Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?
ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ
BÍBÉLÌ KÌ Í ṢE ÌWÉ SÁYẸ́ǸSÌ, SÍBẸ̀ TIPẸ́TIPẸ́ LÓ TI SỌ Ọ̀PỌ̀ NǸKAN NÍPA SÁYẸ́ǸSÌ KÍ ÀWỌN ONÍMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ TÓ MỌ̀ Ọ́N. WO ÀPẸẸRẸ DÍẸ̀.
Nígbà kan, àwọn òléwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé rárá ni ìdáhùn náà. Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti wá gbà pé ọ̀run àti ayé ní ìbẹ̀rẹ̀. Ohun tí Bíbélì sì ti sọ tipẹ́ nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.
Báwo ni ayé ṣe rí?
Láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ayé rí pẹrẹsẹ. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì sọ pé ayé rí roboto. Àmọ́, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Aísáyà tó kọ ìwé kan nínú Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa “òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé,” ọ̀rọ̀ tó lò yìí tún lè túmọ̀ sí “roboto.”—Aísáyà 40:22.
Ṣé ó ṣeé ṣe kí ọ̀run gbó?
Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni tó ń jẹ́ Aristotle sọ pé ayé máa gbó, àmọ́ ọ̀run kò ní yí pa dà tàbí kó gbó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn èèyàn fi gba ohun tó sọ yẹn gbọ́. Àmọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé ìdàrúdàpọ̀ máa wáyé. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé gbogbo nǹkan tó wà láyé àti lọ́run máa gbó. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí ni Lord Kelvin, ó ka ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, tó ní: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó.” (Sáàmù 102:25, 26) Kelvin gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́ pé Ọlọ́run lè ṣe é kí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé má gbó, kí àwọn ohun tó dá má bàa pa run.—Oníwàásù 1:4.
Kí ló gbé ayé àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù dúró?
Aristotle sọ pé inú ohun kan tó rí roboto tó dà bíi gíláàsì ni ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì wọnú ara wọn pinpin, àárín pátápátá sì ni ayé wà. Nígbà tó fi máa di ọgọ́rùn-ún ọdún kejìdínlógún Sànmánì Kristẹni, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti wá ń gbà ohun tó sọ gbọ́ pé ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù kò dúró lórí nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwé Jóòbù tí wọ́n ti kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ pé Ẹlẹ́dàá “so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.”—Jóòbù 26:7.
ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN
BÓ TILẸ̀ JẸ́ PÉ BÍBÉLÌ KÌ Í ṢE ÌWÉ ÌMỌ̀ ÌṢÈGÙN, ÀWỌN ÌLÀNÀ KAN WÀ NÍNÚ RẸ̀ TÓ BÁ Ọ̀RỌ̀ ÌLERA TÒDE ÒNÍ MU.
Yíya àwọn tó ní àrùn sọ́tọ̀.
Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn èèyàn tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ́tọ̀. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje [700] sẹ́yìn tí oríṣiríṣi àrùn ń yọjú ni àwọn dókítà wá bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ̀ lé ìlànà yìí, wọ́n sì gbà pé ó wúlò títí dòní.—Léfítíkù, orí 13 àti 14.
Fífọ ọwọ́ lẹ́yìn téèyàn bá fi ọwọ́ kan òkú.
Ìgbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ń parí lọ làwọn dókítà ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé kò dáa kí wọ́n fi ọwọ́ kan òkú, kí wọ́n tún wá fi ọwọ́ yẹn tọ́jú aláìsàn láìjẹ́ pé wọ́n fọwọ́. Ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ti fa ikú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. Síbẹ̀, Òfin Mósè sọ pé aláìmọ́ ni ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ kan òkú. Kódà òfin náà dìídì sọ pé kí wọ́n fi omi wẹ ẹni náà mọ́ lọ́nà àṣà. Ó dájú pé àwọn àṣà ẹ̀sìn yẹn jẹ́ kí àwọn tó tẹ̀ lé òfin náà ní ìlera tó dára.—Númérì 19:11, 19.
Bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìgbọ̀nsẹ̀.
Ọdọọdún ni ìgbẹ́ gbuuru ń pa èyí tó ju ìdajì mílíọ̀nù àwọn ọmọdé torí pé àwọn tó wà láyìíká wọn kì í bójú tó ìgbọ̀nsẹ̀ lọ́nà tó yẹ. Òfin Mósè sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, kó sì jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbé.—Diutarónómì 23:13.
Ìgbà tó yẹ kí wọ́n dádọ̀dọ́ fún ọmọ.
Òfin Ọlọ́run sọ ní pàtó pé wọ́n gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ ọmọkùnrin ní ọjọ́ kẹjọ tí wọ́n bí i. (Léfítíkù 12:3) Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n bá bí ọmọ jòjòló ni ẹ̀jẹ̀ tó lè tètè dá lára rẹ̀ bó ṣe yẹ. Ní àwọn ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, tí ìmọ̀ ìṣègùn kò tíì jinlẹ̀ tó tòde òní, ó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n dúró di ẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó dádọ̀dọ́ ọmọ fún àǹfààní ọmọ náà.
Bí ìlera ara àti ti ọpọlọ ṣe tan mọ́ra.
Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa ọ̀rọ̀ ìlera àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé èèyàn máa ní ìlera tó dáa tí inú èèyàn bá ń dùn, tó ní ẹ̀mí pé nǹkan ṣì máa dáa, tó ń dúpẹ́ oore, tó sì ní ẹ̀mí ìdáríjì. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.”—Òwe 17:22.