Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni òfin tó wà nínú Léfítíkù 19:16 pé ká má “dìde lòdì sí ẹ̀mí ẹnì kejì” wa túmọ̀ sí, ẹ̀kọ́ wo la sì lè kọ́ látinú ẹ̀?
Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́. Láfikún síyẹn, ó sọ fún wọn pé: “O ò gbọ́dọ̀ máa bani lórúkọ jẹ́ káàkiri láàárín àwọn èèyàn rẹ. O ò gbọ́dọ̀ dìde lòdì sí ẹ̀mí ẹnì kejì rẹ. Èmi ni Jèhófà.”—Léf. 19:2, 16.
Gbólóhùn náà “dìde lòdì sí ẹ̀mí” gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà yọ dáadáa, àmọ́ kí ló túmọ̀ sí? Ìwé àwọn Júù kan tó ṣàlàyé ìwé Léfítíkù sọ pé: “Kò rọrùn láti lóye ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ . . . torí pé ó ṣòro láti mọ ohun tí àkànlò èdè Hébérù náà túmọ̀ sí, àmọ́ ìtumọ̀ ẹ̀ lógidì ni ‘má dúró lórí, nítòsí tàbí lẹ́gbẹ̀ẹ́.’ ”
Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún (15) ni ẹsẹ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó ní: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po. Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀. Máa ṣe ìdájọ́ òdodo tí o bá ń dá ẹjọ́ ẹnì kejì rẹ.” (Léf. 19:15) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, òfin tó wà nínú ẹsẹ kẹrìndínlógún (16) pé ká má “dìde lòdì sí” ẹnì kejì wa máa túmọ̀ sí pé àwa èèyàn Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ rẹ́ ẹnì kejì wa jẹ nílé ẹjọ́, nídìí ọrọ̀ ajé tàbí nínú ìdílé, a ò sì gbọ́dọ̀ yí ọ̀rọ̀ po torí ká lè jàre. Lóòótọ́, kò yẹ ká ṣe àwọn nǹkan yẹn, àmọ́ ọ̀nà míì wà tá a lè gbà lóye ohun tí ẹsẹ kẹrìndínlógún (16) ń sọ.
Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ yẹn sọ. Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa bani lórúkọ jẹ́ káàkiri. Ẹ fi sọ́kàn pé ìbanilórúkọjẹ́ ju òfófó lásán lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé òfófó náà máa ń dá wàhálà sílẹ̀. (Òwe 10:19; Oníw. 10:12-14; 1 Tím. 5:11-15; Jém. 3:6) Àwọn tó ń bani lórúkọ jẹ́ máa ń dìídì parọ́ mọ́ àwọn míì káwọn èèyàn lè máa fojú burúkú wò wọ́n. Ẹni tó ń bani lórúkọ jẹ́ lè jẹ́rìí èké láti ta ko ẹlòmíì kódà tí ohun tó sọ yẹn bá tiẹ̀ máa ṣekú pa onítọ̀hún. Ẹ rántí pé àwọn abanilórúkọjẹ́ ló jẹ́rìí èké láti ta ko Nábótì tí wọ́n fi sọ ọ́ lókùúta pa. (1 Ọba 21:8-13) Èyí jẹ́ ká rí i pé abanilórúkọjẹ́ lè dìde lòdì sí ẹ̀mí ẹlòmíì bó ṣe wà nínú apá tó gbẹ̀yìn Léfítíkù 19:16.
Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan lè ba ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ nítorí ìkórìíra. 1 Jòhánù 3:15 sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apààyàn, ẹ sì mọ̀ pé kò sí apààyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun ṣì wà nínú rẹ̀.” Jèhófà tún fi ọ̀rọ̀ míì ti ẹsẹ kẹrìndínlógún lẹ́yìn, ó ní: “O ò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn rẹ.”—Léf. 19:17.
Torí náà, ìkìlọ̀ pàtàkì ni òfin tó wà nínú Léfítíkù 19:16 jẹ́ fún àwa Kristẹni. A ò gbọ́dọ̀ ní èrò burúkú sí ẹlòmíì tàbí ká bà á lórúkọ jẹ́. Ní kúkúrú, ìkórìíra lè jẹ́ kí ẹnì kan “dìde lòdì sí” ẹlòmíì ní ti pé ó lè máa jowú ẹ̀ kó sì bà á lórúkọ jẹ́. Torí náà, àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni.—Mát. 12:36, 37.