsì wa tó wà ní Australasia ni Arákùnrin Winston àti Pamela Payne (ìyẹn Pam) ti ń sìn. Wọ́n ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kojú onírúurú nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n ṣe ń ti ibì kan lọ sí ibòmíì ni wọ́n ń mú ara wọn bá àṣà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mu, kódà wọ́n fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro títí kan oyún tó bà jẹ́ lára ìyàwó. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ tutù, wọ́n sì ń fìtara bá iṣẹ́ ìsìn wọn lọ. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí, a máa gbọ́ díẹ̀ lára àwọn ìrírí tí wọ́n ní.

Winston, báwo lo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run?

Inú oko kan ní ìpínlẹ̀ Queensland lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni mo dàgbà sí, ìdílé wa ò sì fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn ìsìn. Torí pé àdádó la wà, àwọn tó wà nínú ìdílé wa nìkan ni mo sábà máa ń rí. Ìgbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlá (12) ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run. Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n mọ òtítọ́ nípa rẹ̀. Nígbà tó yá, mo kúrò lóko, mo sì ríṣẹ́ sí ìlú Adelaide ní South Australia. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21), mo lọ fún ìsinmi nílùú Sydney, ibẹ̀ sì ni mo ti pàdé Pam. Òun ló sọ fún mi nípa àwọn onísìn British-Israel. Àwọn ẹlẹ́sìn yìí gbà pé àtọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó lọ sígbèkùn làwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti wá. Torí náà, nígbà tí mo pa dà dé Adelaide, mo dá ọ̀rọ̀ yẹn sílẹ̀ níwájú ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ẹni yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láàárín wákàtí díẹ̀ tá a fi jọ sọ̀rọ̀, ó ṣe àwọn àlàyé kan tó jẹ́ kí n gbà pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà tí mo gbà nígbà tí mo ṣì kéré. Inú mi dùn pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín mo ti wá mọ òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá mi àti Ìjọba rẹ̀. Kí n kúkú sọ pé mo ti rí “péálì kan tó níye lórí gan-an.”​—Mát. 13:45, 46.

Pam, àtikékeré nìwọ náà ti ń wá òtítọ́, ṣé o lè sọ fún wa bó o ṣe rí i?

Ìlú Coffs Harbour ní ìpínlẹ̀ New South Wales ni mo dàgbà sí, ìdílé wa sì fẹ́ràn ìsìn gan-an. Àwọn òbí mi àtàwọn òbí mi àgbà dara pọ̀ mọ́ àwọn onísìn British-Israel. Wọ́n kọ́ èmi, àbúrò mi ọkùnrin, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àtàwọn ẹbí wa míì pé Ọlọ́run dìídì fojúure hàn sáwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Mi ò fi taratara gba ohun tí wọ́n sọ yẹn gbọ́, torí náà ṣe ló dà bíi pé mi ò tíì mọ Ọlọ́run. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14), mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí oríṣiríṣi ṣọ́ọ̀ṣì. Lára ẹ̀ ni ṣọ́ọ̀ṣì Anglican, ìjọ Onítẹ̀bọmi àti ṣọ́ọ̀ṣì Seventh-day Adventist. Síbẹ̀, mi ò mọ Ọlọ́run.

Nígbà tó yá, ìdílé wa kó lọ sílùú Sydney, ibẹ̀ sì ni mo ti pàdé Winston nígbà tó wá fún ìsinmi níbẹ̀. Bó ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tá a jọ sọ ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ìyẹn, tó bá ti kọ lẹ́tà sí mi, ọ̀rọ̀ Bíbélì ló máa ń sọ ṣáá, kí n sòótọ́, ìyẹn máa ń múnú bí mi gan-an. Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń bá mi sọ.

Lọ́dún 1962, mo kó lọ sí Adelaide kí n lè wà nítòsí Winston. Ó ṣètò pé kí n dé sọ́dọ̀ àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Thomas àti Janice Sloman. Tọkọtaya yìí ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Papua New Guinea rí. Ṣe ni wọ́n mú mi bí ọmọ, ó ṣe tán mi ò ju ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) péré lọ nígbà yẹn, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ Jèhófà. Bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìyẹn, kò sì pẹ́ tí mo fi gbà pé mo ti rí òtítọ́. Lẹ́yìn témi àti Winston ṣègbéyàwó, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní kíkún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, ṣe ló túbọ̀ jẹ́ ká mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó dà bíi péálì iyebíye.

Winston, sọ díẹ̀ fún wa nípa àwọn ibi tó o ti ṣiṣẹ́ sìn nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

A. Àwòrán àwọn ilẹ̀ ibi tá a ti ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká

B. Sítáǹbù àwọn erékùṣù kan tá a ti sìn. Erékùṣù Gilbert àti Ellice ni wọ́n ń pe Kiribati àti Tuvalu tẹ́lẹ̀

D. Ìlú kan tó lẹ́wà gan-an ni erékùṣù Funafuti ní Tuvalu. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn erékùṣù tá a ṣèbẹ̀wò sí kí wọ́n tó rán àwọn míṣọ́nnárì lọ síbẹ̀

Kò pẹ́ lẹ́yìn témi àti Pam ṣègbéyàwó ni Jèhófà ti ń ṣí “ilẹ̀kùn ńlá” sílẹ̀ fún wa. (1 Kọ́r. 16:9) Arákùnrin Jack Porter ló kọ́kọ́ jẹ́ ká rí ilẹ̀kùn náà. Òun ni alábòójútó àyíká wa nígbà yẹn. (Èmi àti ẹ̀ jọ wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka báyìí.) Jack àti ìyàwó rẹ̀ Roslyn gbà wá níyànjú pé ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, a sì gbádùn iṣẹ́ náà fún ọdún márùn-ún. Nígbà tí mo pé ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Pam lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká láwọn erékùṣù tó wà ní South Pacific Islands, tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Fiji ń bójú tó nígbà yẹn. Àwọn erékùṣù náà ni American Samoa, Samoa, Kiribati, Nauru, Niue, Tokelau, Tonga, Tuvalu àti Vanuatu.

Nígbà yẹn, àwọn tó wà láwọn erékùṣù yẹn máa ń fura sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà, ṣe la máa ń ṣọ́ra ṣe. (Mát. 10:16) Àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ kéré gan-an, kódà àwọn ìjọ míì kì í nílé tí wọ́n lè fi wá wọ̀ sí. Torí náà, a máa ń wá ibi tá a lè dé sí lọ́dọ̀ àwọn ará abúlé, wọ́n sì máa ń gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀.

O nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, kí ló mú kó o nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ yìí?

Ilé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà ní Samoa

Mo rántí pé nígbà tá a dé erékùṣù Tonga, ìwọ̀nba ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé kékeré lédè Tongan làwọn ará ní. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì làwọn ará máa ń lò lóde ẹ̀rí. Torí náà, nígbà tá a ṣe ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin fáwọn alàgbà, àwọn alàgbà mẹ́ta kan gbà láti tú ìwé Otitọ sí èdè Tongan bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa. Nígbà tí wọ́n tú ìwé yẹn tán, Pam tẹ ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ náà, a sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí wọ́n lè tẹ̀ ẹ́ jáde. Iṣẹ́ náà gbà tó nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ. Ká sòótọ́, ìtumọ̀ yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ dáa tó, síbẹ̀ ìwé yìí ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Tongan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi àti Pam kì í ṣe atúmọ̀ èdè, àmọ́ ìrírí yìí ló mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà.

Pam, tẹ́ ẹ bá fi ìgbésí ayé yín ní Ọsirélíà wé ti àwọn erékùṣù yìí, kí lẹ lè sọ nípa ẹ̀?

Mọ́tò yìí wà lára àwọn ibi tá a gbé nígbà tá à ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká

Kò jọra rárá! Láwọn ibì kan ẹ̀fọn àti ooru tó gbóná gan-an la máa ń fara dà. Láwọn ibòmíì sì rèé, eku tàbí àìsàn ni, kódà nígbà míì, a kì í rí oúnjẹ tó tó jẹ. Láìfi àwọn nǹkan yìí pè, tá a bá parí iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, inú wa máa ń dùn gan-an bá a ṣe ń wo òkun láti inú fale wa, ìyẹn orúkọ tí àwọn ará Samoa máa ń pe ilé tí wọ́n fi koríko bò àmọ́ tí kò ní ògiri. Ní àwọn alẹ́ tí òṣùpá bá mọ́lẹ̀ rekete, a máa ń rí àwọn igi àgbọn, kódà kedere la máa ń rí òkun tó lọ salalu. Irú àwọn àsìkò yìí máa ń jẹ́ ká ṣàṣàrò, ká sì gbàdúrà sí Jèhófà. Ó tún máa ń jẹ́ ká gbọ́kàn wa kúrò lórí àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ bára dé, ká sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn.

A nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé gan-an. Inú wọn máa ń dùn tí wọ́n bá rí àwọn aláwọ̀ funfun, wọ́n sì máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ wọn. Nígbà kan tá a lọ sí erékùṣù Niue, ọmọkùnrin kékeré kan fọwọ́ pa ọwọ́ ọkọ mi, ó wá sọ pé, “Irun ara yín dà bí ìyẹ́ adìyẹ, mo fẹ́ràn ẹ̀ gan-an.” Ó ṣe kedere pé kò rí ẹni tó nírun lára tóyẹn rí, kò sì mọ nǹkan míì tó lè fi wé.

Ó máa ń dùn wá tá a bá ń rí bí nǹkan ṣe nira fáwọn èèyàn ibẹ̀. Àyíká wọn rẹwà lóòótọ́, àmọ́ wọn ò ní ìtọ́jú ìlera tó gbámúṣé, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ lómi mímu. Síbẹ̀, àwọn ará wa ò jẹ́ kíyẹn kó ìdààmú bá wọn, torí pé ó ti mọ́ wọn lára. Tí wọ́n bá ti wà pẹ̀lú ìdílé wọn, tí wọ́n ní ibi tí wọ́n á ti jọ́sìn, tí wọ́n sì ń yin Jèhófà, ó ti parí. Kò sóhun tí wọ́n ń wá jùyẹn lọ. Ohun tá a kọ́ lára wọn mú ká rí i pé ohun díẹ̀ lèèyàn nílò, ìyẹn sì mú ká pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn wa.

Nígbà míì Pam, ìwọ lo máa lọ wá omi pọn tó o sì máa dáná oúnjẹ níbi tó yàtọ̀ síbi tó ti mọ́ ẹ lára, báwo lo ṣe ń ṣe é?

Pam rèé tó ń fọ aṣọ wa nígbà tá a wà ní Tonga

Ọpẹ́lọpẹ́ bàbá mi tó kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Wọ́n jẹ́ kí n mọ bí wọ́n ṣe ń dáná igi àti béèyàn ṣe ń jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn. Nígbà kan tá a lọ ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù Kiribati, ilé kékeré kan la dé sí, koríko ni wọ́n fi bò ó, igi ọparun ni wọ́n sì fi ṣe ògiri. Tí mo bá fẹ́ se oúnjẹ, kódà kó má ju díẹ̀ lọ, àfi kí n gbẹ́ kòtò kí n wá kó háhá àgbọn sínú ẹ̀ kí iná náà lè jó dáadáa. Tí mo bá fẹ́ pọn omi, èmi àtàwọn obìnrin míì máa ń tò sídìí kànga. Igi kan tí wọ́n so okùn mọ́ nídìí ni wọ́n fi ń fa omi, wọ́n á wá so garawa kan mọ́ ọn. Tẹ́ni tó kàn bá fẹ́ fa omi, ó ní ọgbọ́n táá fi ju garawa náà kó lè fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, kómi sì wọnú ẹ̀. Mo rò pé ó rọrùn ni, àfìgbà tó kàn mí. Ni mo bá jù ú títí, àmọ́ mi ò rómi bù, ṣe ni garawa náà ń léfòó. Làwọn tó wà ńbẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, nígbà tí wọ́n rẹ́rìn-ín tán, ọ̀kan nínú wọn bá mi fa omi náà. Kí n sòótọ́, kò sígbà tí wọn kì í ràn wá lọ́wọ́.

Ẹ̀yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe láwọn erékùṣù yẹn. Ṣẹ́ ẹ lè sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí yín fún wa?

Winston: Àwọn àṣà kan ò tètè mọ́ wa lára. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ará bá gbà wá lálejò, gbogbo oúnjẹ wọn ni wọ́n máa ń gbé síta fún wa. Àwa á sì parí gbogbo oúnjẹ náà, láìmọ̀ pé kò yẹ ká parí ẹ̀. Nígbà tá a wá mọ̀, a máa ń ṣẹ́ oúnjẹ kù fún wọn. Síbẹ̀, àwọn ará yẹn ò bínú sí wa. Inú wọn máa ń dùn tá a bá wá bẹ̀ wọ́n wò, wọ́n sì máa ń fojú sọ́nà sígbà tá a tún máa wá lóṣù mẹ́fà míì. Àwọn ará yẹn ò mọ àwọn ará tó wà níbòmíì yàtọ̀ sí èmi àti Pam.

Winston àtàwọn ará ń lọ sóde ẹ̀rí ní erékùṣù Niue

Ìbẹ̀wò wa tún máa ń jẹ́rìí fáwọn èèyàn tó wà ládùúgbò. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn abúlé ló máa ń rò pé ẹ̀sìn abúlé lásán lẹ̀sìn táwọn ará wa ń ṣe. Torí náà, nígbà tí wọ́n rí èmi àtìyàwó mi tá a wá bẹ̀ wọ́n wò láti ilẹ̀ òkèèrè, ó jọ wọ́n lójú gan-an, kódà ó wú wọn lórí.

Pam: Ohun kan ṣẹlẹ̀ tí mi ò jẹ́ gbàgbé láé. Nígbà tá a lọ sí Kiribati, àwọn ará tó wà níjọ ibẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Arákùnrin Itinikai Matera nìkan ni alàgbà, gbogbo ohun tó lè ṣe láti bójú tó wa ló ṣe. Lọ́jọ́ kan, ó gbé apẹ̀rẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ wa, ẹyin kan ṣoṣo ló wà nínú ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ni mo gbé e wá fún.” Ohun tó ṣe yẹn jọ wá lójú gan-an torí ẹyin adìyẹ ò wọ́pọ̀ níbẹ̀, ó sì wọ́n. Ó lè jọ pé ẹ̀bùn yẹn kéré, àmọ́ a mọyì ẹ̀ gan-an.

Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, oyún bà jẹ́ lára ẹ Pam, kí ló mú kó o lè fara dà á?

Mo lóyún lọ́dún 1973 nígbà témi àtọkọ mi wà ní South Pacific. A wá pinnu láti pa dà sí Ọsirélíà, àmọ́ oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn, oyún náà bà jẹ́. Ọ̀rọ̀ yẹn dun ọkọ mi gan-an, ó ṣe tán, ọmọ tiẹ̀ náà ni. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹ̀dùn ọkàn tí mo ní ń dín kù sí i, àmọ́ kò lọ tán títí dìgbà tá a gba Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009. Apá “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” sọ pé: “Ṣé ọmọ inú oyún tó kú sínú ìyá rẹ̀ máa ní àjíǹde?” Àpilẹ̀kọ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo ni ọ̀rọ̀ náà wà. Ó máa wo gbogbo ọgbẹ́ ọkàn tá a ní nínú ayé búburú yìí sàn, nígbà tó bá pàṣẹ fún ọmọ rẹ̀ pé kó “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Àpilẹ̀kọ náà tún jẹ́ ká túbọ̀ mọyì òtítọ́ iyebíye táwa èèyàn Jèhófà ní pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa yanjú ìṣòro aráyé. Báwo ni ìgbésí ayé wa ì bá ṣe rí ká sọ pé a ò nírètí yìí?

A tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lẹ́yìn tá a pàdánù ọmọ wa. A kọ́kọ́ lo oṣù díẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Ọsirélíà, lẹ́yìn náà la pa dà sẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Lọ́dún 1981, lẹ́yìn tá a lo ọdún mẹ́rin ní New South Wales àti Sydney, ètò Ọlọ́run ní ká máa bọ̀ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Ọsirélíà, ibẹ̀ la sì wà látìgbà yẹn.

Winston, ṣé àwọn ìrírí tó o ní láwọn erékùṣù South Pacific ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní báyìí tó o jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Australasia?

Bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tó yá ètò Ọlọ́run ní kí ẹ̀ka ọ́fíìsì Ọsirélíà máa bójú tó American Samoa àti Samoa. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n da ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní New Zealand pọ̀ mọ́ ti Ọsirélíà. Ní báyìí, Ọsirélíà, American Samoa àti Samoa, erékùṣù Cook Islands, New Zealand, Niue, Timor-Leste, Tokelau àti Tonga wà lára àwọn ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia ń bójú tó. Mo sì ti ní àǹfààní láti lọ ṣèbẹ̀wò sí èyí tó pọ̀ jù lára wọn gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ìrírí tí mo ní nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ràn mí lọ́wọ́ gan-an ní báyìí tí mò ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó gbogbo agbègbè yẹn.

Winston àti Pam rèé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Australasia

Ní paríparí ẹ̀, ìrírí témi àti Pam ní ti jẹ́ kí n mọ̀ pé kì í ṣe àwọn àgbàlagbà nìkan ló ń wá Ọlọ́run. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ọmọdé náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó dà bíi péálì iyebíye, kódà táwọn mọ̀lẹ́bí wọn ò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i. (2 Ọba 5:2, 3; 2 Kíró. 34:1-3) Kò sí àní-àní, Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Nígbà tí èmi àti Pam bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run ní ohun tó lé ní àádọ́ta (50) ọdún sẹ́yìn, a ò mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Ó dá mi lójú pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣeyebíye gan-an, ṣe ló dà bíi péálì tí kò ṣe é díye lé. Torí náà, a ti pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun gbà á mọ́ wa lọ́wọ́!