ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn sí Wa Lónírúurú Ọ̀nà
NÍGBÀ tí bàbá mi tó ń jẹ́ Arthur wà lọ́dọ̀ọ́, ó bẹ̀rù Ọlọ́run gan-an, ó sì wù ú pé kó di àlùfáà ìjọ Mẹ́tọ́díìsì. Àmọ́, ó yí èrò rẹ̀ pa dà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń lọ sípàdé wọn. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1914 lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]. Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, ìjọba sì ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun ìjọba jù ú sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́wàá ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kingston tó wà nílùú Ontario, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Lẹ́yìn tí wọ́n dá bàbá mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó di apínwèé-ìsìn-kiri, tá à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà báyìí.
Lọ́dún 1926, bàbá mi fẹ́ ìyá mi tó ń jẹ́ Hazel Wilkinson, tí ìyá rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dún 1908. Wọ́n bí mi ní April 24, 1931, èmi sì ni ìkejì lára ọmọ mẹ́rin tí wọ́n bí. Ìdílé wa fẹ́ràn ìjọsìn Jèhófà gan-an, bí bàbá mi sì ṣe nífẹ̀ẹ́ Bíbélì ló mú káwa náà fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdílé wa sábà máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.—Ìṣe 20:20.
MO JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ BÍI TI BÀBÁ MI, MO SÌ DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939, nígbà tó sì máa dọdún tó tẹ̀ lé e wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Kánádà. Àwọn iléèwé ìjọba máa ń ní káwọn ọmọléèwé kí àsíá, kí wọ́n sì kọ orin orílẹ̀-èdè. Torí pé èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Dorothy kì í dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n máa ń lé wa jáde kúrò ní kíláàsì tí wọ́n bá ti ń kọ orin orílẹ̀-èdè. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, tíṣà mi dójú tì mí, ó sọ pé ojo ni mí. Nígbà tá a jáde iléèwé lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọ kíláàsì mi dọwọ́ bò mí, wọ́n sì lù mí lálùbọlẹ̀. Àmọ́ ṣe lohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí n pinnu pé màá túbọ̀ máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
Nígbà tí mo pọ́mọ ọdún mọ́kànlá ní July 1942, wọ́n ṣèrìbọmi fún mi nínú táǹkì omi tó wà nínú oko kan. Tá a bá wà lákòókò ìsinmi níléèwé, mo máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò ìsinmi (èyí tá à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ báyìí). Lọ́dún kan, èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́ta míì lọ wàásù fáwọn agégẹdú tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kò yàn fúnni ní apá àríwá ìlú Ontario.
Mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní May 1, 1949. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé lọ́wọ́ nígbà yẹn, torí náà wọ́n ní kí n wá ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tó sì di December 1, mo di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Kánádà. Ibi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé ni wọ́n gbé mi sí, mo sì kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé. Tọ̀sántòru la fi ń tẹ̀wé àṣàrò kúkúrú kan tó sọ̀rọ̀ nípa inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wa ní Kánádà, ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ni mo sì fi ṣiṣẹ́ lálẹ́.
Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Ìgbà kan wà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tó fẹ́ lọ wàásù nílùú Quebec ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ètò Ọlọ́run sì ní kí n fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Nígbà yẹn, wọ́n ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn ará nílùú Quebec. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà ni Mary Zazula tó wá láti ìlú Edmonton, Alberta. Torí pé òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tó ń jẹ́ Joe kò ṣíwọ́ àtimáa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn òbí wọn tó jẹ́ onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì lé wọn síta. Ní June 1951, àwọn méjèèjì ṣèrìbọmi, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà làwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bí mo ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, mo rí i pé Mary fọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́, ìyẹn sì wú mi lórí gan-an. Mo wá sọ lọ́kàn mi pé, ‘Tí kò bá sí nǹkan míì, ẹni tí màá fẹ́ nìyí.’ Oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà la ṣègbéyàwó, ìyẹn ní January 30, 1954. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, wọ́n ní ká lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Lẹ́yìn náà, a bẹ àwọn ìjọ tó wà ní apá àríwá ìlú Ontario wò fún ọdún méjì.
Bí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé ṣe ń gbòòrò sí i, ètò Ọlọ́run rọ àwọn ará pé kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àwa náà wá ronú pé tá a bá lè fara da òtútù tó wà ní Kánádà àtàwọn ẹ̀fọn burúkú tó wà níbẹ̀, kò síbi tí ètò Ọlọ́run rán wa lọ tá ò ní lè gbé. Ní July 1956, a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹtàdínlọ́gbọ̀n [27] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, nígbà tó sì máa di November, a ti dé orílẹ̀-èdè Bìràsílì níbi tí wọ́n rán wa lọ.
IṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ BÌRÀSÍLÌ
Nígbà tá a dé ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Bìràsílì, wọ́n kọ́ wa lédè Potogí. Lẹ́yìn tá a ti mọ bí wọ́n ṣe ń kí èèyàn lédè náà, tá a sì ti há ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú kan sórí, wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Tá a bá rí ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, a máa ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó sọ bí ayé ṣe máa rí nínú Ìjọba Ọlọ́run fun un. Ní ọjọ́ tá a kọ́kọ́ lọ sóde ẹ̀rí, obìnrin kan tẹ́tí sí wa dáadáa, torí náà mo ka Ìṣípayá 21:3, 4 fún un, bí mo ṣe ka ẹsẹ yẹn tán báyìí, ṣe ni mo ṣubú lulẹ̀, mo sì dákú! Ọ̀pọ̀ ìgbà nirú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ torí pé ooru tó wà níbẹ̀ kò tíì bá mi lára mu.
Nígbà tó yá, wọ́n rán wa lọ sílùú Campos. Kò sí ìjọ kankan níbẹ̀ nígbà yẹn, àwùjọ àdádó kan péré ló wà, àmọ́ ní báyìí ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló wà níbẹ̀. Nígbà yẹn, ilé àwọn míṣọ́nnárì kan wà níbẹ̀ táwọn arábìnrin mẹ́rin ń gbé. Àwọn arábìnrin náà ni Esther Tracy, Ramona Bauer, Luiza Schwarz, àti Lorraine Brookes tó ń jẹ́ Wallen báyìí. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe nílé náà ni pé kí n máa fọṣọ kí n sì máa wá igi tí wọ́n á fi dáná. Lẹ́yìn tá a parí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lálẹ́ Monday kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó bà wá lẹ́rù. Jẹ́jẹ́ ni ìyàwó mi sùn sórí àga ìnàyìn, tá a sì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a ṣe lọ́jọ́ náà. Bó ṣe gbórí kúrò lórí ìrọ̀rí báyìí, ṣe ni ejò kan fò síta. Lọ̀rọ̀ bá di bóò-lọ-o-yàá-mi, àfìgbà tí mo pa ejò náà.
Lẹ́yìn tá a ti kọ́ èdè Potogí fún ọdún kan, mo di alábòójútó àyíká. Tá a bá dé àwọn ìgbèríko, ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ la máa ń gbé. Kò síná, orí ẹní la máa ń sùn, ẹṣin la máa gùn, kẹ̀kẹ́ ẹṣin la sì máa fi ń kó ẹrù wa. Nígbà kan tá a lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni, ọkọ̀ ojú irin la wọ̀ lọ, a dé sílùú kan tó wà lórí òkè, a sì gba ilé síbẹ̀. Ìwé ìròyìn ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì fi ránṣẹ́ sí wa ká lè rí nǹkan fi ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́ ká lè kó àwọn ìwé náà.
Lọ́dún 1962, ètò Ọlọ́run ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ jákèjádò Bìràsílì fáwọn arákùnrin, wọ́n sì tún pe àwọn arábìnrin tó jẹ́ míṣọ́nnárì. Oṣù mẹ́fà ni mo fi ń lọ láti ilé ẹ̀kọ́ kan sí òmíì láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ Mary ò bá mi lọ. Lára àwọn ìlú tí mo ti dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ni Manaus, Belém, Fortaleza, Recife, àti Salvador. Nígbà kan, a ṣètò ìpàdé àgbègbè nílé sinimá kan nílùú Manaus. Òjò rọ̀ gan-an nígbà àpéjọ yẹn, ó sì ba omi tó ṣeé mu jẹ́, kódà kò jẹ́ ká ríbi tá a ti máa jẹun torí nígbà yẹn ètò Ọlọ́run ṣì máa ń ṣètò oúnjẹ láwọn àpéjọ wa. Torí náà, mo kàn sílé iṣẹ́ àwọn ológun pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́, inú mi sì dùn pé ọ̀gágun onínúure kan ló dá mi lóhùn. Ó ṣètò omi mímu fún wa títí tá a fi parí àpéjọ náà, ó sì rán àwọn sójà láti wá ri tẹ́ǹtì ńlá méjì ká lè ríbi tá a ti máa jẹun.
Nígbà tí mi ò sí nílé, Mary lọ wàásù níbì kan táwọn Potogí ti ń ṣòwò. Kò sẹ́ni tó tẹ́tí sí Mary torí pé bí wọ́n ṣe máa rí towó ṣe nìkan ni wọ́n mọ̀ níbẹ̀. Ni Mary bá sọ fáwọn ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì kan pé, “Kò síbi tí mi ò lè gbé láyé yìí àfi orílẹ̀-èdè Pọ́túgà.” Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn, ṣe la gba lẹ́tà kan, ètò Ọlọ́run ní ká lọ máa sìn lórílẹ̀-èdè Pọ́túgà. Nígbà tá a sì ń sọ yẹn, ìjọba ibẹ̀ fòfin de iṣẹ́ wa, síbẹ̀ a gba iṣẹ́ náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ya Mary lẹ́nu gan-an.
IṢẸ́ ÌSÌN WA NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ PỌ́TÚGÀ
A dé ìlú Lisbon, Pọ́túgà ní August 1964. Àwọn ọlọ́ọ̀pá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ń wá àwọn arákùnrin wa kiri, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn. Torí náà, a ò ṣètò pé káwọn ará wá pàdé wa, a ò sì kàn sáwọn ará kankan. Ilé ibùwọ̀ kan la wà títí tá a fi rí ìwé ìgbéèlú gbà. Lẹ́yìn tí wọ́n fún wa níwèé ìgbélùú, a gba ilé kan tá à ń gbé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní January 1965, a kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó nígbà tá a lọ sípàdé fúngbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn oṣù márùn-ún!
A gbọ́ pé ojoojúmọ́ làwọn ọlọ́pàá ń lọ sílé àwọn ará, wọ́n á tú ilé wọn, wọ́n á sì mú wọn. Láwọn àsìkò yẹn, ìjọba ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa pa, torí náà ilé àwọn arákùnrin la ti ń ṣèpàdé. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ni wọ́n mú lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá kí wọ́n lè gbọ́ tẹnu wọn. Wọ́n máa ń fìyà jẹ wọ́n kí wọ́n lè sọ orúkọ àwọn tó ń múpò iwájú. Torí náà, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ àbísọ pera wọn bíi José tàbí Paulo, dípò fífi orúkọ ìdílé pera wọn. Ohun táwa náà sì ṣe nìyẹn.
Báwọn ará ṣe máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé ló jẹ wá lógún. Iṣẹ́ ìyàwó mi ni pé kó máa tẹ Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì sórí bébà, lẹ́yìn náà àá wá ṣe ẹ̀dà rẹ̀.
A GBÈJÀ ÌHÌN RERE NÍ KÓÒTÙ
Nígbà tó di June 1966, wọ́n gbé wa lọ sílé ẹjọ́ tó wà nílùú Lisbon. Gbogbo àwọn ará mọ́kàndínláàádọ́ta [49] tó wà níjọ Feijó ni wọ́n mú wá láti jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n ń ṣèpàdé tí kò bófin mu nílé ẹnì kan. Káwọn ará lè mọ ohun tí wọ́n máa sọ, a ṣe ìdánrawò. Mo ṣe bíi lọ́yà ìjọba tó fẹ̀sùn kàn wọ́n, mo wá ń da ìbéèrè bò wọ́n, àwọn náà sì ń dáhùn. A mọ̀ pé wọn ò ní dá wa láre, àmọ́ a gbà pé àǹfààní ló máa jẹ́ fún wa láti jẹ́rìí fáwọn tó máa wà ní kóòtù náà. Nígbà tí lọ́yà tó gbẹjọ́ wa rò máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fa ọ̀rọ̀ Gàmálíẹ́lì yọ, ìyẹn ẹni tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 5:33-39) Àwọn oníròyìn gbé ọ̀rọ̀ ẹjọ́ náà sórí afẹ́fẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbọ́ ọ. Síbẹ̀, gbogbo àwọn ará yẹn ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n, àwọn kan oṣù kan àtààbọ̀, àwọn míì sì lo oṣù márùn-ún àtààbọ̀. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó múnú wa dùn? Lọ́yà tó gba ẹjọ́ wa rò lọ́jọ́sí ní ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Kódà ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé kó tó kú.
Ní December 1966, ètò Ọlọ́run sọ mí di alábòójútó ẹ̀ka, ọ̀pọ̀ àkókò ni mo sì lò lórí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ òfin àti ẹ̀tọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní. A ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọba gbà wá láyè pé ká máa jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe fẹ́ lórílẹ̀-èdè Pọ́túgà. (Fílí. 1:7) Nígbà tó sì máa di December 18, 1974, wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, a sì ń jọ́sìn Jèhófà bá a ṣe fẹ́. Torí náà, a ṣèpàdé mánigbàgbé kan nílùú Oporto àti Lisbon. Arákùnrin Nathan Knorr àti Frederick Franz wá láti oríléeṣẹ́ wa kí wọ́n lè bá wa yọ̀. Àpapọ̀ àwọn tó pé jọ sípàdé yẹn lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46,870].
Jèhófà rọ̀jò ìbùkún sórí iṣẹ́ ìwàásù wa débi pé ọ̀pọ̀ erékùṣù tí wọ́n ti ń sọ èdè Potogí làwọn èèyàn ti gba òtítọ́. Lára àwọn erékùṣù náà ni Azores, Cape Verde, Madeira àti São Tomé and Príncipe. Torí náà, ètò Ọlọ́run ní ká mú ẹ̀ka ọ́fíìsì wa gbòòrò sí i. Nígbà tó sì di April 23, 1988, a ya ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sí mímọ́. Tayọ̀tayọ̀ làwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta [45,522] fi pé jọ láti gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin Milton Henschel sọ lọ́jọ́ yẹn. Inú wa dùn gan-an pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó tó ogún tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Pọ́túgà náà pésẹ̀ síbẹ̀ lásìkò yẹn.
A KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN TÓ FÒÓTỌ́ ỌKÀN SIN JÈHÓFÀ
Bá a ṣe ń bá àwọn arákùnrin tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà ṣiṣẹ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn tí jẹ́ ká kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ lára Arákùnrin Theodore Jaracz nígbà tá a jọ bẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì kan wò. Ìṣòro ńlá kan ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè tá a bẹ̀ wò yẹn, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sì ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe. Arákùnrin Jaracz wá fi àwọn arákùnrin náà lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ẹ ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe. Ẹ jẹ́ ká fìyókù sílẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.” Àpẹẹrẹ míì ni tìgbà tá a lọ sí Brooklyn. Èmi àtìyàwó mi àtàwọn míì lọ kí Arákùnrin Franz. Torí pé Arákùnrin Franz ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a ní kó gbà wá nímọ̀ràn, ó wá sọ pé: “Ẹ rọ̀ mọ́ ètò Jèhófà, lọ́jọ́ dídùn lọ́jọ́ kíkan, ẹ má fètò náà sílẹ̀. Ètò yìí nìkan ló ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.”
A mọrírì ìmọ̀ràn yẹn gan-an, ohun tá a sì ṣe nìyẹn. Kò sígbà tínú wa kì í dùn tá a bá ń rántí àwọn ìbẹ̀wò tá a ṣe sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì lórílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìbẹ̀wò yẹn jẹ́ ká lè máa gbóríyìn fáwọn ará lọ́mọdé lágbà fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a sì máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú.
Ọjọ́ ogbó ti dé, àwa méjèèjì sì ti lé lọ́gọ́rin ọdún báyìí. Onírúurú àìsàn ló ń bá ìyàwó mi fínra. (2 Kọ́r. 12:9) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti dán ìgbàgbọ́ wa wò, àmọ́ ìyẹn ti mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì mú ká túbọ̀ pinnu pé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Tá a bá ń rántí bá a ṣe fayé wa sin Jèhófà, ṣe la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa lónírúurú ọ̀nà. *
^ ìpínrọ̀ 29 Arákùnrin Douglas Guest kú nígbà tá à ń ṣàkójọ ìrírí yìí, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí dójú ikú ní October 25, 2015.