Wọ́n Fìfẹ́ Hàn sí Wọn Gan-an
OBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Yomara àtàwọn àbúrò ẹ̀ ọkùnrin ń gbé ní abúlé kékeré kan lórílẹ̀-èdè Guatemala. Orúkọ àwọn àbúrò ẹ̀ ni Marcelo àti Hiver. Yomara bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà tó yá, àwọn àbúrò ẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta níṣòro kan. Wọn ò ríran rárá, wọn ò sì lè ka ìwé àwọn afọ́jú. Torí náà, ẹni tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń kàwé fún wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sì tún máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀.
Ohun míì tó jẹ́ ìṣòro ni bí wọ́n á ṣe máa lọ sípàdé ìjọ. Wọn ò lè dá lọ sílé ìpàdé tó sún mọ́ wọn jù, ìrìn náà sì máa ń gbà tó ogójì (40) ìṣẹ́jú. Àmọ́ àwọn ará ìjọ ṣètò bí wọ́n á ṣe máa mú wọn lọ sí gbogbo ìpàdé. Nígbà táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀, àwọn ará máa ń bá wọn múra iṣẹ́ wọn kí wọ́n lè mọ̀ ọ́n sórí.
Ní May 2019, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé ní abúlé wọn. Lásìkò yẹn, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan ti kó wá sí abúlé wọn. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà pinnu pé àwọn máa kọ́ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bí wọ́n á ṣe máa kàwé àwọn afọ́jú, tí wọ́n á sì mọ̀ ọ́n kọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tọkọtaya yìí ò mọ nǹkan kan nípa ẹ̀. Torí náà, wọ́n lọ sílé ìkówèésí kan kí wọ́n lè rí ìwé táá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa ìwé àwọn afọ́jú, kí wọ́n sì lè mọ bá a ṣe ń kọ́ àwọn afọ́jú.
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Yomara, Marcelo àti Hiver ti lè ka ìwé àwọn afọ́jú dáadáa, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. a Ní báyìí, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Marcelo sì tún di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni wọ́n ń gbájú mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Wọ́n ń fìtara sin Jèhófà, ìyẹn sì ti mú káwọn ará tó wà lágbègbè wọn máa fìtara sin Jèhófà.
Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn ará ìjọ torí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́. Yomara sọ pé: “Àtìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ wàásù fún wa ni wọ́n ti ń fìfẹ́ tòótọ́ hàn sí wa.” Marcelo sọ pé: “A ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ wa, a sì wà lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí ìfẹ́ so pọ̀ kárí ayé.” Yomara àtàwọn àbúrò ẹ̀ ń retí ìgbà tí ayé máa di Párádísè, tí wọ́n á sì fojú ara wọn rí i.—Sm. 37:10, 11; Àìsá. 35:5.
a Ètò Ọlọ́run ṣe ìwé kan tó ń jẹ́ Learn to Read Braille láti ran ẹni tó fọ́jú tàbí ẹni tí ò ríran dáadáa lọ́wọ́ kó lè mọ ìwé àwọn afọ́jú kà, kó sì lè mọ̀ ọ́n kọ.