Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Ń Sẹ̀san fún Àwọn Tó Ń Fi Taratara Wá A

Jèhófà Máa Ń Sẹ̀san fún Àwọn Tó Ń Fi Taratara Wá A

“Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”​—HÉB. 11:6.

ORIN: 85, 134

1, 2. (a) Báwo ni ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ṣe tan mọ́ra? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò?

BÍBÉLÌ sọ pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà “nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:19) Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin gan-an, ọ̀nà kan tó sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa ń bù kún wọn. Bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà bá ṣe jinlẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wa ṣe máa lágbára tó. Kì í ṣe pé a mọ̀ pé Ọlọ́run wà nìkan ni, a tún mọ̀ pé ó máa ń sẹ̀san fáwọn tó nífẹ̀ẹ́.​—Ka Hébérù 11:6.

2 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ohun tó lè ṣe, kò sí bá ò ṣe ní mẹ́nu kan jíjẹ́ tó jẹ́ olùsẹ̀san. Kí ìgbàgbọ́ wa tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbà pé Ọlọ́run máa ń san èrè fáwọn tó ń fi taratara wá a, torí pé “ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí.” (Héb. 11:1) Ó dájú pé tá a bá nígbàgbọ́, àá gbà pé Ọlọ́run máa bù kún wa. Àmọ́, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́san láyé àtijọ́ àti lóde òní? A máa jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí.

JÈHÓFÀ ṢÈLÉRÍ PÉ ÒUN MÁA BÙ KÚN ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ ÒUN

3. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nínú Málákì 3:10?

3 Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí pé òun máa san ẹ̀san fún àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá ojúure òun. Ó sọ pé: “ ‘Jọ̀wọ́, dán mi wò, . . . ’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ ” (Mál. 3:10) Tá a bá ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí rọ̀ wá, à ń fi hàn pé a mọrírì ìwà ọ̀làwọ́ Jèhófà.

4. Kí nìdí tí ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33 fi dá wa lójú?

4 Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé tí wọ́n bá ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run máa bù kún wọn. (Ka Mátíù 6:33.) Ohun tó mú kó dá Jésù lójú ni pé kò sígbà tí Jèhófà kì í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Jésù mọ̀ pé àwọn ìlérí Jèhófà kì í yẹ̀. (Aísá. 55:11) Torí náà, ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Héb. 13:5) A ti wá rí bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe bá ohun tí Jésù sọ mu pé tá a bá wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, Ọlọ́run á bù kún wa.

Jésù mú kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run máa san wọ́n lẹ́san gbogbo ohun tí wọ́n yááfì (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Báwo ni èsì tí Jésù fún Pétérù ṣe fún ìgbàgbọ́ wa lókun?

5 Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pétérù bi Jésù pé: “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” (Mát. 19:27) Dípò tí Jésù fi máa bá Pétérù wí pé ó ṣe béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi dá òun àtàwọn yòókù lójú pé Ọlọ́run máa san wọ́n lẹ́san gbogbo ohun tí wọ́n yááfì. Àwọn àpọ́sítélì yẹn àtàwọn míì máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, wọ́n á gbádùn àwọn ìbùkún míì. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 19:29) Ìbùkún táwọn ọmọ ẹ̀yìn á rí gbà máa ju gbogbo ohun tí wọ́n yááfì lọ. Kí lèèyàn lè fi sílẹ̀ tàbí yááfì torí Ìjọba Ọlọ́run tó lè dà bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ bàbá, ìyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò àtàwọn ọmọ téèyàn á rí nínú ètò Jèhófà?

“ÌDÁKỌ̀RÓ FÚN ỌKÀN” WA

6. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣèlérí pé òun máa sẹ̀san fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀?

6 Ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa sẹ̀san fún wa ń mú ká lè jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò. Láfikún sí àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn báyìí torí a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, á tún ń fojú sọ́nà láti gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún lọ́jọ́ iwájú. (1 Tím. 4:8) Kò sí àní-àní pé mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà “ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a” máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀.​—Héb. 11:6.

7. Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe dà bí ìdákọ̀ró?

7 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ pé: “Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mát. 5:12) Yàtọ̀ sáwọn tó máa gba èrè wọn lọ́run, àwọn tó nírètí àtigbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé náà máa ‘yọ̀, wọ́n á sì fò sókè fún ìdùnnú.’ (Sm. 37:11; Lúùkù 18:30) Torí náà, yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé ńbí la máa wà, ìrètí tá a ní máa dà bí ‘ìdákọ̀ró fún ọkàn wa, tí ó dájú, tó sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in.’ (Héb. 6:17-20) Bí ìdákọ̀ró ṣe máa ń di ọkọ̀ mú tí kì í jẹ́ kí ìjì dojú rẹ̀ dé, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tó dájú ṣe máa ràn wá lọ́wọ́. Kò ní jẹ́ ká ṣinú rò, kò ní jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn bò wá mọ́lẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa dojú dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lágbára láti fara da àdánwò.

8. Báwo ni ìrètí tá a ní kò ṣe ní jẹ́ ká ṣe àníyàn àṣejù?

8 Torí pé a ní ìrètí nínú ohun tí Bíbélì sọ, a kì í ṣe àníyàn àṣejù. Ńṣe làwọn ìlérí Ọlọ́run máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, bí ìgbà téèyàn fi oògùn sójú ọgbẹ́ tára sì tuni. Ọkàn wa balẹ̀ pé tá a bá ‘ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà,’ ó máa ‘gbé wa ró’! (Sm. 55:22) Ó dá wa lójú hán-ún pé Ọlọ́run máa ṣe “ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò.” (Éfé. 3:20) Wò ó ná, kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run máa ṣe kọjá gbogbo ohun tí a béèrè, ó máa ṣe é lọ́pọ̀ yanturu, àní sẹ́, á tiẹ̀ ṣe é ju ọ̀pọ̀ yanturu lọ fún wa!

9. Báwo làwọn ìlérí Jèhófà ṣe dá wa lójú tó?

9 Ká tó lè rí èrè náà gbà, a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà yóò bù kún ọ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún láti gbà, kìkì bí ìwọ kì yóò bá kùnà láti fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ kí o lè kíyè sára láti pa gbogbo àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí mọ́. Nítorí tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò bù kún ọ, ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún ọ gan-an.” (Diu. 15:4-6) Ṣé ó dá ẹ lójú gan-an pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ń fòótọ́ ọkàn sìn ín láìyẹsẹ̀? Àpẹẹrẹ púpọ̀ ló wà táá jẹ́ kó dá ẹ lójú.

JÈHÓFÀ SAN WỌ́N LẸ́SAN

10, 11. Báwo ni Jèhófà ṣe san Jósẹ́fù lẹ́san?

10 Torí wa ni Jèhófà ṣe mú kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ Bíbélì. Àkọsílẹ̀ àwọn tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà àti bó ṣe bù kún wọn wà nínú Bíbélì. (Róòmù 15:4) Àpẹẹrẹ kan ni ti Jósẹ́fù. Láìṣẹ̀ láìrò, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n tà á sóko ẹrú, lẹ́yìn ìyẹn ni ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ parọ́ mọ́ ọn, bó ṣe di pé wọ́n ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n nílẹ̀ Íjíbítì nìyẹn. Ǹjẹ́ Ọlọ́run náà wá gbàgbé Jósẹ́fù? Kò sóhun tó jọ ọ́! Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá . . . Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ohun tí ó sì ń ṣe ni Jèhófà ń mú kí ó yọrí sí rere.” (Jẹ́n. 39:21-23) Láìka bí wọ́n ṣe pọ́n Jósẹ́fù lójú tó, ó gbà pé lọ́jọ́ kan Ọlọ́run á dá sọ́rọ̀ náà.

11 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Fáráò dá Jósẹ́fù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ó sì sọ Jósẹ́fù tó jẹ́ ẹrú tẹ́lẹ̀ di igbá kejì ara rẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́n. 41:1, 37-43) Nígbà tí ìyàwó Jósẹ́fù bí ọmọkùnrin méjì, Jósẹ́fù sọ àkọ́bí ní Mánásè. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ti mú kí n gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.” Ó sì sọ èkejì ní Éfúráímù. Ó wá ní: “Ọlọ́run ti mú kí n so èso ní ilẹ̀ ipò ìráre mi.” (Jẹ́n. 41:51, 52) Torí pé Jósẹ́fù jẹ́ adúróṣinṣin, Jèhófà bù kún un, èyí sì mú kó lè dá ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti tàwọn ará Íjíbítì sí. Kókó náà ni pé Jósẹ́fù gbà pé Jèhófà ló san òun lẹ́san tó sì bù kún òun.​—Jẹ́n. 45:5-9.

12. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò?

12 Ẹlòmíì tí Jèhófà tún bù kún ni Jésù Kristi torí pé ó jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà lójú onírúurú àdánwò. Kí ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú.” (Héb. 12:2) Kò sí àní-àní pé inú Jésù dùn gan-an pé òun sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Baba rẹ̀ tẹ́wọ́ gbà á, ó sì tún fún un láwọn àǹfààní àgbàyanu. Bíbélì sọ pé ó “ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” Bíbélì tún sọ pé: ‘Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga, ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn.’​—Fílí. 2:9.

JÈHÓFÀ KÌ Í GBÀGBÉ OHUN TÁ A ṢE

13, 14. Báwo làwọn ohun tá a bá ṣe fún Jèhófà ṣe máa ń rí lára rẹ̀?

13 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì àwọn ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀, bó ti wù kó kéré tó. Ó mọ àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù àtàwọn ohun tó ń kó àníyàn bá wa. Tí ìṣòro àtijẹ àtimu, àìsàn tàbí ẹ̀dùn ọkàn kò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, Jèhófà lóye wa ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka àwọn ìṣòro tó ò ń kojú.​—Ka Hébérù 6:10, 11.

14 Ká rántí pé a lè sọ ìṣòro wa fún Jèhófà “Olùgbọ́ àdúrà,” ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa gbọ́ tiwa. (Sm. 65:2) Bíbélì sọ pé: “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. Kódà, ó lè lo àwọn ará láti pèsè ìrànlọ́wọ́ yìí. (2 Kọ́r. 1:3) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fàánú hàn sáwọn èèyàn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17; Mát. 6:3, 4) Torí náà, tá a bá ń fi tinútinú ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, Jèhófà gbà pé òun la ṣe é fún. Ó sì ṣèlérí pé òun máa san èrè fún wa.

JÈHÓFÀ MÁA BÙ KÚN WA NÍSINSÌNYÍ ÀTI TÍTÍ LÁÉ

15. Èrè wo ni ìwọ ń fojú sọ́nà láti rí gbà lọ́jọ́ iwájú? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

15 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń fara dà á torí pé wọ́n ní ìrètí àtigba “adé òdodo, . . . èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo, yóò fi san [wọ́n] lẹ́san ní ọjọ́ yẹn.” (2 Tím. 4:7, 8) Síbẹ̀ tó ò bá sí lára àwọn tó ní ìrètí àtilọ sọ́run, kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fojú pa ẹ́ rẹ́. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Bíbélì pè ní “àwọn àgùntàn mìíràn” ń fojú sọ́nà láti gbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Nínú ayé tuntun yẹn, wọ́n á “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”​—Jòh. 10:16; Sm. 37:11.

16. Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 3:19, 20 ṣe tù wá nínú?

16 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ohun tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kò tó nǹkan tàbí pé bóyá ni inú Jèhófà dùn sí wa. Kódà, a lè máa ronú pé bóyá la yẹ lẹ́ni tí Jèhófà máa fún lérè. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (Ka 1 Jòhánù 3:19, 20.) Ohun yòówù ká ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà torí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ àti ìfẹ́ tá a ní fún un, Jèhófà á rí i pé òun san wá lẹ́san, kódà bí ohun tá a ṣe kò bá tiẹ̀ jọ àwa fúnra wa lójú.​—Máàkù 12:41-44.

17. Sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá à ń gbádùn báyìí.

17 Kódà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé Èṣù yìí, Jèhófà ń bù kún àwa èèyàn rẹ̀. Jèhófà ń mú ká máa gbá yìn-ìn nínú Párádísè tẹ̀mí, a sì ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún. (Aísá. 54:13) Bí Jésù ṣe sọ ọ́ náà ló rí, Jèhófà ń bù kún wa báyìí, torí pé a wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (Máàkù 10:29, 30) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé à ń fi taratara wá Ọlọ́run, a tún ń gbádùn ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tí kò láfiwé.​—Fílí. 4:4-7.

18, 19. Báwo ni ìbùkún tí Jèhófà ń fún wa ṣe ń rí lára wa?

18 Kárí ayé làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń sọ nípa oore tó ń ṣe fún wa. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arábìnrin Bianca tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó ń bá mi gbé ìṣòro mi, kò sì fi mí sílẹ̀ lọ́jọ́ kan. Ayé yìí ò lójú mọ́, gbogbo nǹkan sì ti dojú dé. Àmọ́ bí mo ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, ṣe ló dà bíi pé ó dì mí mú, tọ́kàn mi sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Kò sígbà tí mo ṣe ohun kan fún Jèhófà tí kì í bù kún mi ní ìlọ́po-ìlọ́po.”

19 Àpẹẹrẹ míì ni ti Arábìnrin Paula tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ẹni àádọ́rin [70] ọdún ni, ó sì ní àrùn tó ń mú kí ihò wà nínú ọ̀pá ẹ̀yìn, ìyẹn àrùn spina bifida. Ó sọ pé: “Lóòótọ́ mi ò lè rìn kiri bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ ìyẹn ò ní kí n dín iṣẹ́ ìwàásù mi kù. Mo máa ń lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù, bíi kí n wàásù lórí fóònù tàbí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì, mo ní ìwé kan tí mo kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn kókó látinú ìtẹ̀jáde wa sí, mo sì máa ń yẹ̀ ẹ́ wò látìgbàdégbà. Mo pe ìwé náà ní ‘Ìwé Tó Ń Gbé Mi Ró.’ Téèyàn bá ń ronú nípa àwọn ìlérí Jèhófà, èèyàn á tètè borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Ìṣòro yòówù ká ní, Jèhófà máa dúró tì wá, á sì ràn wá lọ́wọ́.” Ìṣòro rẹ lè yàtọ̀ sí ti Bianca àti Paula. Síbẹ̀, máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún ìwọ àtàwọn míì. Ó máa dáa tó o bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún ẹ nísinsìnyí àti bó ṣe máa bù kún ẹ lọ́jọ́ iwájú!

20. Kí la máa rí gbà tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn?

20 Máa rántí pé Jèhófà máa san ẹ́ ní “ẹ̀san ńláǹlà” bó o ṣe ń gbàdúrà sí i, tó o sì ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ‘lẹ́yìn tí o bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tán, wàá rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.’ (Héb. 10:35, 36) Torí náà, jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára, kó o sì máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó dá ẹ lójú pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni wàá ti gba ẹ̀san yíyẹ.​—Ka Kólósè 3:23, 24.