Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ìmọ̀ràn Tó Wúlò
Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ìmọ̀ràn Bíbélì ṣeé fọkàn tán, ó sì lè ranni lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin lára àwọn ìmọ̀ràn náà.
1. Ìgbéyàwó
Èrò táwọn èèyàn ní nípa ìgbéyàwó àti ohun tó lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀ yàtọ̀ síra.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Kálukú yín gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Torí pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ó mọ ohun tó yẹ kí tọkọtaya ṣe tí wọ́n bá fẹ́ máa láyọ̀. (Máàkù 10:6-9) Tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣe pàtàkì sí tọkọtaya ni bí wọ́n ṣe máa ran ẹnì kejì wọn lọ́wọ́, ayọ̀ máa wà nínú ìdílé wọn. Ọkọ kan máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun, tó bá ń tọ́jú ẹ̀, tó sì ń ṣìkẹ́ ẹ̀. Bákan náà, aya kan máa fi hàn pé òun ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ òun, tó bá ń hùwà tó dáa sí i, tó sì ń bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ WÚLÒ: Tọkọtaya ni Quang àti Thi, orílẹ̀-èdè Vietnam ni wọ́n sì ń gbé. Ilé wọn ò tòrò rárá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Quang máa ń hùwà tí kò dáa síyàwó ẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò kì í gba tìyàwó mi rò rárá, mo sì máa ń dójú tì í.” Ìyàwó ẹ̀ wá gbà pé àfi káwọn kọra àwọn sílẹ̀. Ó sọ pé: “Mi ò fọkàn tán ọkọ mi mọ́, mi ò sì rí i bí ẹni tí mo lè bọ̀wọ̀ fún mọ́.”
Nígbà tó yá, Quang àti Thi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì rí bí wọ́n ṣe lè lo ìmọ̀ràn tó wà ní Éfésù 5:33 nínú ìdílé wọn. Quang sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n máa hùwà tó dáa, kí n máa ṣohun táá jẹ́ kíyàwó mi mọ̀ pé mo fẹ́ràn ẹ̀, kí n máa tọ́jú ẹ̀, kí n sì máa ṣìkẹ́ ẹ̀. Nígbà tí mo sì ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì ń bọ̀wọ̀ fún mi.” Ìyàwó náà sọ pé: “Bí mo ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà ní Éfésù 5:33, tí mo sì ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń ṣìkẹ́ mi, tó ń tọ́jú mi, tó sì ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ìdílé ṣe lè láyọ̀, ka Jí! No. 2 2018 lórí jw.org. Àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀.”
2. Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Sáwọn Èèyàn
Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń hùwà àìdáa sáwọn kan ni pé àwọ̀ wọn, ìrísí wọn, ìlú wọn àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tiwọn. Àwọn kan tún kórìíra àwọn míì torí pé wọn ò fara mọ́ èrò wọn nípa àjọṣe ọkùnrin àti obìnrin.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú èèyàn.”—1 Pétérù 2:17.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Bíbélì ò kọ́ wa pé ká kórìíra tàbí ká máa fìyà jẹ àwọn tí kì í ṣọmọ ìlú wa, kò sì kọ́ wa pé ká kórìíra àwọn tó ń bá ọkùnrin bíi tiwọn tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló kọ́ wa pé ẹ̀yà tàbí ìlú yòówù káwọn èèyàn ti wá, ipò yòówù kí wọ́n wà láwùjọ, gbogbo èèyàn ló yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún. (Ìṣe 10:34) Tá ò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò tàbí ìwà àwọn kan, ó ṣì yẹ ká máa hùwà tó dáa sí wọn, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Mátíù 7:12.
ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ WÚLÒ: Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ Daniel pé èèyàn burúkú làwọn tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà, wọ́n sì lè ṣàkóbá fún orílẹ̀-èdè wọn. Èyí mú kí Daniel kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Éṣíà, ó tiẹ̀ máa ń dójú tì wọ́n níta gbangba. Daniel sọ pé: “Mo gbà pé ohun tí mò ń ṣe yìí fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè mi. Mi ò tiẹ̀ mọ̀ pé kò dáa rárá.”
Nígbà tó yá, Daniel kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Ńṣe ni mo yí èrò mi pa dà pátápátá. Mo wá rí i pé ibi yòówù ká ti wá, ìkan náà ni gbogbo wa lójú Ọlọ́run.” Nígbà tí Daniel ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn ní báyìí, ó ní: “Tí mo bá pàdé àwọn èèyàn, ibi tí wọ́n ti wá ò ṣe pàtàkì sí mi mọ́ rárá. Gbogbo èèyàn ni mo fẹ́ràn, mo sì láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kárí ayé.”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka Jí! No. 3 2020 lórí jw.org. Àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ṣé Ìkórìíra Lè Dópin?”
3. Owó
Torí pé àwọn èèyàn fẹ́ láyọ̀, wọ́n sì fẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, gbogbo ọ̀nà ni wọ́n fi ń wá bí wọ́n ṣe máa dolówó.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ọgbọ́n jẹ́ ààbò bí owó ṣe jẹ́ ààbò, àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.”—Oníwàásù 7:12.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Òótọ́ ni pé owó wúlò gan-an, àmọ́ tẹ́nì kan bá tiẹ̀ lówó rẹpẹtẹ, ìyẹn ò sọ pé onítọ̀hún máa láyọ̀ tàbí pé ọjọ́ ọ̀la ẹ̀ máa dáa. (Òwe 18:11; 23:4, 5) Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́, tá a sì fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dáa, a gbọ́dọ̀ máa lo ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì nígbèésí ayé wa.—1 Tímótì 6:17-19.
ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ WÚLÒ: Ọkùnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Indonesia, Cardo lorúkọ ẹ̀. Ojoojúmọ́ ayé ẹ̀ ló fi ń wá bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ. Ó sọ pé: “Gbogbo ohun tọ́pọ̀ èèyàn ń lé lọwọ́ mi tẹ̀. Mo máa ń rìnrìn-àjò lọ síbi tó wù mí, mo ra ọ̀pọ̀ nǹkan olówó iyebíye, oríṣiríṣi mọ́tò àti ilé.” Àmọ́ ọrọ̀ tí Cardo kó jọ ò tọ́jọ́ rárá. Ó sọ pé: “Mo kó sọ́wọ́ àwọn gbájú ẹ̀. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, gbogbo ọrọ̀ tí mo fàárọ̀ ọjọ́ mi kó jọ ti pòórá. Gbogbo ọjọ́ ayé mi ni mo fi kó ọrọ̀ jọ, àmọ́ ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ ńlá ló gbẹ̀yìn ẹ̀.”
Nígbà tó yá, Cardo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nípa owó. Kò wá bó ṣe máa dolówó lójú méjèèjì mọ́, àmọ́ ńṣe ló ń gbé ìgbé ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. Cardo sọ pé: “Kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run lóhun tó ṣeyebíye jù lọ láyé yìí. Mo ti wá ń sùn dáadáa báyìí, mo sì ní ayọ̀ tòótọ́.”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa owó, lọ sí jw.org, kó o wo Ilé Ìṣọ́ No. 3 2021, kó o sì ka àpilẹ̀kọ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Kàwé Dáadáa Tó Sì Lówó Rẹpẹtẹ?”
4. Ìbálòpọ̀
Oríṣiríṣi èrò làwọn èèyàn ní nípa ìbálòpọ̀.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ . . . ta kété sí ìṣekúṣe. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu nínú jíjẹ́ mímọ́ àti nínú iyì, kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 4:3-5.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Bíbélì sọ pé tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, ó yẹ ká máa kó ara wa níjàánu. Ọ̀rọ̀ náà “ìṣekúṣe” kan àgbèrè, iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe ọkọ àtìyàwó, kí ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin àti obìnrin máa bára wọn lò pọ̀ àti kí èèyàn máa bá ẹranko lò pọ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya nìkan ni Ọlọ́run sì fún lẹ́bùn náà.—Òwe 5:18, 19.
ÌMỌ̀RÀN BÍBÉLÌ WÚLÒ: Obìnrin kan tó ń jẹ́ Kylie lórílẹ̀-èdè Australia sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì ṣègbéyàwó, mo gbà pé tí mo bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tí mò ń fẹ́, ọkàn mi á balẹ̀, torí á nífẹ̀ẹ́ mi, kò sì ní já mi jù sílẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọkàn mi ò balẹ̀ rárá, inú mi sì bà jẹ́ gan-an.”
Nígbà tó yá, Kylie kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá mọ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìbálòpọ̀. Ó sọ pé: “Mo ti wá rí i pé ńṣe ni Ọlọ́run fún wa láwọn ìlànà tí kò ní jẹ́ ká ṣe ohun tó máa dùn wá gan-an, tó sì máa kó bá wa. Ní báyìí, mò ń láyọ̀ torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni mò ń ṣe. Mo tún ní ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ mi tó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ọ̀pọ̀ ewu ló ti ré mi kọjá torí pé mò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì!”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ sí jw.org, kó o sì ka àpilẹ̀kọ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbé Pọ̀ Láìṣègbéyàwó?”
Ẹlẹ́dàá wa ti jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe. Òótọ́ ni pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó fún wa, àmọ́ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹ̀, a máa jàǹfààní púpọ̀. Ó dájú pé tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ọkàn wa máa balẹ̀, a sì máa ní ayọ̀ tòótọ́.