Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
IṢẸ́ ńlá ló wà níwájú Jóṣúà yìí. Òun ló máa ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe fẹ́ gba ilẹ̀ ìlérí. Ó sì dájú pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa kojú lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Àmọ́ Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé ó máa ṣàṣeyọrí, ó sọ fún un pé: ‘Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Máa pa àwọn Òfin mi mọ́. Máa kà á ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè máa ṣe gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣàṣeyọrí, wàá sì hùwà ọgbọ́n.’—Jóṣ. 1:7, 8.
Kò sí àní-àní pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé, ọ̀pọ̀ ìṣòro làwa náà sì ń kojú. (2 Tím. 3:1) Ó dájú pé tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún Jóṣúà, àwa náà máa ṣàṣeyọrí. A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì déédéé, ká sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.
Àmọ́ ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ wa ni ò gbádùn ká máa kẹ́kọ̀ọ́, àwọn míì sì gbà pé kò rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì gan-an. Torí náà, ká lè gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó sì ṣe wá láǹfààní, á dáa ká ronú lórí àwọn àbá tó wà nínú àpótí náà “ Gbìyànjú Àwọn Àbá Yìí.”
Onísáàmù náà kọrin pé: “Mú kí n máa rìn ní ipa ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ, nítorí tí mo ní inú dídùn sí i.” (Sm. 119:35) Ó dájú pé wàá gbádùn kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wàá sì rí àwọn ìṣúra táá ṣe ẹ́ láǹfààní bó o ṣe ń walẹ̀ jìn nínú Bíbélì.
Òótọ́ ni pé àwa ò ṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bíi ti Jóṣúà, síbẹ̀ àwa náà láwọn ìṣòro tá à ń kojú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ka Bíbélì, ká sì máa fi àwọn ohun tá à ń kà sílò kó lè ṣe wá láǹfààní. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ṣàṣeyọrí, àá sì máa hùwà ọgbọ́n.