Tí Àìsàn Burúkú Bá Ń Ṣe Ẹ́
ÌBÀNÚJẸ́ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ tí dókítà bá sọ pé ìwọ tàbí ẹnì kan tó o fẹ́ràn ní àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kan. Yàtọ̀ sí pé onítọ̀hún á máa jẹ ìrora àìsàn, á tún máa ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára. Ohun míì tó tún máa ń dá kún ìbẹ̀rù àti àníyàn aláìsàn náà ni bó ṣe ń pààrà ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, àgàgà tí àwọn dókítà bá lọ dá a dúró sílé ìwòsàn, tàbí tó bá ṣòro láti rí oògùn rà, tàbí tí oògùn tó ń lò bá ń ṣiṣẹ́ gbòdì lára rẹ̀. Ká sòóótọ́, ìdààmú ọkàn tí àìsàn burúkú máa ń fà máa ń tánni lókun.
Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ohun tó tu àwọn nínú jù lọ ni pé àwọn máa ń gbàdúrà sí
Ọlọ́run, àwọn sì máa ń ka ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì. Bákan náà, ó máa ń tuni nínú gan-an tí tẹbí-tọ̀rẹ́ bá fìfẹ́ hàn tí wọ́n sì dúró tini.OHUN TÓ RAN ÀWỌN KAN LỌ́WỌ́
Robert tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta (58) sọ pé: “Tó o bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àìsàn rẹ. Gbàdúrà sí Jèhófà. Sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún un. Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Sọ fún un pé kó fún ẹ lágbára tí wàá fi fara da àìsàn náà, kó o sì lè ṣe ohun tó máa fún ìdílé rẹ lókun.”
Robert sọ pé: “Ó máa ń dáa gan-an tí ìdílé ẹni bá dúró tini, tí wọ́n sì jẹ́ alábàárò gidi. Lójoojúmọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí mi máa ń pè mí láti béèrè nípa ìlera mi. Àwọn ọ̀rẹ́ mi náà ò pa mí tì, wọ́n máa ń fún mi ní ìṣírí. Ìyẹn ti jẹ́ kí n lè máa fara dà á nìṣó.”
Tó o bá ní ọ̀rẹ́ kan tó ń ṣàìsàn, ọ̀rọ̀ tí Linda sọ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó ní: “Ó lè wu onítọ̀hún láti ṣara gírí, kó má sì fẹ́ máa fìgbà gbogbo sọ̀rọ̀ nípa àìlera rẹ̀. Torí náà àwọn ohun tẹ́ ẹ ti jọ máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni kẹ́ ẹ máa sọ.”
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́ àti àdúrótì tẹbí-tọ̀rẹ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ayé rẹ ṣì máa dùn, kódà tó o bá ń ṣàìsàn tó lágbára gan-an.