Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Táwọn méjì tí kì í ṣe tọkọtaya bá sun inú ilé kan náà mọ́jú lábẹ́ ipò tó ń kọni lóminú, ǹjẹ́ a lè torí ẹ̀ gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde?
Bẹ́ẹ̀ ni, ti pé wọ́n sun inú ilé kan náà mọ́jú jẹ́ ẹ̀rí pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣèṣekúṣe, èyí sì lè gba pé kí àwọn alàgbà gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde àyàfi tó bá jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lábẹ́ àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.—1 Kọ́r. 6:18.
Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn náà dáadáa kí wọ́n tó lè gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde. Bí àpẹẹrẹ: Ṣé àwọn méjèèjì ń fẹ́ ara wọn sọ́nà? Ṣé àwọn alàgbà ti fún wọn nímọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn síra wọn láwọn ìgbà kan? Kí ló fà á tí wọ́n fi ní láti sùn pa pọ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà? Ṣé wọ́n ti ṣètò tẹ́lẹ̀ pé àwọn á jọ sun ibẹ̀ mọ́jú? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n sùn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ náà, àbí àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ kan ló wáyé tó fi jẹ́ pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe ju pé kí wọ́n sùn pa pọ̀? (Oníw. 9:11) Ibo lẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n sùn sí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ipò kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra, àwọn nǹkan míì wà táwọn alàgbà tún máa gbé yẹ̀ wò.
Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò fínnífínní, wọ́n á pinnu bóyá ohun táwọn méjèèjì ṣe máa gba pé kí wọ́n gbé ìgbìmọ̀ onídàájọ́ dìde.