Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Àwọn Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé Di Ìránṣẹ́ Jèhófà

Àwọn Obìnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé Di Ìránṣẹ́ Jèhófà

 

NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn, Araceli yarí kanlẹ̀, ló bá kígbe mọ́ mi pé: “Ẹ má bá mi sọ̀rọ̀ mọ́. Mi ò fẹ́ gbọ́ nǹkan kan nípa ẹ̀sìn yín mọ́, ó ń fọ́ mi lórí. Mi ò tiẹ̀ fẹ́ rí yín mọ́!” Ọ̀rọ̀ tí àbúrò mi sọ yẹn dùn mí gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti pé ọmọ ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] báyìí, mi ò tíì gbà gbé. Àmọ́, bí ìwé Oníwàásù 7:8 ṣe sọ, “òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.”Felisa.

Felisa: Orílẹ̀-èdè Sípéènì la dàgbà sí, ìdílé wa ò sì fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni wá, ìdílé wa sì fẹ́ràn ẹ̀sìn gan-an. Kódà, mẹ́tàlá lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa ló jẹ́ àlùfáà tàbí òṣìṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì. Àlùfáà ni ọ̀kan lára àwọn ẹbí ìyá mi, olùkọ́ sì tún ni ní ọ̀kan lára àwọn iléèwé Kátólíìkì. Lẹ́yìn tó kú, Póòpù John Paul Kejì dá a lọ́lá, ó sì sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn ẹni mímọ́. Alágbẹ̀dẹ ni bàbá mi, iṣẹ́ àgbẹ̀ sì ni màmá mi ń ṣe. Èmi ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́jọ táwọn òbí wa bí.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìlá, ogun abẹ́lé kan bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Lẹ́yìn ogun náà, wọ́n rán bàbá mi lọ sẹ́wọ̀n torí ọ̀rọ̀ òun àtàwọn aláṣẹ ò wọ̀ tó bá dọ̀rọ̀ òṣèlú. Kò rọrùn fún màmá mi láti rí oúnjẹ tó tó gbogbo wa jẹ, torí náà, wọ́n ní kí mẹ́ta lára àwọn àbúrò mi ìyẹn Araceli, Lauri àti Ramoni lọ máa gbé nílé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé nílùú Bilbao. Ó kéré tán, wọ́n á ṣáà máa rí oúnjẹ tó tó jẹ níbẹ̀.

Araceli: Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí nígbà yẹn, ọmọ ọdún méjìlá ni Lauri, Ramoni sì ti pé ọmọ ọdún mẹ́wàá. Àárò ilé máa ń sọ wá gan-an. Ilé la máa ń tún ṣe nílé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n rán wa lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó tún tóbi ju ibi tá a wà tẹ́lẹ̀ lọ nílùú Zaragoza, àwọn arúgbó ni wọ́n ń tọ́jú níbẹ̀. Iṣẹ́ àṣekúdórógbó là ń ṣe níbẹ̀, a máa ń fọ ilé ìdáná débi pé apá wa á fẹ́rẹ̀ẹ́ já, èyí sì máa ń mú kó rẹ̀ wá gan-an.

Felisa: Nígbà táwọn àbúrò mi lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní Zaragoza, màmá mi àti ẹbí wa kan sọ pé kémi náà máa lọ gbé níbẹ̀. Torí pé wọn ò fẹ́ kí n máa rí ọmọkùnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ mi ni wọ́n ṣe ni kí n kúrò nílé. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn ò dùn mí púpọ̀ torí pé mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì wù mí kí n gbé nírú ilé bẹ́ẹ̀ fúngbà díẹ̀. Ojoojúmọ́ ni mò ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì wù mí kémi náà di míṣọ́nnárì Kátólíìkì bíi ti ẹbí wa kan tó wà nílẹ̀ Áfíríkà.

Apá òsì: Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà nílùú Zaragoza, lórílẹ̀-èdè Sípéènì; apá ọ̀tún: Bíbélì ìtumọ̀ Nácar-Colunga

Nígbà tí mo dé ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà, mi ò lè ṣe ohun tó wù mí. Àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà ò fọwọ́ sí i pé kí n lọ sin Ọlọ́run nílùú míì. Torí náà lẹ́yìn ọdún kan, mo pa dà lọ sílé kí n lè lọ tọ́jú ẹbí wa kan tó jẹ́ àlùfáà. Èmi ni mo máa ń bá wọn tọ́jú ilé, a sì jọ máa ń fi Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà gbàdúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. Mo sì fẹ́ràn láti máa to àwọn òdòdó tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà dáadáa, kí n sì gbé ère Màríà àti tàwọn “ẹni mímọ́” síbi tó yẹ kí wọ́n wà.

Araceli: Nígbà tí mo wà ní Zaragoza, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ àkọ́kọ́ téèyàn máa ń jẹ́ kó tó di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Lẹ́yìn náà, àwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ rán mi lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà nílùú Madrid, wọ́n sì rán Lauri lọ sí èyí tó wà nílùú Valencia. Ramoni wà ní Zaragoza ní tiẹ̀. Ìlú Madrid ni mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kejì téèyàn máa jẹ́ kó tó di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Àwọn ọmọ ilé ìwé àtàwọn àgbàlagbà tí wọ́n wá ń gbé níbẹ̀ pọ̀ gan-an. Torí náà, kò sáyè eré rárá, iṣẹ́ ni kùrà. Ilé ìwòsàn tó wà níbẹ̀ ni mo sì ti ń ṣiṣẹ́.

Àfi bíi pé kémi náà ti di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Mo rò pé ńṣe la ó máa ka Bíbélì bí ẹni máa kú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tàbí Jésù. Mo kọ́ èdè Latin, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì pè ní “ẹni mímọ́,” mo sì ń jọ́sìn Màríà. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, iṣẹ́ àṣelàágùn la máa ń ṣe.

Gbogbo ẹ̀ ti wá tojú sú mi, ọkàn mi ò sì balẹ̀. Ó ń ṣe mí bíi kí n máa ṣiṣẹ́ táá mówó wọlé fún mi kí n lè máa tọ́jú ìdílé mi, dípò kí n máa ṣiṣẹ́ láti sọ àwọn míì di ọlọ́rọ̀. Torí náà, mo bá obìnrin tó jẹ́ olórí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mo sì jẹ́ kó mọ̀ pé mo fẹ́ kúrò níbẹ̀. Àmọ́, ṣe ló tì mí mọ́lé. Ó rò pé ìyẹn á mú kí n yí èrò mi pa dà.

Nígbà tó yá, wọ́n tú mi sílẹ̀, àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé mo ṣì ń wọ́nà àtilọ, wọ́n tún pa dà tì mí mọ́lé. Lẹ́yìn tí wọ́n ti tì mí mọ́lé nígbà mẹ́ta, wọ́n sọ fún mi pé, tí mo bá mọ̀ pé mo fẹ́ lọ, kí n buwọ́ lùwé pé Sátánì ni mo fẹ́ máa sìn báyìí dípò Ọlọ́run. Ara mi bù máṣọ. Òótọ́ ni mo fẹ́ kúrò níbẹ̀, àmọ́ mi ò lè ṣe ohun tí wọ́n ní kí n ṣe yẹn. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, mo ní mo fẹ́ bá àlùfáà sọ̀rọ̀, mo sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ó gbàṣẹ látọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀bù pé kí wọ́n dá mi pa dà sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní Zaragoza. Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan tí mo débẹ̀, wọ́n ní mo lè máa lọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Lauri àti Ramoni náà kúrò nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n wà.

ÌWÉ KAN TÓ PÍN WA NÍYÀ

Felisa

Felisa: Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo ṣègbéyàwó, èmi àti ọkọ mi sì ń gbé nílùú Cantabria, lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Mo ṣì máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Lọ́jọ́ Sunday kan, àlùfáà fìbínú sọ fún wa ní ṣọ́ọ̀ṣì pé, “Ẹ wo ìwé yìí!” Ó fi ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye hàn wá. Ó wá sọ pé, “Tá a bá rẹ́ni tí wọ́n ti fún ní ìwé yìí nínú yín, kó yáa mú un wá báyìí tàbí kó lọ sọ ọ́ nù!”

Mi ò ní ìwé yẹn lọ́wọ́, àmọ́ mo fẹ́ ní in. Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan, àwọn obìnrin méjì kan wá sílé mi. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, wọ́n sì fún mi ní ìwé yẹn kan náà. Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni mo kà á. Nígbà táwọn obìnrin náà pa dà wá, wọ́n bi mí pé ṣé màá fẹ́ káwọn máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì sọ fún wọn pé mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.

Ìwé Otitọ

Ó ń wù mí ṣáá pé kí n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Torí náà, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Mo fẹ́ sọ ohun tí mo ti kọ́ nípa rẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Torí náà, mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1973. Gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe ni mo máa ń bá àwọn ìdílé mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Àmọ́, gbogbo wọn ló gbà pé irọ́ ni ohun tí mo gbà gbọ́, pàápàá jù lọ Araceli tó jẹ́ àbúrò mi.

Araceli: Torí pé wọ́n fìyà jẹ mí nílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, inú bí mi, inú mi ò sì dùn sí ẹ̀sìn mi mọ́. Àmọ́, ìyẹn ò ní kí n má lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ Sunday, mo sì máa ń fi Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà gbàdúrà lójoojúmọ́. Ó ṣì wù mí pé kí n lóye Bíbélì, torí náà, mo bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ìgbà yẹn ni Felisa wá sọ àwọn ohun tó ń kọ́ fún mi. Ohun tó ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé mo rò pé orí ẹ̀ ti yí ni. Mi ò gba ohun tó ń sọ fún mi rárá.

Araceli

Nígbà tó yá, mo pa dà lọ sílùú Madrid láti lọ ṣiṣẹ́, mo sì ṣègbéyàwó níbẹ̀. Látọdún yìí wá, mo ti kíyè sí i pé àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé kì í fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù sílò. Torí náà, mi ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Mi ò nígbàgbọ́ mọ́ nínú ọ̀run àpáàdì tàbí àwọn “ẹni mímọ́,” mi ò sì rò pé àwọn àlùfáà lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Kódà, mo da gbogbo ère tí mo fi ń jọ́sìn nù. Mi ò mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ni mò ń ṣe àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì kò tẹ́ mi lọ́rùn àmọ́ mo ṣì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ó wù mí kí n mọ̀ ọ́, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́.” Mo rántí pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá kan ilẹ̀kùn mi, àmọ́ mi ò ṣílẹ̀kùn fún wọn rí. Mi ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn kankan mọ́.

Ilẹ̀ Faransé ni Lauri ń gbé, Ramoni sì ń gbé ní Sípéènì. Nígbà tó máa fi di ọdún 1980, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbogbo èrò mi ni pé àwọn náà ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe bíi ti Felisa, irọ́ gbuu ni wọ́n ń kọ́. Nígbà tó yá, èmi àti Angelines, obìnrin kan tó ń gbé ládùúgbò wa dọ̀rẹ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Angelines àti ọkọ rẹ̀ bi mí pé ṣé màá fẹ́ kí àwọn máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní mi ò fẹ́ràn ẹ̀sìn, wọ́n mọ̀ pé mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo ní: “Ẹ lè wá máa kọ́ mi, ìyẹn tẹ́ ẹ bá máa jẹ́ kí n lo Bíbélì mi!” Bíbélì ìtumọ̀ Nácar-Colunga ni mo ní lọ́wọ́.

BÍBÉLÌ SỌ WÁ DỌ̀KAN LẸ́YÌN-Ọ̀-RẸYÌN

Felisa: Nígbà tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1973, àwọn Ẹlẹ́rìí bí àádọ́rin [70] ló wà ní ìlú Santander tó jẹ́ olú ìlú Cantabria. A máa ń rin ìrìn-àjò lọ wàásù ní gbogbo abúlé tó wà ní ìlú náà. Bọ́ọ̀sì la máa kọ́kọ́ wọ̀, tá a bá bọ́ọ́lẹ̀, àá wá máa wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láti abúlé kan sí òmíì.

Láti ọdún yìí wá, mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mọ́kànlá lára wọn sì ti ṣèrìbọmi. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ló pọ̀ jù lára àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Mo ní láti ṣe sùúrù fún wọn. Mo mọ̀ pé ó máa ṣe díẹ̀ káwọn náà tó gbà pé irọ́ gbuu lohun táwọn gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀. Mo mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà àti Bíbélì nìkan ló lè mú kéèyàn yí èrò rẹ̀ pa dà kó sì wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Hébérù 4:12) Ọlọ́pàá ni ọkọ mi tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1979, Bienvenido lorúkọ rẹ̀. Ìyá mi náà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúngbà díẹ̀ kí wọ́n tó kú.

Araceli: Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò fọkàn tán wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, mo yí èrò mi pa dà. Yàtọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n tún máa ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù. Mo túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Bíbélì, mo sì wá ń láyọ̀ sí i. Kódà àwọn aládùúgbò mi kan kíyè sí èyí, wọ́n sì wá sọ fún mi pé, “Araceli, tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ tó ǹ kọ́ yìí o!”

Mo rántí pé mo gbàdúrà pé, “Jèhófà mo dúpẹ́ o, pé o ò jẹ́ kọ́rọ̀ mi sú ẹ, o sì tún fún mi láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ohun tí mò ń fi gbogbo ìgbésí ayé wá nìyẹn.” Mo tún bẹ Felisa ẹ̀gbọ́n mi pé kó dárí jì mí torí gbogbo ọ̀rọ̀ àbùkù tí mo sọ sí i. Látìgbà yẹn lọ, a kì í bára wa jiyàn mọ́, ó sì máa ń wù wá ká jíròrò ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1989, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61].

Felisa: Ọmọ ọdún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] ni mí báyìí, ọkọ mi ti kú, mi ò sì lè ṣe tó bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Àmọ́, mo ṣì máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, mo máa ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.

Araceli: Gbogbo àlùfáà àtàwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí mo bá rí ni mo máa ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, bóyá torí pé obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé lèmi náà tẹ́lẹ̀. Èmi àtàwọn kan lára wọn ti jọ jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti gba àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé ìròyìn. Mi ò lè gbà gbé ọ̀kan lára àwọn àlùfáà yẹn. Lẹ́yìn tá a ti sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀, ó gba ohun tí mò ń sọ. Ó wá sọ fún mi pé: “Ibo ni mo ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ níbi tí mo dàgbà dé yìí? Kí làwọn ọmọ ìjọ mi àtàwọn ẹbí mi máa sọ?” Mo wá sọ fún un pé: “Kí ni Ọlọ́run náà á sọ?” Ó gbà pé òótọ́ ni mo sọ, mo sì rí i pé inú ẹ̀ ò dùn. Àmọ́, ẹ̀rù ń bà á láti fi ẹ̀sìn rẹ̀ sílẹ̀.

Mi ò jẹ́ gbà gbé ọjọ́ tí ọkọ mi sọ pé òun máa tẹ̀ lé mi lọ sípàdé. Ó ti lé lọ́mọ ọgọ́rin [80] ọdún nígbà tó kọ́kọ́ wá sípàdé, kò sì pa ìpàdé kankan jẹ mọ́ látìgbà yẹn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Mi ò jẹ́ gbà gbé bá a ṣe jọ máa ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Oṣù méjì ṣáájú ọjọ́ tó máa ṣèrìbọmi ló kú.

Felisa: Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà, àwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò fọwọ́ sí i. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọ̀kan lára ohun tó múnú mi dùn jù lọ nìyẹn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, a jọ máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run wa àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Inú mi dùn gan-an pé gbogbo wa la jọ ń sin Jèhófà báyìí. *

^ ìpínrọ̀ 30 Ọmọ ọdún 87 ni Araceli, Felisa jẹ́ ọmọ ọdún 91, Ramoni sì jẹ́ ọmọ ọdún 83. Gbogbo wọn ṣì ń sin Jèhófà. Lauri kú lọ́dún 1990, òun náà sin Jèhófà títí tó fi kú.