Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 37 sọ pé a so ọ̀pá méjì pa pọ̀ di ọ̀kan. Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

Jèhófà fi ọkàn àwọn èèyàn rẹ̀ balẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé wọ́n máa pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n á sì tún pa dà di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa wà níṣọ̀kan láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.

Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé kó kọ ọ̀rọ̀ sára ọ̀pá méjì. Ohun tó máa kọ sára ọ̀pá àkọ́kọ́ ni, “Fún Júdà àti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì alájọṣe rẹ̀.” Ohun tó sì máa kọ sára ìkejì ni, “Fún Jósẹ́fù, ọ̀pá Éfúráímù, àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì alájọṣe rẹ̀.” Ọ̀pá méjèèjì máa di “ọ̀kan ṣoṣo” lọ́wọ́ Ìsíkíẹ́lì.—Ìsík. 37:15-17.

Àwọn wo ni “Éfúráímù” ṣàpẹẹrẹ? Jèróbóámù ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá, ìlà ìdílé Éfúráímù ló sì ti wá. Nínú gbogbo ẹ̀yà mẹ́wàá náà, ẹ̀yà Éfúráímù ni òléwájú lára wọn. (Diu. 33:13, 17; 1 Ọba 11:26) Ọ̀dọ̀ Éfúráímù tó jẹ́ ọmọ Jósẹ́fù ni ẹ̀yà yìí ti wá. (Núm. 1:32, 33) Jósẹ́fù rí ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ gbà látọ̀dọ̀ Jékọ́bù bàbá rẹ̀. Torí náà, ó tọ́ tá a bá pe ọ̀pá tó dúró fún ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ní “ọ̀pá Éfúráímù.” Ọdún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn ará Ásíríà kó ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì nígbèkùn. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn ni Ìsíkíẹ́lì kọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sílẹ̀. (2 Ọba 17:6) Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fọ́n káàkiri àwọn àgbègbè tí Bábílónì ń ṣàkóso torí pé àwọn ará Bábílónì ti ṣẹ́gun àwọn ará Ásíríà nígbà yẹn.

Ní ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì kó ẹ̀yà méjì tó wà ní gúúsù nígbèkùn pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀yà mẹ́wàá. Ìdílé Júdà làwọn tó ń jọba lórí ẹ̀yà méjì yìí ti wá, ilẹ̀ Júdà kan náà sì làwọn àlùfáà ń gbé torí pé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ sìn. (2 Kíró. 11:13, 14; 34:30) Torí náà, ó bá a mu wẹ́kú pé ọ̀pá “Júdà” dúró fún ẹ̀yà méjì náà.

Ìgbà wo ni ọ̀pá méjèèjì yìí di ọ̀kan? Ó di ọ̀kan nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn, tí wọ́n sì lọ tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn tó wá láti ẹ̀yà mẹ́wàá àtàwọn tó wá láti ẹ̀yà méjì ló jọ pa dà sí Ísírẹ́lì. Kò wá sí ìyapa kankan mọ́ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ìsík. 37:21, 22) Gbogbo wọn jọ ń sin Jèhófà pa pọ̀ níṣọ̀kan. Yàtọ̀ sí Ìsíkíẹ́lì, wòlíì Aísáyà àti Jeremáyà náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣọ̀kan yìí.—Aísá. 11:12, 13; Jer. 31:1, 6, 31.

Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí ń sọ nípa ìjọsìn tòótọ́? Ohun tó ń sọ ni pé: Jèhófà máa mú káwọn olùjọsìn rẹ̀ ‘di ọ̀kan ṣoṣo.’ (Ìsík. 37:18, 19) Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti wá ṣẹ ní àsìkò tiwa yìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọdún 1919 ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ nígbà tí Ọlọ́run tún wọn tò, tó sì mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Gbogbo bí Sátánì ṣe ń sapá láti pín wọn níyà, pàbó ló já sí.

Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ ló nírètí àtidi ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù lókè ọ̀run. (Ìṣí. 20:6) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ṣe ni wọ́n dà bí ọ̀pá Júdà. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn Júù tẹ̀mí yìí. (Sek. 8:23) Wọ́n dà bí ọ̀pá Jósẹ́fù, torí pé wọn ò sí lára àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi.

Àwùjọ méjèèjì yìí jọ ń sin Jèhófà pa pọ̀ lábẹ́ ìdarí Ọba kan, ìyẹn Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run pè ní “Dáfídì ìránṣẹ́ mi” nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. (Ìsík. 37:24, 25) Jésù gbàdúrà pé kí gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn òun ‘jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba òun ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú òun, tí òun sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ * (Jòh. 17:20, 21) Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tó pè ní agbo kékeré máa di “agbo kan” pẹ̀lú “àwọn àgùntàn mìíràn.” Gbogbo wọn máa wà lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòh. 10:16) Ẹ ò rí i pé ohun tí Jésù sọ gan-an ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò Jèhófà lónìí. Àwa èèyàn Jèhófà ń jọ́sìn pa pọ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrètí tá a ní yàtọ̀ síra.

^ ìpínrọ̀ 6 Jésù sọ àwọn àpèjúwe kan nígbà tó ń sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra lásìkò wíwàníhìn rẹ̀. Ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ táá máa múpò iwájú. (Mát. 24:45-47) Lẹ́yìn náà, ó sọ àwọn àpèjúwe tó kan gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso lọ́run. (Mát. 25:1-30) Ó wá parí rẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe nípa àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, táá sì máa ti àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́yìn. (Mát. 25:31-46) Bó ṣe rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì náà nìyẹn, lóde òní àwọn tó máa lọ sókè ọ̀run ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹ sí lára. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá máa ń tọ́ka sí àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, síbẹ̀, ìṣọ̀kan tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ jẹ́ ká rí i pé ìṣọ̀kan máa wà láàárín àwọn tó ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé àtàwọn tó ń retí àtilọ sọ́run.