Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fàánú Hàn sí “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

Máa Fàánú Hàn sí “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

NÍGBÀ tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn kan ò ní fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. (Lúùkù 10:​3, 5, 6) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn kan tá à ń wàásù fún lè jágbe mọ́ wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rọ̀jò èébú lé wa lórí. Tá ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan yìí lè múnú bí wa, kó sì mú ká má fàánú hàn sáwọn èèyàn mọ́.

Ẹni tó láàánú máa ń fi ara rẹ̀ sípò àwọn tíṣòro bá, ó máa ń ṣaájò wọn, ó sì máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, tá ò bá káàánú àwọn tá à ń wàásù fún, ìtara wa lè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn, a ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ jáfáfá mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tá a bá ń káàánú àwọn tá à ń wàásù fún, ńṣe là ń koná mọ́ ìtara tá a ní fún iṣẹ́ ìwàásù.​—⁠1 Tẹs. 5:⁠19.

Kí ló lè jẹ́ káàánú àwọn tá à ń wàásù fún máa ṣe wá kódà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn mẹ́ta kan tá a lè fara wé yẹ̀ wò, àwọn ni, Jèhófà, Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

MÁA FÀÁNÚ HÀN BÍI TI JÈHÓFÀ

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni Jèhófà ti fara da ẹ̀gàn táwọn èèyàn mú bá orúkọ rẹ̀. Síbẹ̀ kò yí pa dà, “ó jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.” (Lúùkù 6:35) Bó ṣe ń mú sùúrù fún ọ̀pọ̀ ọdún fi hàn pé onínúure ni lóòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó fẹ́ kí “gbogbo onírúurú ènìyàn” rí ìgbàlà. (1 Tím. 2:​3, 4) Lóòótọ́, Ọlọ́run kórìíra àwọn tó ń hùwà búburú, síbẹ̀ àwa èèyàn ṣeyebíye lójú rẹ̀ kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.​—⁠2 Pét. 3:⁠9.

Jèhófà mọ̀ pé Sátánì gbọ́n féfé, ó sì ti fọ́ ojú àwọn èèyàn látàrí irọ́ tó ń gbé lárugẹ. (2 Kọ́r. 4:​3, 4) Ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ torí pé àtikékeré ni wọ́n ti kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ èké, ìwàkiwà sì ti mọ́ wọn lára. Láìka gbogbo ìyẹn sí, ó wu Jèhófà láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sáwọn ará Nínéfè. Lóòótọ́, ìwà ipá kún ọwọ́ àwọn aráàlú yẹn, síbẹ̀ Jèhófà sọ fún Jónà pé: “Kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn?” (Jónà 4:11) Torí pé àwọn èèyàn Nínéfè ò mọ Jèhófà, Jèhófà káàánú wọn, ìdí nìyẹn tó fi rán Jónà pé kó lọ kìlọ̀ fún wọn.

Bíi ti Jèhófà, àwa náà gbà pé ẹ̀mí àwọn èèyàn ṣeyebíye. A lè fara wé Jèhófà tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣe tán láti gbọ́ wa, kódà tó bá tiẹ̀ dà bíi pé wọ́n ò ní wá sínú òtítọ́.

MÁA FÀÁNÚ HÀN BÍI TI JÉSÙ

Bíi ti Baba rẹ̀, àánú ṣe Jésù nígbà tó rí àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Ìdí ni pé, Jésù mọ ohun tó fa ìṣòrò wọn gan-an. Ó mọ̀ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ṣì wọ́n lọ́nà, wọ́n sì ti mú kí nǹkan nira fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára wọn lè jẹ́ káwọn nǹkan kan dí wọn lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn òun, síbẹ̀ ó “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”​—⁠Máàkù 4:​1-9.

Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ tẹ́ni tó o wàásù fún ò bá tẹ́tí sí ẹ nígbà àkọ́kọ́

Àwọn nǹkan àìròtẹ́lẹ̀ lè mú kí ẹni tí kì í tẹ́tí sí wa nígbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́

Táwọn èèyàn ò bá kọbi ara sí ìwàásù wa, ó yẹ ká ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ṣeé ṣe kó fà á. Ó ṣeé ṣe káwọn kan lérò tí kò dáa nípa Bíbélì tàbí nípa ẹ̀sìn Kristẹni. Ó sì lè jẹ́ pé ìwà burúkú tó kún ọwọ́ àwọn kan tó pé ara wọn ní Kristẹni ló ń kọ wọ́n lóminú. Nígbà míì sì rèé, wọ́n lè ti gbọ́ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa wa. Àyà àwọn míì lè máa já láti gbọ́ ìwàásù wa torí wọn ò fẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn aládùúgbò fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́.

Àwọn míì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí àwọn nǹkan tójú wọn ti rí, èyí sì lè mú kí wọ́n kọtí ikún sí ìwàásù wa. Arábìnrin Kim tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló jẹ́ pé ogun ló lé wọn kúrò nílùú wọn, gbogbo nǹkan ìní wọn sì ti bógun lọ. Ó burú débi pé wọn ò nírètí, nǹkan tojú sú wọn, wọ́n sì máa ń fura sáwọn èèyàn. Gbogbo ìgbà la máa ń pàdé àwọn tí kì í fẹ́ ká wàásù lágbègbè yìí. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn kan lù mí lóde ẹ̀rí.”

Kí ló mú kí Kim máa fàánú hàn sáwọn èèyàn láìka ìwà tí wọ́n ń hù sí i? Ó sọ pé: “Mo máa ń fi ohun tó wà ní Òwe 19:11 sọ́kàn, ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé: ‘Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.’ Bí mo ṣe máa ń ronú nípa ohun tójú àwọn èèyàn náà ti rí, àánú wọn máa ń ṣe mí. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, kì í ṣe gbogbo wọn náà ló burú o! A tiẹ̀ láwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ládùúgbò yẹn.”

Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ká sọ pé èmi náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì wá wàásù fún mi, báwo ni màá ṣe hùwà sí wọn?’ Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a ti gbọ́ onírúurú ọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe káwa náà má fẹ́ gbọ́ ìwàásù wọn, ó sì máa gba pé káwọn Ẹlẹ́rìí fàánú hàn sí wa. Tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sọ́kàn pé ohun tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wa làwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣe sáwọn míì, àánú àwọn tá à ń wàásù fún á máa ṣe wa kódà tó bá tiẹ̀ ṣòro fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—⁠Mát. 7:⁠12.

MÁA FÀÁNÚ HÀN BÍI TI PỌ́Ọ̀LÙ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fàánú hàn sáwọn èèyàn tó fi mọ́ àwọn tó tako iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò gbàgbé irú ẹni tóun náà jẹ́ nígbà kan rí. Ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀ rí mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tím. 1:13) Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ gbàgbé bí Jèhófà àti Jésù ṣe fàánú hàn sí i. Ìdí nìyẹn tó fi lè fi ara rẹ̀ sípò àwọn tó ń ṣàtakò sí iṣẹ́ wàásù rẹ̀ torí pé irú ẹni tóun náà jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn.

Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó pàdé àwọn tó ti jingíri sínú ẹ̀kọ́ èké? Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé ìlú Áténì. Ìṣe 17:16 sọ pé inú bí i gan-an nígbà tó rí i pé “ìlú ńlá náà kún fún òrìṣà.” Síbẹ̀, ohun tó bí Pọ́ọ̀lù nínú nílùú yẹn gan-an ló fi jẹ́rìí fún wọn. (Ìṣe 17:​22, 23) Pọ́ọ̀lù máa ń lo onírúurú ọ̀nà láti wàásù fáwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra kó lè ‘rí i dájú pé òun gba àwọn kan là.’​—⁠1 Kọ́r. 9:​20-23.

Àwa náà lè fara wé Pọ́ọ̀lù tá a bá pàdé àwọn tó ní èrò tí kò dáa nípa wa tàbí tó ti jingíri sínú ẹ̀kọ́ èké. A lè fi ohun tí wọ́n mọ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ wàásù “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fún wọn. (Aísá. 52:⁠7) Arábìnrin Dorothy sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ni wọ́n ti kọ́ pé Ọlọ́run ti le koko jù àti pé kì í rí tèèyàn rò. Mo máa ń kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn pé wọ́n tiẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, lẹ́yìn náà màá wá fi ohun tí Bíbélì sọ nípa ànímọ́ Jèhófà tó fani mọ́ra àtàwọn ìlérí rẹ̀ ọjọ́ iwájú hàn wọ́n.”

“MÁA FI IRE ṢẸ́GUN IBI”

Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, ìwà àti ìṣe àwọn tá à ń wàásù fún á “máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:​1, 13) Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àánú àwọn tá à ń wàásù fún máa ṣe wá, ká má sì jẹ́ kí ìwà àti ìṣe wọn ba ayọ̀ wa jẹ́. Jèhófà máa fún wa lókùn ká lè “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Mo sábà máa ń pàdé àwọn tó ní ìgbéraga, tí wọn ò kì í gbọ́rọ̀ wa, wọn ò sì ka àwa Ẹlẹ́rìí sí. Ó lè bí èèyàn nínú. Àmọ́, mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn pé kó jẹ́ kí n lè fojú tó tọ́ wo ẹni náà. Ó máa ń jẹ́ kí n lè gbọ́kàn kúrò lórí irú èèyàn tẹ́ni náà jẹ́, kí n sì ń ronú nípa bí mo ṣe lè ràn án lọ́wọ́.”

A kì í jẹ́ kó sú wa, gbogbo ìgbà là ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́

Torí pé a kì í jẹ́ kó sú wa, àwọn kan tí kì í gbọ́ wa tẹ́lẹ̀ lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Ó tún yẹ ká máa fún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin níṣìírí bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí. Jessica sọ pé: “Táwọn ará bá ń sọ ìrírí tí kò dùn mọ́ wọn tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí, dípò kí n sọ ọ̀rọ̀ tó máa dá kún un, ńṣe ni màá fọgbọ́n yí ìjíròrò náà sí èyí tó ń gbéni rò. Bí àpẹẹrẹ, mo lè sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe, kódà táwọn kan ò bá tiẹ̀ dáhùn pa dà lọ́nà rere.”

Jèhófà mọ onírúurú nǹkan tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó dájú pé inú rẹ̀ á máa dùn bó ṣe ń rí i tá à ń fara wé òun, tá a sì ń fàánú hàn sáwọn èèyàn! (Lúùkù 6:36) Àmọ́ àánú àti sùúrù Jèhófà láàlà, kò ní máa wà títí lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọ àkókó pàtó tó máa pa ayé yìí run. Ní báyìí ná, iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ kánjúkánjú. (2 Tím. 4:⁠2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fìtara wàásù, ká sì jẹ́ káàánú “gbogbo onírúurú ènìyàn” máa ṣe wá.