ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26
Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Borí Ìbẹ̀rù
“Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.”—SM. 118:6.
ORIN 105 “Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Àwọn nǹkan wo ló lè máa bà wá lẹ́rù?
Ẹ JẸ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa kan. Nestor àti Maria ìyàwó ẹ̀ fẹ́ lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù sí i. * Àmọ́ kí wọ́n tó lè ṣiṣẹ́ náà láṣeyọrí, wọ́n ní láti dín owó tí wọ́n ń ná kù. Torí náà, ẹ̀rù ń bà wọ́n pé àwọn ò ní láyọ̀ táwọn ò bá fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ mọ́. Ẹlòmíì ni Biniam, nígbà tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń ṣenúnibíni sí wa, ó mọ̀ pé wọ́n lè ṣe inúnibíni sóun náà torí òun ti ń jọ́sìn Jèhófà, ìyẹn sì mú kẹ́rù bà á gan-an. Àmọ́ jìnnìjìnnì tún bá a nígbà tó ro ohun táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ máa ṣe tí wọ́n bá gbọ́ pé òun ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Valérie lọ ṣàyẹ̀wò nílé ìwòsàn, wọ́n sọ fún un pé ó ti ní àrùn jẹjẹrẹ kan tó burú gan-an, kò sì rọrùn fún un láti rí dókítà tó máa ṣiṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Ká sòótọ́, ẹ̀rù bà á pé òun lè kú.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè borí ẹ̀rù tó ń bà wá?
2 Ṣé ẹ̀rù ti ba ìwọ náà rí? Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ lára wa lẹ̀rù ti bà rí. Àmọ́, tá ò bá sapá láti borí ìbẹ̀rù náà, ó lè jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó máa ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ohun tí Sátánì sì fẹ́ nìyẹn. Ó tún máa ń mú kẹ́rù bà wá ká lè rú òfin Jèhófà títí kan èyí tó sọ pé ká máa wàásù ìhìn rere. (Ìfi. 12:17) Sátánì burú, ó lágbára, kò sì láàánú. Àmọ́, a lè gba ara wa lọ́wọ́ ẹ̀. Báwo la ṣe máa ṣe é?
3. Kí ló máa jẹ́ ká borí ìbẹ̀rù?
3 Tá a bá gbà pé Jèhófà fẹ́ràn wa àti pé ó ń tì wá lẹ́yìn, Sátánì ò ní lè dẹ́rù bà wá. (Sm. 118:6) Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó kọ Sáàmù 118 ní ọ̀pọ̀ ìdààmú. Ó láwọn ọ̀tá tó pọ̀ gan-an, kódà àwọn èèyàn pàtàkì wà lára wọn (ẹsẹ 9, 10). Wọ́n sì máa ń fúngun mọ́ ọn nígbà míì (ẹsẹ 13). Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà bá a wí gan-an (ẹsẹ 18). Síbẹ̀, onísáàmù yẹn sọ pé: “Mi ò ní bẹ̀rù.” Kí ló mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀? Ó mọ̀ pé bí Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run bá tiẹ̀ bá òun wí, ó nífẹ̀ẹ́ òun gan-an. Ó dá onísáàmù náà lójú pé ipò èyíkéyìí tóun bá wà, Ọlọ́run tó fẹ́ràn òun ṣe tán láti gba òun.—Sm. 118:29.
4. Ìbẹ̀rù wo la lè borí tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?
4 Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, a máa borí nǹkan mẹ́ta tó sábà máa ń dẹ́rù bà wá. Àwọn nǹkan náà ni, (1) ìbẹ̀rù pé a ò ní lè pèsè fún ìdílé wa, (2) ìbẹ̀rù èèyàn àti (3) ìbẹ̀rù ikú. Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí borí ìbẹ̀rù wọn torí ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.
A LÈ MÁA BẸ̀RÙ PÉ A Ò NÍ LÈ PÈSÈ FÚN ÌDÍLÉ WA
5. Àwọn nǹkan wo ló máa ń ṣẹlẹ̀ tó lè mú kí olórí ìdílé kan máa ṣàníyàn? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
5 Àwọn olórí ìdílé tó jẹ́ Kristẹni gbà pé ojúṣe pàtàkì ni láti pèsè àwọn nǹkan tí ìdílé wọn nílò. (1 Tím. 5:8) Tó o bá jẹ́ olórí ìdílé, ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù máa bà ẹ́ pé iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. O lè máa ṣàníyàn pé báwo lo ṣe máa pèsè oúnjẹ, tó o sì máa sanwó ilé. O sì lè máa bẹ̀rù pé tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ pẹ́rẹ́n, o lè má rí iṣẹ́ míì. Bíi ti Nestor àti María tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé tó o bá ṣe àwọn àyípadà nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹ, owó táá máa wọlé fún ẹ ò ní tó ẹ ná. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò sin Jèhófà mọ́ torí pé Sátánì ti lo irú ọgbọ́n yìí láti dẹ́rù bà wọ́n.
6. Kí ni Sátánì máa ń fẹ́ ká gbà gbọ́?
6 Sátánì máa ń fẹ́ ká gbà pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kì í dá sí bá a ṣe máa pèsè fún ìdílé wa. Torí náà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé gbogbo ohun tó bá gbà la máa ṣe kí iṣẹ́ tá à ń ṣe má bàa bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́ kódà tó bá tiẹ̀ máa pa ìjọsìn wa lára.
7. Kí ni Jésù fi dá wa lójú?
7 Jésù mọ Bàbá ẹ̀ ju ẹnikẹ́ni míì lọ, ó sì fi dá wa lójú pé Jèhófà “mọ àwọn ohun tí [a] nílò, kódà kí [a] tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Mát. 6:8) Jésù sì mọ̀ pé Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò torí inú ìdílé Ọlọ́run làwa Kristẹni wà. Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà tó jẹ́ Olórí ìdílé wa máa ṣe ohun tó wà nínú 1 Tímótì 5:8.
8. (a) Kí ló máa jẹ́ ká borí ẹ̀rù tó ń bà wá pé a ò ní lè pèsè ohun tí ìdílé wa nílò? (Mátíù 6:31-33) (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tọkọtaya tó gbé oúnjẹ wá fún arábìnrin kan nínú àwòrán yẹn?
8 Tá a bá gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti ìdílé wa, kò ní ṣòro fún wa láti gbà pé ó máa pèsè àwọn ohun tá a nílò. (Ka Mátíù 6:31-33.) Ó máa ń wu Jèhófà gan-an láti pèsè àwọn ohun tá a nílò, ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì lawọ́ sí wa gan-an. Nígbà tó dá ayé, kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa gbé ẹ̀mí wa ró nìkan ló pèsè. Ó tún fìfẹ́ pèsè àwọn nǹkan míì táá jẹ́ kára tù wá, ká sì gbádùn ara wa. (Jẹ́n. 2:9) Torí náà, tá ò bá lóhun tó pọ̀ tó, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ pé Jèhófà ṣì ń pèsè ohun tá a nílò fún wa. (Mát. 6:11) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé kò sí nǹkan tara tá a lè yááfì báyìí tá a lè fi wé àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa àti èyí tó máa pèsè fún wa lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Nestor àti María rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn.—Àìsá. 65:21, 22.
9. Kí lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Nestor àti María?
9 Nestor àti María ní iṣẹ́ àti ilé tó dáa ní Kòlóńbíà. Wọ́n sọ pé: “A ronú pé á dáa ká dín iṣẹ́ tá à ń ṣe kù ká lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ àyà wa ń já pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, owó táá máa wọlé fún wa ò ní tó nǹkan.” Kí ló mú kí wọ́n borí ẹ̀rù tó ń bà wọ́n? Wọ́n ronú nípa gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wọn àti bó ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tó dá wọn lójú pé kò sígbà tí Jèhófà ò ní bójú tó àwọn, wọ́n fi iṣẹ́ olówó ńlá tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀. Wọ́n ta ilé wọn, wọ́n sì kó lọ sí apá ibì kan tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè wọn. Báwo ni nǹkan tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára wọn? Nestor sọ pé: “A ti rí i pé òótọ́ lohun tó wà nínú Mátíù 6:33. Gbogbo ohun tá a nílò ni Jèhófà ń pèsè fún wa. Kódà ní báyìí, ṣe layọ̀ wa ń pọ̀ sí i.”
ÌBẸ̀RÙ ÈÈYÀN
10. Kí nìdí tí ò fi yà wá lẹ́nu pé àwa èèyàn máa ń bẹ̀rù ara wa?
10 Àtìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà làwọn èèyàn ti máa ń hùwà ìkà sáwọn míì. (Oníw. 8:9) Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń fi ipò tí wọ́n wà ni àwọn míì lára, àwọn ọ̀daràn máa ń fojú àwọn èèyàn rí màbo, àwọn ọmọ burúkú tó wà nílé ìwé máa ń bú àwọn ọmọ ilé ìwé wọn, wọ́n sì máa ń halẹ̀ mọ́ wọn, kódà ìwà burúkú làwọn míì máa ń hù sí ìdílé wọn. Kò yà wá lẹ́nu nígbà náà pé àwa èèyàn máa ń bẹ̀rù ara wa! Àmọ́ báwo ni Sátánì ṣe máa ń mú ká bẹ̀rù èèyàn kó lè rí wa mú?
11-12. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń lo àwọn èèyàn láti dẹ́rù bà wá?
11 Sátánì máa ń fẹ́ ká bẹ̀rù àwọn èèyàn débi pé a ò ní ṣe ohun tó tọ́, a ò sì ní wàásù mọ́. Sátánì ti mú káwọn ìjọba kan fòfin de iṣẹ́ wa, wọ́n sì tún ń ṣe inúnibíni sí wa. (Lúùkù 21:12; Ìfi. 2:10) Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló máa ń parọ́ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn tó bá gba irọ́ yìí gbọ́ máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ gbéjà kò wá. (Mát. 10:36) Ṣé àwọn ọgbọ́n tí Sátánì ń dá yìí yà wá lẹ́nu? Rárá o. Ìdí ni pé àtìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti ń dá irú ọgbọ́n yẹn.—Ìṣe 5:27, 28, 40.
12 Sátánì máa ń dá àwọn ọgbọ́n míì yàtọ̀ sí pé kó mú ká máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ ìjọba. Ní ti àwọn kan, ohun táwọn ìdílé wọn máa ṣe fún wọn tí wọ́n bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń bà wọ́n lẹ́rù ju ìyà tí ẹnikẹ́ni lè fi jẹ wọ́n lọ. Torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an, wọ́n fẹ́ káwọn náà wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Ó máa ń dùn wọ́n gan-an táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá ń sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí tó ń ta ko àwọn ará wa kan tẹ́lẹ̀ ti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ tí ìdílé wa bá pa wá tì torí pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí la máa ṣe?
13. Tá a bá gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká fara dà á tí ìdílé wa bá pa wá tì? (Sáàmù 27:10)
13 Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 27:10 lè tù wá nínú gan-an. (Kà á.) Tá a bá ń rántí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa, ọkàn wa máa balẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa. Ó sì dá wa lójú pé ó máa san wá lẹ́san bá a ṣe ń fara dà á. Jèhófà nìkan ló lè pèsè gbogbo ohun tá a nílò nípa tara àtàwọn nǹkan táá jẹ́ ká lè máa jọ́sìn ẹ̀ nìṣó. Biniam tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí i pé ohun tí Jèhófà máa ń ṣe gan-an nìyẹn.
14. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Biniam?
14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Biniam mọ̀ pé àwọn aláṣẹ lè ṣe inúnibíni sóun, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Biniam mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an, ìyẹn ló sì jẹ́ kó borí ìbẹ̀rù èèyàn. Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé ìyà táwọn aláṣẹ máa fi jẹ mí máa tó ìyẹn. Àmọ́, ohun tó dẹ́rù bà mí jù ni inúnibíni tí ìdílé mi máa ṣe sí mi. Àyà mi ń já pé tí mo bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú bàbá mi ò ní dùn, àwọn tó kù nínú ìdílé mi á sì máa fojú burúkú wò mí.” Àmọ́ ó dá Biniam lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́. Biniam sọ pé: “Mo máa ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí wọn ò lówó lọ́wọ́, nígbà tí wọ́n ṣe ẹ̀tanú sí wọn àti nígbà tí wọ́n gbéjà kò wọ́n. Mo mọ̀ pé tí mi ò bá fi Jèhófà sílẹ̀, ó máa bójú tó mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá mú mi, tí wọ́n sì fìyà jẹ mí, síbẹ̀ mo rí i pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́.” Jèhófà wá di Baba tó ju Baba lọ fún Biniam, àwọn ará náà ò sì fi í sílẹ̀.
ÌBẸ̀RÙ IKÚ
15. Kí nìdí tí ò fi burú kéèyàn máa bẹ̀rù ikú?
15 Bíbélì sọ pé ọ̀tá ni ikú jẹ́. (1 Kọ́r. 15:25, 26) Ẹ̀rù ikú lè máa bà wá tára wa ò bá yá tàbí tí ẹnì kan nínú ìdílé wa bá ń ṣàìsàn tó le. Kí nìdí tí ẹ̀rù ikú fi ń bà wá? Ìdí ni pé Jèhófà ò dá wa pé ká máa kú, ṣe ló fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa títí láé. (Oníw. 3:11) Síbẹ̀, tá a bá fojú tó tọ́ wò ó, tá ò sì bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn á jẹ́ ká máa bójú tó ara wa. Bí àpẹẹrẹ, àá máa jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, àá sì máa ṣe eré ìmárale. Yàtọ̀ síyẹn, àá máa lọ ṣàyẹ̀wò ara wa lọ́dọ̀ àwọn dókítà, àá lo àwọn oògùn tó bá yẹ lásìkò, a ò sì ní máa fi ẹ̀mí ara wa wewu.
16. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wa?
16 Sátánì mọ̀ pé a ò fẹ́ kú. Ó sọ pé tá ò bá fẹ́ kú, gbogbo nǹkan la máa yááfì títí kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5) Ẹ ò rí i pé onírọ́ ni Sátánì! Síbẹ̀, torí pé Sátánì ni “ẹni tó lè fa ikú,” ó máa ń fìyẹn dẹ́rù bà wá ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. (Héb. 2:14, 15) Nígbà míì, àwọn tí Sátánì ń lò máa ń halẹ̀ mọ́ wa pé ká sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn máa pa wá. Láwọn ìgbà míì sì rèé, Sátánì máa ń lo àìsàn tó lè la ikú lọ láti mú ká ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn dókítà tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fúngun mọ́ wa pé ká gba ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì máa ta ko òfin Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan lè sọ fún wa pé ká gba ìtọ́jú tó lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ.
17. Bí Róòmù 8:37-39 ṣe sọ, kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa bẹ̀rù ikú?
17 Òótọ́ ni pé a ò fẹ́ kú, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà á ṣì máa nífẹ̀ẹ́ wa tá a bá tiẹ̀ kú. (Ka Róòmù 8:37-39.) Táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá kú, ó ṣì máa ń rántí wọn bíi pé wọ́n wà láàyè. (Lúùkù 20:37, 38) Ó ń fojú sọ́nà fún ìgbà tó máa jí wọn dìde. (Jóòbù 14:15) Nǹkan ńlá ni Jèhófà san ká “lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa. Torí náà, dípò ká pa òfin Jèhófà tì nígbà tá a bá ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí wa tàbí nígbà táwọn kan bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó tù wá nínú, kó sì fún wa lọ́gbọ́n àti okun tá a nílò. Ohun tí Valérie àti ọkọ ẹ̀ ṣe gan-an nìyẹn.—Sm. 41:3.
18. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Valérie?
18 Nígbà tí Valérie pé ẹni ọdún márùndínlógójì [35], àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ kan tí ò wọ́pọ̀, tó sì ń yára tàn lọ sáwọn ibòmíì lára ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà ṣe mú kó borí ìbẹ̀rù ikú. Ó ní: “Àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fún mi yí ìgbésí ayé wa pa dà lójijì. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ abẹ kan tó díjú fún mi kí n má bàa kú. Ọ̀pọ̀ àwọn dókítà oníṣẹ́ abẹ ni mo kàn sí, àmọ́ gbogbo wọn ló sọ pé àwọn ò lè ṣiṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀. Lóòótọ́ àyà mi ń já, síbẹ̀ mo mọ̀ pé òfin Ọlọ́run sọ pé kí n má gbẹ̀jẹ̀. Àtikékeré ni Jèhófà ti nífẹ̀ẹ́ mi, èmi náà ti wá láǹfààní báyìí láti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti sọ fún mi pé àìsàn náà ń burú sí i ni mo máa ń pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni màá ṣe, màá sì dójú ti Èṣù. Nígbà tó sì yá, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ náà fún mi láìlo ẹ̀jẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìsàn yẹn ò tíì lọ, kò sígbà tí Jèhófà ò fún wa lóhun tá a nílò. Bí àpẹẹrẹ, ní òpin ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ìgbà tá a ṣe àyẹ̀wò náà, àpilẹ̀kọ tá a jíròrò nípàdé ni ‘Bá A Ṣe Lè Máa Fi Ìgboyà Kojú Ìpọ́njú Lóde Òní.’ * Àpilẹ̀kọ yìí tù wá nínú gan-an, kódà a kà á lákàtúnkà. Irú àwọn àpilẹ̀kọ yìí àti bá a ṣe ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé ló fi èmi àti ọkọ mi lọ́kàn balẹ̀, tó sì jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́.”
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń BÀ WÁ LẸ́RÙ
19. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?
19 Ibi yòówù káwa Kristẹni wà láyé, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tá a ní, ó sì ń jẹ́ ká borí àwọn ìdẹwò Èṣù. (1 Pét. 5:8, 9) Ìwọ náà lè borí ìdẹwò Èṣù. Láìpẹ́, Jèhófà máa pàṣẹ fún Jésù àtàwọn tó máa bá a jọba pé kí wọ́n “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Lẹ́yìn ìyẹn, àwa tá à ń sin Jèhófà láyé “ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já [wa] láyà” mọ́. (Àìsá. 54:14; Míkà 4:4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù.
20. Kí ló máa jẹ́ ká borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù?
20 A gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á máa nífẹ̀ẹ́ wa, á sì máa dáàbò bò wá. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́, ká sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí bí Ọlọ́run ṣe ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a níṣòro. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn nǹkan tó ń bà wá lẹ́rù!—Sm. 34:4.
ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
^ Ìbẹ̀rù máa ń dáàbò bò wá nígbà míì torí kì í jẹ́ ká kó sínú ewu. Àmọ́ ìbẹ̀rù tún lè pa wá lára. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Sátánì lè mú ká máa bẹ̀rù, ká sì ṣe ohun tí ò dáa. Àmọ́ a ò ní jẹ́ kí Sátánì kó jìnnìjìnnì bá wa. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́? A máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí pé, tó bá dá wa lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, a ò ní bẹ̀rù.
^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.