Àwọn Nǹkan Wo Ni Ọlọ́run Ti Ṣe?
Tó o bá fẹ́ mọ ẹnì kan dáadáa, ó máa dáa kó o mọ àwọn nǹkan tó ti gbé ṣe àtàwọn ìṣòro tó ti borí. Bákan náà, tó o bá fẹ́ mọ Ọlọ́run dáadáa, o ní láti mọ àwọn nǹkan tó ti ṣe. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹnu máa yà ẹ́ láti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run ti ṣe tá à ń jàǹfààní ẹ̀ títí dòní, tó sì máa ṣe wá láǹfààní lọ́jọ́ iwájú.
ỌLỌ́RUN DÁ OHUN GBOGBO FÚN ÀǸFÀÀNÍ WA
Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa atóbilọ́lá, àwọn “ànímọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá.” (Róòmù 1:20) “Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a, Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.” (Jeremáyà 10:12) Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ń fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.
Tiẹ̀ wo bí Jèhófà ṣe buyì kún wa, ní ti pé ó dá wa “ní àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé ó dá wa lọ́nà tá a fi lè gbé àwọn ànímọ́ àgbàyanu ẹ̀ yọ dé ìwọ̀n àyè kan. Ó dá wa lọ́nà táá fi máa wù wá pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, ká lè mọyì àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtàwọn ìwà rẹ̀. Bá a sì ṣe túbọ̀ ń sapá láti fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípa rẹ̀ sílò, àá máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì ládùn. Pabanbarì ẹ̀ ni pé, ó tún mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ òun ká lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀.
Tá a bá wo àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, àá rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún [wa] láti ọ̀run, ó sì ń fún [wa] ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ [wa], ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn [wa].” (Ìṣe 14:17) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run ṣe kọjá pé kó kàn máa fún wa láwọn ohun tó ń gbé ẹ̀mí wa ró. Ó tún ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò fún wa lóríṣiríṣi àti lọ́pọ̀lọpọ̀ ká lè gbádùn ayé wa. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, díẹ̀ làwọn nǹkan yìí jẹ́ nínú àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.
Sáàmù 115:16; Àìsáyà 45:18) Àwọn wo ló fẹ́ kó máa gbé inú rẹ̀, báwo ló sì ṣe fẹ́ kí wọ́n gbé ibẹ̀ pẹ́ tó? “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—Sáàmù 37:29.
Jèhófà dá ayé káwa èèyàn lè máa gbébẹ̀ títí láé. Bíbélì sọ pé: “Ayé ni ó fún àwọn ọmọ èèyàn,” ó tún sọ pé “kò kàn dá a lásán, àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀.” (Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, tó sì ní kí wọ́n máa gbé ayé nínú Párádísè, kí wọ́n ‘máa ro ó, kí wọ́n sì máa tọ́jú rẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 15) Apá méjì ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wọn pín sí. Ó ní: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Èyí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa gbádùn ayé wọn títí láé. Àmọ́, ó dunni pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà lára “àwọn olódodo” tó máa “jogún ayé.” Ṣùgbọ́n, a dúpẹ́ pé àìgbọ́ràn wọn kò dá iṣẹ́ Ọlọ́run dúró. A máa tó rí ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun míì tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa.
ỌLỌ́RUN FÚN WA NÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ̀
Orúkọ míì tá a máa ń pe Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa ní Bíbélì? Ìdí pàtàkì tó fi fún wa ni pé ó fẹ́ ká mọ òun. (Òwe 2:1-5) Lóòótọ́ kì í ṣe gbogbo ìbéèrè tá a lè ní ni Bíbélì dáhùn, àwa náà kúkú mọ̀ pé kò sí ìwé tó lè sọ ohun gbogbo nípa Ọlọ́run. (Oníwàásù 3:11) Síbẹ̀, gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì lè jẹ́ ká mọ Ọlọ́run. A lè fi òye mọ irú ẹni tó jẹ́ nípa bó ṣe bá àwọn èèyàn lò. A tún lè mọ irú àwọn èèyàn tó fẹ́ràn àtàwọn tó kórìíra. (Sáàmù 15:1-5) Kódà, a lè mọ irú ìjọsìn tó tẹ́wọ́ gbà, irú ìwà tó fẹ́ ká máa hù àti èrò tó fẹ́ ká ní nípa owó àtàwọn nǹkan ìní. Bákan náà, a lè mọ Jèhófà dáadáa tá a bá kà nípa àwọn ohun tí Jésù Kristi Ọmọ ẹ̀ ṣe àtohun tó sọ nínú Bíbélì.—Jòhánù 14:9.
Ìdí míì tí Jèhófà fi fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé ó fẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láyọ̀ káyé wa sì dáa. Jèhófà ń lo Bíbélì láti bá wa sọ̀rọ̀ ká lè mọ ohun tó máa mú kí ìdílé wa láyọ̀, ká tún lè mọ ohun tó máa jẹ́ ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti bá a ṣe lè borí àníyàn ìgbésí ayé. Bá a ṣe máa rí i nínú ìwé yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì bíi: Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ tó báyìí? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Bíbélì tún ṣàlàyé àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe, kí ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ lè ṣẹ.
Ó dájú pé ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló sì wà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá. Nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ni Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì, ó sì tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún kí wọ́n tó parí ẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣì péye nítorí pé Ọlọ́run gangan ló ni ín. (2 Tímótì 3:16) Ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn ìwé àtijọ́ míì. Nígbà tá a fi àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó wà lóde òní wéra pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìwé Bíbélì àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì péye. Bákan náà, oríṣiríṣi itú làwọn ẹni ibi ti pa káwọn èèyàn má bàa túmọ̀ Bíbélì sí èdè míì tàbí kí wọ́n má bàa pín in kiri tàbí kí wọ́n kà á, síbẹ̀ Bíbélì lékè nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Kódà, òun ni ìwé tó délé dóko jù láyé, òun sì ni ìwé tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù láyé. Ti pé Bíbélì ṣì wà títí dòní olónìí jẹ́ ẹ̀rí pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa máa wà títí láé.”—Àìsáyà 40:8.
ỌLỌ́RUN MÁA ṢE OHUN TÓ NÍ LỌ́KÀN
Ohun míì tí Ọlọ́run tún ti ṣe ni pé ó ti pèsè ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó mú kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa máa ṣẹ. Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwa èèyàn ni pé ká máa gbé ayé títí láé. Àmọ́ nígbà tí Ádámù ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó pàdánù àǹfààní láti máa wà láàyè títí láé, ìyẹn sì kan gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn torí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Àìgbọràn ọmọ aráyé wá fẹ́ mú kó dà bíi pé Ọlọ́run ò ní lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Kí ni Jèhófà wá ṣe?
Jèhófà yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó gbé àwọn ìwà ẹ̀ yọ. Ó ṣe ìdájọ́ tó yẹ fún Ádámù àti Éfà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, àmọ́ ó ṣí ọ̀nà ìgbàlà fáwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Ọgbọ́n tí kò láfiwé ni Jèhófà fi bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Ẹsẹ̀kẹsè tí wàhálà yẹn ṣẹlẹ̀ ló ti wá ojútùú sí i, ó sì kéde rẹ̀ fáyé gbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó máa lo Jésù Kristi Ọmọ ẹ̀ láti dá aráyé nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀?
Jèhófà ṣètò kan láti gba aráyé lọ́wọ́ wàhálà tí ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù ti fà, ó rán Jésù wá sáyé láti kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè máa rìn ní ọ̀nà ìyè, lẹ́yìn náà Jésù fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” a (Mátíù 20:28; Jòhánù 14:6) Ohun tó sì jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe fún Jésù ni pé ẹni pípé bí Ádámù lòun náà. Àmọ́ Jésù ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ títí dójú ikú. Torí pé Jésù ò dẹ́ṣẹ̀ kankan, kò yẹ kó kú, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi jí i dìde sí ìyè ní ọ̀run. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti ṣe ohun tí Ádámù ò rí ṣe, ìyẹn láti fún aráyé onígbọràn ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. “Nítorí bó ṣe jẹ́ pé àìgbọràn èèyàn kan ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbọràn èèyàn kan á ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di olódodo.” (Róòmù 5:19) Nípasẹ̀ ìràpadà Jésù, Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ nípa mímú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti máa gbé ayé títí láé.
Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ nípa Jèhófà látinú bó ṣe bójú tó wàhálà tí àìgbọràn Ádámù dá sílẹ̀. A ti rí i pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ tí kò fi ní parí ohun tó bá bẹ̀rẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló máa “yọrí sí rere.” (Àìsáyà 55:11) A tún ti rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ju bá a ṣe rò lọ. Bíbélì sọ pé: “Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Bí ìfẹ́ náà ṣe jẹ́ nìyí, kì í ṣe pé àwa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòhánù 4:9, 10.
Bó ṣe jẹ́ pé Ọlọ́run “kò . . . dá Ọmọ rẹ̀ pàápàá sí, àmọ́ tó fi í lélẹ̀ nítorí gbogbo wa,” ó dá wa lójú pé ó máa ‘fún wa ní gbogbo ohun míì nítorí inú rere rẹ̀,’ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣèlérí. (Róòmù 8:32) Àwọn nǹkan wo ni Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa? Máa ka ìwé yìí nìṣó.
ÀWỌN NǸKAN WO NI ỌLỌ́RUN TI ṢE? Jèhófà dá àwa èèyàn ká lè máa gbé ayé títí láé. Ó pèsè Bíbélì fún wa torí pé ó fẹ́ ká mọ òun. Jèhófà lo Jésù Kristi láti rà wá pa dà, ńṣe nìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé gbogbo ohun tó ní lọ́kàn pátá ló máa ṣẹ
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìràpadà, ka ẹ̀kọ́ 27 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì www.ps8318.com/yo.